End SARS, End SWAT: MC Oluomo ní òun kọ́ ló rán àwọn jàǹdùkú sáwọn olùwọ́de l'Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter/mcoluomo
Alaga ẹgbẹ awakọ ero NURTW ni ipinlẹ Eko, Alaaji Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ ti ṣapejuwe ẹsun ti awọn kan n fi kan an pe oun lo ran awọn janduku lati ls da iwọde #ENDSARS ru l'Eko gẹgẹ bi irọ lasan.
O ṣalaye ninu fọnran kan to fi si oju opo Twitter rẹ pe gbogbo ara ni oun ti fi ti iwọde naa lẹyin lati ibẹrẹ pẹpẹ nitori naa oun ko lee si nidi idaru rẹ.
O wa fi egun le pe ki iṣẹ oun daru bi oun ba mọ si awọn jaduku to lọ kọlu awọn eeyan naa.
Àwọn ikọ̀ mẹ́fà tí kò lè jẹ́ kí ìwọ́de #End SARS, #End SWAT wa sópin lásìkò yìí

Oríṣun àwòrán, others
Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS lárinrin àti ìtumọ̀Iwọde End SARS to n lọ lọwọ kaakiri awọn ilu nla ni Naijiria ni ọpọ awọn onwoye ohun to n lọ ti sọ pe o jẹ ọkan Pataki lara awọn iwọde to ni eto julọ ni Naijiria.Iwọde naa to ti n gbẹnule ọjọ kẹjọ bayii ni awọn ọdọ Naijiria fi n bere fun fifopin si iwa Baṣọrun Gaa ti awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, SARS, n wu si awọn ọdọ ti wọn n fẹsun iwa jibiti kan lọna aitọ.Bi ọpọ ero ṣe n darapọ mọ iwọde naa lojojumọ lawọn miran n gbe igbesẹ ki ifẹhonuhan ọhun dun, ko si larinrin.
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?
- Ṣé Èdùà dá ààtàn isó ni? Ọkùnrin kan tó yasó nínú ọkọ̀ Uber rí ẹ̀wọn he
- Ẹ wo èrò bìbà níbi ìwọ́de #EndSARS ní ìlú Ibadan
- Mọ̀ nípa iPhone 12, fóònù ológo 5G tí kìí lo "Charger” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde
Wo diẹ lara awọn to fi adun ati aṣeyọri si iwọde End SARS naa to n lọ lọwọ:
1.Awọn elere idaraya:
Ọkan lara awọn oluwọde naa gbe alupupu Power bike rẹ wa sojuko ọhun lati da awọn eeyan laraya.
Ni agbegbe Alausa, ẹnikan tilẹ gbe kẹkẹ ati aja rẹ wa, ti oun ati aja rẹ si n fi kẹkẹ ọhun dárà.
Yatọ si eyi, ọpọ igba ni wọn maa n fi awọn orin da awọn eeyan laraya, bii orin Fela Anikulapo, Naira Marley, Eedris Abdulkareem, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, @Davido/Fortune
2.Awọn to n kọ orin:
Ohun kan Pataki to mu iwọde End SARS ladun to si jẹ ki ijọba mọ ohun ti wọn n bere fun ni orin End SARS ti awọn oluwọde n kọ leralera.
Bi awọn to ṣaaju ṣe n kọ orin naa ni awọn elegbe n kọ tẹle wọn pe "End SARS!"

Oríṣun àwòrán, others
3.Awọn alasia:
Isọri awọn miran to jẹ ki iwọde End SARS ni itumọ ni bi awọn eeyan kan ṣe n gbe asia orile¬̣-ede Naijiria lojuko iwọde naa.
Ọkunrin lara awọn eeyan naa tilẹ ti di gbajumọ nitori bo ṣe maa n gbe asia naa to si ma n ju sọtun ati si osi.
Ni Enugu, ọdọbinrin kan tilẹ so asia naa mọ ori, o joko sori ere kan to ga to si n wa ẹkun mu nitori ohun ti awọn oṣiṣẹ SARS ti fi oju mọlẹbi rẹ ri.

