Ondo Election 2020: Àwọn aráàlú ń sáré ra ohun èèlò fún ìpalẹ̀mọ́ ìbò gómìnà ọ̀la

Pẹlu bo ṣe ku wakati mẹrinlelogun ti idibo gomina ni ipinlẹ Ondo yoo waye, gbogbo eto ti gbinaya, to si ti n de ibi to lapẹẹrẹ.
Nigba ti ikọ BBC Yoruba kan si igboro ilu Akurẹ lọjọ Ẹti, gba gba gba lawọn agbofinro wa nikalẹ kaakiri tibu toro olu ilu ipinlẹ Ondo.
Bẹẹ lawọn ọwọ ikọ alaabo bii DSS, ọmọ ogun oriilẹ, ikọ to n gbogun ti ogun oloro, NDLEA at'awọn miran n lọ kaakiri ilu, lati rii pe awọn kọlọransi ko da omi alaafia ilu ru.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Toyin Abraham àtàwọn ọ̀dọ́ sọ̀kò èèbú síra wọn torí ìwọ́de #EndSARS
- Ọlọ́pàá f'ẹsẹ̀ fẹ́ẹ l'Eko lẹ́yìn tó ki ìbọn bọ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lẹ́nu tó sì yìn ín
- Iyabo Ojo sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ abẹ tó ṣe, Nkechi Blessing ra ǹkan irinsẹ fún arọ
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Àwọn tó jí mi gbé ti fẹ́ẹ̀ pa mí, kí àwọn ọlọ́pàá tó dóòlà mi - Agbẹjọ́rò Bisola Ajayi
Ni awọn ọja kaakiri, karakata nlọ ni pẹrẹu bii ọpọ ṣe n gbiyanju lati ra nnkan sile, nitori aini si lilọ bibọ lọjọ idibo naa, tawọn ọlọja pẹlu n ṣe aayan ati pa owo sapo ṣaaju ọjọ naa.

Awọn ọlọja to ba ikọ BBC Yoruba sọrọ nilu, Ọrẹ, Akurẹ, Ikarẹ at'awọn ilu miran ṣalaye pe, ọja ko fi bẹẹ ya ṣugbọn awọn ṣi ni ireti pe didun lọsan yoo so, ṣaaju ki ilẹ ọjọ Ẹti to ṣu.Bí
Nigba ti ikọ iroyin wa de olu ileeṣẹ ajọ INEC ni ipinlẹ Ondo nilu Akurẹ, awọn oṣiṣẹ ajọ naa n sare lati yanju awọn ohun kan si meji to nilo amojuto, ki eto idibo naa to bẹrẹ.

Awọn ipade lọọkan o jọkan lo ti n waye, ti eto aabo yipo ileeṣẹ ajọ naa si ti kun fọfọ pẹlu awọn ọlọpaa kogberegbe.
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti kede isede bẹrẹ lati agogo mejila oru ọjọ Abamẹta ni ipinlẹ Ondo, lati rii daju pe awọn ohun eelo idibo to lasiko idibo naa.

Tí wọ́n bá kó owó wá fun yín lásìkò ìdìbò, owó tí wọ́n jí ni o, ẹ gbà á àmọ́...

Ọkan lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP ẹka ti ilu Eko, Oloye Bode George ti sọrọ nipa eto idibo ipinlẹ Ondo.
Eyitayo Jegede ni oludije ti Bode George to jẹ agba ninu ẹgbẹ oṣelu PDP n gbaruku ti ninu idibo ipinlẹ Ondo.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti BBC Yoruba ṣe pẹlu rẹ lori iwoye rẹ bi idibo naa yoo ṣe lọ, o ṣalaye pe bi ajọ eleto idibo ṣe bẹrẹ igbesẹ kan nisisiyii to jẹ wipe lati ibudo idibo ni wọn ti n ko ibo jọ dara pupọ.
O ni eyi dara ju bi wọn ṣe maa n ṣe e lọ tẹlẹ ti wọn a ko o lọ sibikan ti o ṣeeṣe ki ojoro ti ṣẹlẹ. Nisisyiyi o ni otitọ ti leke.
Bakan naa o ni abajade èrú tí wọn ma n ṣe nigba yẹn kii maa n gbe ẹbi fun alare ni. Nibayii ninu idibo, o ni "nkan tawọn eeyan ba fẹ ni Ọlọrun maa n ba wọn fẹ".
Bode gboriyin fun ajọ INEC pẹlu bi wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ igbesẹ tuntun yii lasiko ipinlẹ Edo to da bii pe wọn fi ṣe ayẹwo to si yọri si rere, o ki sadankata ajọ INEC.
"Abosi, ọjẹlu, iwa ipanle la maa n ba nidi ọrọ idibo tẹlẹ ṣugbọn tawọn eeyan dẹ mọ pe nkan ti awọn di ni wọn maa ka sita, inu wọn a dun".
O ni igbayii la ṣẹṣẹ n ṣe bii gbogbo àgbáyé ṣe ń ṣe é ní Nàìjíríà ti Naijiria da bii awọn to ku.
Lori ọrọ pinpin owo tori idibo, o gba awọn eeyan nimọran lati gba owo ṣugbọn ki wọn dibo fun ẹni ti yoo ṣiṣẹ fun wọn.
Bakan naa lori ọrọ abo "nigba ti mo gbọ pe gomina Akeredolu s pe idibo yii kii ṣe ija lati ja ku torinaa bi oun ba fidi rẹmi, oun a gbe igba oun kuro jẹjẹ, mo gba a ladura ko ri bẹẹ bo ṣe sọ ọ".
Ṣugbọn o ni awuyewuye to n lọ kiri pe wọn n yinbọn ni ipinlẹ Ondo lọjọ melo sẹyin, ki gbogbo wọn lọ tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
O si gba awọn ọdọ ti wọn fi n ṣe janduku nimọran pe ki wọn ronu boya awọn naa fẹ iyi ati ọla ninu wọn ki wọn ṣe oriire ki wọn ka oju kuro lara owo pẹpẹpẹ ti wọn n fun wọn pe ki wọn maa gbe ibọn.















