Fayoṣe: Bẹ́ẹ ṣe yọ fìlà lórí Bola ige tó pa òwe ikú rẹ̀, kò lè ṣiṣẹ́ fún mi
Ariwo ijẹ ti ẹ jẹ tẹtẹ Bola Ige, aye ẹ maa jẹ dagunro mí bẹẹ ni Ayodele Fayose mu bẹnu.
Igbe gbajare yi n gbẹnu Oshokomolẹ latari iṣẹlẹ to waye ni asekagba ipolongo idibo ẹgbẹ PDP ni Ondo t'awọn kan ti si fila lori rẹ.
Gomina tẹlẹ rí ni ipinlẹ Ekiti to si tun jẹ agbaọjẹ ninu ẹgbẹ alatako ni Naijiria fi ọrọ yi sita loju opo Facebook.
Agbẹnusọ rẹ Lere Olayinka lo buwọlu atejade yi to si ni Fayose ko ni yẹ ko ni gbo lati maa sọ ododo nigbakugba.
Ko fi mọ ọ bẹẹ, Fayose tun naka abuku si agba oloselu PDP nii, Bode George, ati gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde pe awọn ni wọn de janduku to si fila lori oun nibi eto ipolongo idibo PDP l'Akure.
Ninu alaye ti Fayose sọ nínú atejade rẹ,o ni igba toun n rin lọ si ori aaye t'awọn alejo wa ni janduku kan sadede sun mọ oun to si ṣi fila ori oun.

Oríṣun àwòrán, Ayodele Fayose
"Bí wọn ṣe yọ fila lori Bola Ige bi yẹn ni Ile Ife.
Gbogbo wa la mọ ohun to t'ẹyin rẹ bo"
"Nitori naa mi o ni fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ yi"
Fayose salaye pe oun ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti ati pe wọn gbọdọ wadii awọn to wa lẹyin oro ti o fi n ke.
Lẹnu ọjọ mẹta yi, Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ati Ayodele Fayose jijọ n tahun sí ara wọn lori didari ẹgbẹ oṣelu PDP.
Kí ló wà nídìí ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì láàrin Makinde ati Fayose?

Ẹ̀wọ̀n ni wàá gbẹ̀yìn sí, kò sí bóo ṣe dọ́gbọ́n tó - Seyi Makinde wa ègúná ọ̀rọ̀ lé Fayose
Aawọ oṣelu to n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria eyi to jẹ awọn ilu Yoruba da bii pe o tun ti n gbona bii ogun bayii gẹgẹ bi itahunsira ni gbangba ṣe bẹ silẹ laarin gomina Oyo, Seyi Makinde ati gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose.
Eyi to tun ṣẹṣẹ jẹ tuntun laarin wọn ni igba ti gomina Makinde n fesi si abajade ẹsun ti ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra, EFCC fi kan Ayo Fayose ti Makinde ni ko si ohunkohun ti Fayose i baa ṣe lori ẹjọ yii, ẹwọn ni yoo lọ gbẹyin.
Ẹsun mọkanla ni ajọ EFCC fi kan Fayose lati ọjọ kejilelogun oṣu kẹwa ọdun 2018 toun tu ile iṣẹ kan to n jẹ Spotless Investment Ltd.
Fayose ni oun o jẹbi ẹsun naa ti wọn si ni beeli rẹ ni aadọta miliọnu naira pẹlu oniduro kan.
Latẹnu ọkan lara awọn oluranlọwọ Seyi Makinde, Dare Adeleke ni o ti fesi lori ayelujara si ohun ti Lere Olayinka, agbẹnusọ Fayose sọ pe "ati iwọ ati ọga rẹ to n sanwo fun ẹ, ẹwọn ni ipin yin, ko si bi ẹ ṣe fẹ yi idajọ naa to, ẹ o lọ sẹwọn".
Bi ẹ ba ranti, ọrọ laarin gomina Makinde ati awọn eekan PDP bii Fayose, Hon. Ladi Adebutu, Sẹnetọ Ademola Adeleke ati alaga ẹgbẹ PDP ni Eko, amojuẹrọ Deji Doherty ti n di fa ki n fa a tipẹ lorii tani yoo ṣakoso idari ẹgbẹ PDP nilẹ Yoruba.
Awọn kan korajọ sẹyin Ayodele Fayose paapaa julọ awọn to wa ni Ekiti, Osun, Ogun ati Eko ti awọn ti Oyo ati Ondo gba sẹyin Seyi Makinde
Àìgbọ́n àti àìmọ̀kanmọ̀kàn ló ń da Fayose láàmù, kò gba ẹnu rẹ̀ láti sọ̀rọ̀ sí mi - Bode George
Oloye Olabode George, tii se asaaju kan ninu ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Eko, ti fesi si oko ọrọ ti gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose sọ si.
Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe Ayodele Fayose ti sọ fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Eko pe ayafi ti oloye Bode George ba yẹba ninu ẹgbẹ oselu naa, ni egbẹ PDP to le moke nipinlẹ Eko.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lati fesi si ohun ti Fayose sọ naa, Bode George ni aigbọn ati aimọ lo n se Fayose nitori ko yẹ ko jẹ oun lo yẹ ki Fayose ri fin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wòlíì Sotitobire yóò gba ìdájọ́ lórí ẹ̀ṣùn ìjọ́mọgbé lọ́la
- Ẹ̀yin olùkọ́, ìlànà àkànṣe owó oṣù tuntun dé fún yín
- Ibadan ń jó àjórẹ̀yìn láàrin ẹgbẹ́, ẹ fún wa ní ìpínlẹ̀ tiwa - Kola Balogun bẹ ilé aṣòfin
- 'Nítori ààbò ẹmí MC Murphy ló fi gbá #100,000 lọ́wọ́ K1 lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀'
- Tani Akeredolu tó ń díje dupò gómìnà fún ìgbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo?
- Ikọ̀ Boko Haram àti gbogbò àwọn tó ń sàtìlẹyìn fún wọn kò ní rí ọdún 2021 - Pásítọ̀ Adeboye
Asaaju ẹgbẹ oselu PDP naa ni oun seranwọ fun Fayose lati moke ni igba meji gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ekiti, o si ya oun lẹnu pe o le pada ri oun fin.