Oríṣun àwòrán, Other
4.Awọn onimọtoto:
Iyatọ kan gboogi to wa laarin iwọde End SARS yii ati awọn to ti kọja lọ ni bi awọn eeyan kan ṣe palẹmọ ojuko iwọde lẹyin ti awọn eeyan ba pada sile wọn tan.
Awọn eeyan naa n ṣe iṣẹ takuntakun lati ri pe ko si idọti Kankan lojuko ti iwọde ti n waye.
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Ọlọ́pàá mẹ́sàn án tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ Akure t'éèyàn méjì ti kú sì wà nílé ìwòsàn
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
5.Awọn olupese:
Isọri awọn eeyan yii ni awon to n fun awọn olufẹhonuhan ni ounjẹ ki wọn baa le ni okun lati tẹsiwaju ninun iwọde ọhun.
Awọn ni olupese ounjẹ, omi ati ohun irinsẹ fun awọn oluwọde, bi awọn kan ṣe parapọ da owo burẹdi ni awọn miran parapọ da owo DJ ti yoo da wọn laraya.

Oríṣun àwòrán, @Falz
6.Awọn oluṣeto:
Lara awọn oluṣeto ni awọn gbajumọ lawujọ to fi ẹnu si ọrọ naa, to si n ṣatilẹyin fun awọn olufẹhunuhan.
Diẹ lara awọn oluṣeto ni a ti ri olorin takasufe, oṣere tiata ati awọn gbajumọ kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, @Police
Awọn miran lara wọn gbe owo kalẹ fun iwọde naa, bẹẹ ni awọn mii ẹwẹ n ru wọn soke lati tẹsiwaju ninu iwọde ọhun.
Lara awọn eeyan ọhun ni Falz, Toyin Abraham, Kanyew West, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ṣeeṣe ki ajakalẹ aarun coronavirus bẹ silẹ lorilẹede Naijiria fun igba keji- Ọjọgbọn Faduyile
Ìwọ́de 'End SARS' lè tan àjàkálẹ̀ arùn coronavirus lẹ́ẹ̀kejì ní Nàìjíríà- Ọjọ̀gbọ́n Faduyile
Alaga ajọ ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo tẹlẹ, Ọjọgbọn Francis Faduyile lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.
Ọjọgbọn Faduyile ṣalaye pe lootọ ni akọsilẹ fihan pe awọn to n lugbadi aarun covid-19 lojoojumọ ko pọ mọ.
Aàrẹ àná NMA, Francis Faduyile ní ìwọ́de 'End SARS' lè ṣe okùnfà àjàkálẹ̀ arùn covid 19 lẹ́ẹ̀kejì ní Nàìjíríà
Ọjọgbọn Faduyile ṣalaye pe ti ajakalẹ arun ba bẹ silẹ lẹẹkeji, ọwọja rẹ maa n ṣaa ba le ju ti igba akọkọ lọ.
Amọ, o sọ pe ewu nla lo wa ninu akọsilẹ to n fihan pe eeyan perete lo n ko aarun covid-19 lojoojumọ nitori ọpọ lo ti n sinmi bayii pe corovavirus ti lọ.
Dokita Faduyile sọ pe eyi gan an le mu ki coronavirus tun bẹ silẹ fun igba keji.
Ọjọgbọn iṣegun naa ṣalaye pe ti ajakalẹ aarun ba bẹ silẹ lẹẹkeji, ọwọja rẹ maa n ṣaa ba le ju ti igba akọkọ lọ.
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ni Naijira, NMA tẹlẹ tun sọ pe afaimọ ki aarun covid-19 maa tun bẹ silẹ lẹẹkeji pẹlu bi ọpọ eeyan ti n ṣe iwọde #EndSARS lai bikita nipa coronavirus.
O ni ko si ẹni to n tele awọn ilana lati dena aarun coronavirus bi wọn ti n ṣe ifẹhonuhan #EndSARS.
Ọna lati dena itankalẹ coronavirus lasiko iwọde #EndSARS
Ọjọgbọn Faduyile ṣalaye pe ko ṣi ṣiṣe ko si ai ṣe lori ọrọ ate dena coronavirus ju pe ki awọn eeyan maa tẹle ilana itakete si ara ẹni lọ bi wọn ti n ṣe iwọde.
Dokita Faduyile tun sọ pe ọna miran lati daabo ara ẹni lasiko iwọde yii ni lilo ibomu.
O ni nipa lilo ibomu ni eeyan ko le ko aarun coronavirus lara awọn oluwọde miiran.
Dokita Faduyile sọ pe awọn oluwọde yii wa lati oriṣiiriṣii ile to yatọ eleyi to le mu ki aarun covid-19 tete tan kalẹ laarin wọn.
O tun fikun ọrọ rẹ kẹmika apakokoro naa yoo ṣe iranwọ nipa dibaabo bo ara ẹni lọwọ covid-19 lasiko yii.
Bakan naa lo sọ pe awọn eeyan ko gbọdọ lati maa fọ ọwọ wọn loorekoore lasiko yii.
Ìfẹ́hònúhàn 'End SARS' ń tẹ́síwájú láì jẹ́ pé Buhari ṣe...
Àwọn olùwọ́de kọ̀ láti dáwọ́ dúró lẹ́yìn tí IGP tú SARS ká
Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa ni Ọga Agba ileesẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu kede pe oun ti tu ẹka ileesẹ ọlọpaa SARS ká.
Eyi waye lẹyin ọjọ mẹrin ti awọn ọdọ ti n fi ẹhonu han, ti wọn si n ṣe iwọde kaakiri Naijiria.
Sugbọn ṣa, iwọde ipolongo #ENDSARS ko ti i dawọ duro.

Bi iwọde ṣe n waye ni awọn agbegbe bii Lekki nilu Eko, lo n waye ni ilu Abuja ni Onitsha.
Wo diẹ lara bi iwọde naa ṣe n lọ:
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 1
Kinni awọn ibeere wọn lẹyin ti wọn tu SARS ka?
Awọn ọdọ naa n sọ pe o di igba ti Aarẹ Muhammadu Buhari fun'ra rẹ ba kede pẹlu aṣẹ, to si fi ontẹ lu u ju ikede ori ahọn lasan lọ.
Wọn ni nitori pe eyi jẹ igba kjarun un ti ijọba maa kede lori ọrọ SARS ṣugbọn to jẹ irọ. Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
- Wọ́n kò pa ẹnikẹ́ni sí ààfin Ṣọun Ogbomosọ, òkú tí àwọn ọdọ́ gbé wa ni ọlọ́pàá wọ́ jáde - Agbẹnusọ Ṣọ̀un
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
- Ilé alájà mẹ́ta wó pa èèyan méje, èèyàn 20 farapa ní Obalende, Eko
- Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
Lara ohun ti wọn n pariwo ni pe ki ileesẹ ọlọpaa tu awọn oluwọde #ENDSARS to wa ni ahamọ rẹ silẹ.
Iroyin sọ pe awọn ọlọpaa mu awọn oluwọde kan.
Wọn tun n fẹ ki ileesẹ fiyajẹ awọn ọlọpaa to ti sẹku pa eeyan ni Naijiria lai ṣe egbe.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Koda, wọn n fẹ ki ileesẹ ọlọpaa gbe igbimọ kan, ti kii ṣe ti ọlọpaa kalẹ, ti yoo mojuto iwadii ati igbẹjọ gbogbo àwọn ọlọpaa ti wọn ba fi ẹsun kan pe o fiya jẹ tabi pa ẹnikẹni, laarin ọjọ mẹwaa.
Ko tan sibẹ o, wọn ni awọn fẹ àtúnṣe ati afikun si owo oṣu awọn ọlọpaa Naijiria, boya ti wọnba n gba owo oṣu to dara bii ti agbofinro ilẹ okeere, ori wọn yoo pe sii ni bi wọn a ṣe maa ba ara ilu to pọ fun aabo to peye
Ati pe ki wọn ṣe ayẹwo ilera ọpọlọ fun awọn ọlọpaa SARS tẹlẹ, ki wọn o si tun ṣe idanilẹkọ fun wọn, ki wọn o to darapọ mọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa miran.
Iwọde #ENDSARS ni Lekki
Ni ṣe ni àwọn oluwọde naa di oju ọna marosẹ Lekki si Epe, pẹlu oriṣiriṣi akọle ti wọn gbe dani.
Aarẹ Buhari paṣẹ fun Ọga Agba ọlọpaa lori ọrọ SARS
Ọjọ Ẹti ni Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe oun ti paṣẹ fun Ọga Agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni aṣẹ lori igbesẹ ti yoo gbe lori iwọde #ENDSARS to n lọ kaakiri orilẹ-ede Naijiria, lẹyin ti awsn mejeeji ṣe ipade lọjọ Ẹti.
Aarẹ Buhari ninu ikede to fi sita loju opo Twitter lori ọrọ na sọ pe ki awọn ọmọ Naijiria o ma ṣe ṣiyemeji lori igbesẹ atunto ti awọn n ṣe nileeṣẹ ọlọpaa.
O ni "gbogbo igba ni wọn n fi to mi leti lori igbesẹ atunsẹ to n lọ lati fi opin si bi awọn ọlọpaa ṣe ma n fi iya jẹ ni, ati awọn iwa ti ko tọ miran. Ati lati ri i daju pe awọn ọlọpaa n jiyin iṣẹ fun araalu."
Ipade ti aarẹ ṣe pẹlu Ọga Agba ọlọpaa waye lẹyin ọjọ meji ti awọn ọdọ bẹrẹ iwọde ojoojumọ lati ọjọru nipinlẹ Eko, ati awọn ipinlẹ miran ni Naijiria.
- Wo ìdí tí Tẹni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ silẹ̀
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Kò sí Ààrẹ tàbí Gómìnà tó lè dá ìfẹ̀họ́núhàn àwọn Nàìjíríà lórí #EndSARS dúró- Monday Ubani
- Ẹ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria- Pásítọ̀ Sam Adeyemi
Buhari sọ pe ọga ọlọpaa ti gba aṣẹ lọwọ oun lati gbe igbesẹ lori awuyewuye to n waye lati ọdọ araalu lori iwakiwa to wa lọwọ awọn ọlọpaa SARS, ati lati ri i daju pe awọn ọlọpaa to hu iwa ti ko tọ foju wina ofin.
Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Twitter, Buhari bẹ awọn ọmọ Naijiria lati mu suuru, bo tilẹ jẹ pe wọn ni ẹtọ lati ṣe iwọde lori ohun ti ko ba dun mọ wọn ninu.
"Olufọkansin ni ọpọ lara awọn ọlọpaa Naijiria, to si n fi ara ṣiṣẹ lati pese aabo fun ẹmi ati dukia ni Naijiria, ao si ni dawọ atilẹyin wa duro ki wọn o le ṣe iṣẹ wọn."
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn oluwọde #ENDSARS pa ọlọpaa kan ni Delta
Ọga Agba fun ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn oluwọde EndSars nipinlẹ Delta ṣe pa ọlọpaa kan.
Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye nilu Ughelli, lasiko ti awọn ọdọ ṣe iwọde lati polongo fun pipa ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n risi iwa idigunjale, SARS, rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn oluwọde naa mu iwa janduku mọ, ti wọn si ti ipa bẹ ẹ pa Kọburu ọlọpaa kan, Etaga Stanley, ni ipa ika.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Yatọ si Kọburu ti wọn pa, Sajẹnti kan naa, Patrick Okuone, naa tun fi ara pa yanna-yanna nibi iṣẹlẹ ọhun, nitori ibọn ti awọn oluwọde yin.
Awọn oluwọde naa tun mu ibọn AK-47, ati ọta ibọn marundinlọgbọn.
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Àwọn tó jí mi gbé ti fẹ́ẹ̀ pa mí, kí àwọn ọlọ́pàá tó dóòlà mi - Agbẹjọ́rò Bisola Ajayi
- Ọlọ́pàá f'ẹsẹ̀ fẹ́ẹ l'Eko lẹ́yìn tó ki ìbọn bọ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lẹ́nu tó sì yìn ín
Iroyin sọ pe lẹyin ti awọn ọlọpaa naa yinbọn si aarin awọn oluwọde ni awọn ọdọ naa gba ẹsan nipa pipa ọlọpaa naa.
Ọgbẹni Adamu sọ pe lootọ ni iwọde jẹ ọna ti awọn ara ilu le gba fi ẹhonu han si ijọba, amọ o yẹ ki wọn o ma a ṣe pẹlu iwa ọmọluabi.
O ni "ileeṣẹ ọlọpaa ko ni la oju rẹ silẹ mọ, ki awsn ara ilu ma a kọlu awọn oṣiṣẹ rẹ, tabi awọn oṣiṣẹ eleto aabo miran."
Bakan naa lo tun ti paṣẹ fun Kọmisanaa ọlọpaa nipinlẹ Delta lati ṣewadii iṣẹlẹ naa, ko si ri i pe ọwọ tl awọn to hu iwa naa.

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Àwọn ọ̀dọ́ l'Eko yarí, ìwọ́de tó tako ọlọ́pàá SARS gbòde
Awọn ọdọ ni ọgọọrọ ti korajọ lati fẹhọnuhan tako iṣekupani awọn ọlọpaa SARS lorilẹede Niajiria.
Iwọde naa bẹrẹ lati Computer Village, ni Ikeja lọ si olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa ni Ikeja, lati fi ẹhonu wọn han lori bi awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe ṣe n paniyan bo ṣe wu wọn ni Naijiria.
Awọn ọdọ naa ṣeleri wi pe, ifẹhọnuhan naa yoo tẹsiwaju fun ọjọ meji kaakiri ipinlẹ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àwọn ajínigbé yìí dájú o, wọ́n fipá bá obìnrin mẹ́rin ló pọ̀ níwájú mi"
- Ìgbeyàwó túka nígbà tí afipábánilópọ̀ fi fídíò aya àfẹ́sọ́nà sórí ayélujára
- Sotitobire: Ojú àwọn Wòlí tó tí lọ sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn ọdaràn tẹ́lẹ̀ rèé
- Tí wọ́n bá kó owó wá fun yín lásìkò ìdìbò, owó tí wọ́n jí ni o, ẹ gbà á àmọ́...
- Ìdájọ́ ẹ̀wòn gbére kò ní kí Wòlíì Sotitobire má lọ sí ilèẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn - Agbẹjọ́rò Pásítọ̀ Alfa Babatunde
- Afurasí darandaran jí èèyàn mẹ́rìnlá gbé ní Ọ̀ṣun
- Àwọn mẹ́wàá tí wọ́n jígbé ní Ọ̀ṣun gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Awọn ọdọ gbe iwe akọle lorisirisi dani bii opin gbọdọ de si iwa ifiyajẹni lọna aitọ "Say no to brutal injustice", irun ori to ta koko kii ṣe ẹsẹ,
"Dreadlocks are no crimes", ọlọpaa yẹ ko ma a ṣọ wa ni, kii ṣe ki wọn ma a gba owo ọwọ wa, "Protect not exploit' ati eleyii ti wọn kọ pe ki ọlọpaa Naijiria ye pa wọn, "Nigeria police stop killing us'.
Ninu ọrọ ti awọn ọdọ naa sọ, wọn ni ijọba gbọdọ fi opin si iṣẹ awọn ọlọpaa SARS ni Naijiria.
''Pẹlu gbogbo ikede ti Ọga Agba ọlọpaa kede, o ṣi fihan gbangba pe, ikọ SARS ko jẹwọ ninu iwa buruku ti wọn n hu si awọn ara ilu.''
Bakan naa ni wọn kesi Ọga agba ọlọpaa lati ṣe iwadii ẹsun ipaniyan ti wọn ki kan awọn ikọ SARS, eleyii ti wọn ni awọn lọgalọga naa mọ nipa rẹ.

Oríṣun àwòrán, TWITTER
ENDSARS: Ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, ẹ ṣè ìrànwọ́ irinṣẹ́ fáwọn ọlọ́pàá- Naira Marley bẹ̀bẹ̀
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe,akọrin takasufe, Naira Marley ti ṣalaye fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria pe awọn to ṣe irun dada sori kii ṣe ọdaran o.
Nigba to n takurọsọ loju opo Instagram rẹ lori ọrọ awọn ọlọpaa SARS pẹlu alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Uba, Marley ni awọn obinrin to n wọ sikẹẹti penpe ko tumọ si pe alaṣẹwo ni wọn.
Naira Marley sọ pe oun wọgile iwọde ti oun gbero lati ṣe tẹlẹ nitori aabo awọn eeyan kii ṣe pe bo ya ẹru n ba oun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/nairamarley
Amọ, oun naa ko faramọ aba awọn eeyan pe ki wọn ko ọlọpaa SARS nlẹ, o ni ijọba ko nilo lati ko ọlọpaa nilẹ wi pe atunṣe ni wọn nilo.
Olorin takasufe ti ọpọ mọ si Marlian wi pe niṣe lo yẹ ki wọn ko awọn ọlọpaa SARS kuro loju titi.
O ni ohun to ba mu ki wọn ko SARS nlẹ, ijọba gbọdọ fopin si ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC naa.
- Agbẹjọ́rò fún Sotitobire yọ ọwọ́ nínú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lónìí!
- Ẹ̀wọ̀n ni wàá gbẹ̀yìn sí, kò sí bóo ṣe dọ́gbọ́n tó - Seyi Makinde wa ègúná ọ̀rọ̀ lé Fayose
- INEC kéde agbègbè ẹsẹ̀ odò 270 ti èrú ìbò ti le wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Ààrẹ Donald Trump ti padà sí ilé ìjọba lẹ́yìn ọjọ díẹ̀ tó lùgbàdì ààrùn coronavirus
- Ẹ̀yin olùkọ́, ìlànà àkànṣe owó oṣù tuntun dé fún yín
Naira Marley tun beere lọwọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa bo ya o tọnu lati kamẹra ọlọpaa to ba n ṣiwa wu.
Uba da lohun pe ko lodi si ofin lati kamẹra ọlọpaa to ba n ṣe ohun ti ko da, amọ o kilọ pe ki awọn ṣe mẹdọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto aabo to ba gbebọn dani.
Naira Marley rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipa pipese awọn ohun elo ti wọn nilo lẹnu iṣẹ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú Naira Marley lọ́wọ́lọ́wọ́
Ọ̀gá àgbà àjọ ọlọ́pàá Nàìjíríà ní àwọn ń fí àsìkò yìí pé àwọn ọdọ́ Nàìjíríà pé, gbogbo àriwo wọn ni àwọn ti gbọ́ lórí àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn kan ń hù nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá pàápàá jùlọ àwọn ikọ SARS.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ló sọ èyí lójú òpó twitter rẹ̀ lásìkò to n kàn si @officialnairam1 pé àwọn ti ṣetan láti ṣe ìpàdé pọ̀ pẹlú ilé iṣẹ́ ọ̀dọ́ àti àwọn míràn tí ọ̀rọ̀ kan ní Nàìjíríà láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòrò náà.
Ọ fí kún un pé ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹfa oṣu yìí, àwọn ṣetan láti ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú Naira Marley láti dáhun gbogbo àwọn ìbéèrè tó bá ni láti sọ lórúkọ àwọn ọ̀dọ́ Naìjíríà lórí ọ̀rọ̀ SARS àti àwọn ǹkan míràn tó jẹ wọ́n lógún.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi han pé àwọn ti ṣetan láti bá àwọn ti ọ̀rọ̀ kan láti ri dájú pé, àwọn ọlọ́pàá bọ̀wọ̀ fún ẹtọ́ àrá ìlú àti la'ti ni ìbáṣepọ tó dán mọ́ràn láàrín ọlọ́pàá àti àrá ìlú.
Ẹ̀wẹ̀ Naira Marley náà ti kọ sí ojú òpó Twiiter rẹ @officialnairam1 pé àwọn kò ni ṣe ìfẹhonu hàn mọ́, ṣùgbọ́n ó ké si àwọn ọ̀dọ́ pé, ikéde náà wà fún ki àrá ìlú le ni ìfọ̀kanbalẹ̀.
O fi kun pé, àwọn ń retí ǹkan ti wọ́n yóò ṣe , sùgbọ́n ó ṣe pàtàkì kí ki gbogbo ọ̀dọ́ ṣe ara wọn lọ́kan látu yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀.

Oríṣun àwòrán, NAira Marley/Facebook
Gbajugbaja olorin ọmọ Naijiria, Naira Marley ti bọ soju opo ayelujara lati kede pe oun yoo lewaju iwọde ifẹhonuhan lodi si iwa ti awọn ọlọpaa SARS n wu ni lorilẹede.
Afeez Fashola ti gbogbo eeyan mọ si Naira Marley fi lede loju opo Twitter rẹ pe oun yoo dari iwde ifẹhonuhan wọọrọwọ lọjọ Aje ọsẹ yii to si sọ fun awọn ololufẹ rẹ ki wọn darapọ.
Bakan naa o jẹ ko di mimọ pe awọn ikọ SARS kan ti ko lọwọ ninu iru ibajẹ yii atawọn ọlọpaa kan ti fifẹ han lati darapọ mọ iwọde naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
"Ti ẹ ba pade SARS tabi oṣiṣ alaabo kankan lọjọ Aje, ẹ ma ṣe ba wọn ja. Wọn ti fi aye gba wa lati beere ibeere, ṣugbọn ẹ ma ja tabi ba ohunkohun jẹ. Iwọde alafia la fẹ ṣe".
Si eyi, ọpọlọpọ awọn to n tẹle Marley lo da si ọrọ naa ti wọn si n ṣe afikun tabi idi ti ọrọ rẹ ko fi ta leti wọn. Awọn kan ni kii ṣe ọrọ ibọn yiyin nikan bikoṣe yiyẹ foonu eeyan wo ati ifiyajẹni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ẹwẹ, awọn olorin mii atawọn oṣere mii naa ti fi ọrọ sita lodi si iwa yii to fi mọ awọn mii naa ti wọn fifẹ han lati darapọ mọ iwọde ọhun.
Fun apẹrẹ, olorin ọmọ Naijiria mii ti wọn mọ si Runtown toun naa lero lẹyin loju opo ayelujara naa wa lara awọn to n ṣagbatẹru iwọde yii.
Ọ̀rọ̀ SARS kọ èmi àti ààrẹ Buhari lóminú - Yemi Osinbajo
Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo ni ọrọ ikọ ọlọpaa SARS ṣe n pa awọn araalu gbọdọ wa si opin.
Yemi Osinbajọ sọ ọrọ yii loju ọpọ ikansiraẹni Twitter rẹ ni Ọjọ Aiku.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Osinbajọ ni ọrọ naa gba ero ati atunṣe, eleyii ti aarẹ Buhari sọ wi pe awọn yoo wa ọna abayọ fun iṣekupani awọn ikọ ọlọpaa yii.
- Ikọ̀ Boko Haram àti gbogbò àwọn tó ń sàtìlẹyìn fún wọn kò ní rí ọdún 2021 - Pásítọ̀ Adeboye
- Ayé má níkà o! Tottenham ya aṣọ iyì mọ́ Manchester United lára nírọ̀lẹ́ ọ̀jọ́ ìsinmi
- Àwọn ọmọ FIBAN kò gbọdọ̀ lo orin Wasiu Ayinde mọ́ lẹ́yìn ìfìyàjẹní Murphy- FIBAN
- Yoruba wo ló fẹ́ gbé Oduduwa Republic tẹ́ n pariwo? - Lizzy Anjorin
''Inu mi bajẹ si iṣẹlẹ yii pẹlu bi awọn ikọ SARS ṣe n fi panpẹ mu awọn eniyan lai ni di.''
''Ọpọlọpọ eniyan ni ẹmi wọn ti ba iṣẹlẹ iwa ipa ti ikọ SARS n lo pẹlu awọn eniyan''.
Bakan naa ni igbakeji aarẹ naa fikun wi pe ki awọn yoo mu atunto ba ikọ ọlọpaa naa.
- Àwọn olùpolongo ìdìbò Aketi àti Jegede ń forígbárí l'Ondo, bí wọ́n ṣe n yìnbọn ni wọn n sun táyà
- ₦750m ni Akeredolu ń gbà lóṣù fún ‘Security Vote’ àti ₦150m owó oṣù - Agboola Ajayi fèsì
- INEC kéde agbègbè ẹsẹ̀ odò 270 ti èrú ìbò ti le wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọ̀pọ̀ aráàlú Owo wà nílé ìwòsàn, síbẹ̀ APC àti PDP kò gba ẹ̀bi
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye

Oríṣun àwòrán, davidoofficial
''Láti òní lọ, FSARS ò gbọdọ̀ káàkiri ìlú mọ́ tàbí tú ẹrù aráàlú wò mọ́''- Ọ̀gá ọlọ́pàá pàṣẹ
O to gẹẹ! Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Mohammed Adamu ti paṣẹ wi pe awọn ọlọpaa SARS ko gbọdọ kaakiri ilu mọ lati oni lọ.
Bakan naa ni ọga ọlọpaa tun sọ pe ọlọpaa SARS ko gbọdọ da awọn araalu duro lati maa tu ẹru wọn mọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, DCP Frank Mba ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ọga ọlọpaa Naijiria pe awọn ọlọpaa SARS ko gbọdọ duro soju titi mọ dabi dari igbokegbodo ọkọ loju popo mọ.
- Yoruba wo ló fẹ́ gbé Oduduwa Republic tẹ́ n pariwo - Lizzy Anjorin
- Pásítọ̀ CAC àti afurasí 'Yahoo boy' Olawale tó lu Hayatou ní jìbìtì N12.7m kó sí páńpẹ́ EFCC
- Adìyẹ́ jẹ̀fun ara wọn! Ẹ̀ṣọ́ NSCDC ṣèèṣì yìnbọ̀n pa ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS l'Osun
- MC Murphy ko sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ to wà níbẹ̀, tó ba wùú kó sọ òótọ- Adebayọ
Bakan naa ni ọga ọlọpaa tun paṣẹ pe ọlọpaa kankan ko gbọdọ mu ẹnikẹni nigba ti o ba wọ aṣọ ile.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 2
Ọga ọlọpaa sọ pe iṣẹ awọn SARS bayii ko gbọdọ ju ki wọn maa gbogun ti awọn adigunjale tabi awọn ajinigbe lọ.
Lati owurọ ọjọ Aiku ni ọgọrọ eeyan ti yabo oju ayelujara nibi ti wọn ti n kepe ijọba lati wọgile ọlọpaa nitori ọṣẹ ti wọn n ṣe fun ọpọ araalu papaa julọ awọn ọdọ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa FSARS meji, Monday Uchiola and Okechukwu Ogbonna lori ẹsun iwa idunkoko mọ araalu lọni aitọ.
Ohun tójú àwọn èèyàn tún rí tí wọ́n figbé ENDSARS bọnu
Lọwọlọwọ, awọn ọmọ Naijiria tun ti wu ọna ti awọn ọlọpaa kogberegbe SARS fi n huwa si awọn araalu sita.
Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ pato to fi tun wu eyi jade ko ṣẹyin iroyin kan to sọ pe ikọ SARS yinbọn pa ọkunrin kan lọjọ Abamẹta.
Iṣẹlẹ ọhun ni wọn ni o waye niwaju ile itura Wetland lagbegbe Ughelli ni ipinlẹ Delta.
Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, ikọ SARS yinbọn pa ọkunrin naa tan wọn si na papa bora.
Ẹwẹ, eyi ti mu iriwisi ọtọọtọ jade latẹnu awọn Naijiria ati pe bi iṣẹlẹ naa ko ba fidi mulẹ, eeṣe ti awọn alaṣẹ tọrọ kan bii Sunday Dare to jẹ minisita fun ọrọ ọdọ ati idagbasoke ere idaraya, gomina Eko Babajide Sanwoolu fi da si i ati lasiko yii gan?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Babajide Sanwoolu ni "aabo awọn araalu lo jẹ mi logun gẹgẹ bi oluṣọ agba ni ipinlẹ Eko". O ti fi da awọn eeyan loju pe awọn yoo gbe igbesẹ to tọ kiakia.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Awọn ọmọ Naijiria ti fọn sori ayelujara lati bẹrẹ si ni sọ ohun toju wọn n ri lọwọ awọn ọlọpaa SARS pẹlu #ENDSARS.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 8
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 9
Kii ṣe ajoji mọ bi iroyin ṣe maa n jade lọtun losi lori ọṣẹ ti ikọ SARS n ṣe si awọn araalu yala ọkunrin tabi obinrin.





