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose
"Se bi ti ẹgbẹ ni o, abi o muti yo, abi o mugbo yo, o ti pẹ ti Fayose ti maa n fi ẹnu rẹ yẹn sọ isọkusọ bii ọmọ ti wọn ko bii re, ti kii si se ọmọluabi.
Ki lo kan Fayose gan pẹlu ipinlẹ Eko, Ekiti to ti wa gan, wahala to da silẹ nibẹ, a sẹsẹ n yanju rẹ ni."
Bode George ni Fayose ko bọwọ fun agba, ewu to si wa lori oun, kii se pe oun fi owo ra a, bẹẹ ni ko lọgbọn ori, Ọlọrun yoo si gba ẹsan lara Fayose, ayafi ti ko ba wa dọbalẹ ni ọọfisi mi lai mọye igba lati beere fun iranlọwọ.

Bakan naa lo fikun pe, Fayose ko le wọ aarin ero ni Eko bi, sebi se lo gbe oku baba rẹ pamọ fun ọdun kan, eyi to fihan pe kii se ọmọ gidi.
"Wọn ko nile iwosan ti wọn ti n wo were, amọ awa ni nilu Eko nibi, a si mu Fayose lọ sibẹ pe ki wọn lọ yẹ ọpọlọ rẹ wo, ologun si ni emi, emi kii gba igba kugba, mo si kọja ẹni ti ọmọ kan maa yọ ẹnu si tabi fi tayin."
"Ti Fayose ba to bẹẹ, ko bọ si aarin wa nilu Eko, ko maa bọ, yoo ri ẹẹkẹ rẹ lai gbe digi, ọmọ ọdun melo lo wa nigba temi se gomina lọdọ wọn, awa maa tun kọ ni Eko, tori Fayose gọ, o si fi ẹnu họra, wọn ko si bi re."
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko fún Fayose lọ́jọ́ méje láti bẹ àwọn adarí ẹgbẹ́

Ẹgbẹ́ òṣelú People's Democratic Party (PDP) ni ìpińlẹ Eko ti fún gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ekiti Ayodele Fayose ni gbédéke ọjọ méje láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn àgbà ẹgbẹ́ PDP.
Èyí wáye lẹ́yìn tí wọn ni Fayose sọ̀rọ̀ tó lé dá ẹgbẹ́ rú tó sì lè dá wàhalà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ kéèkèé àti àgbà ẹgbẹ́.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ PDP ni ìpínlẹ̀ Eko Taofik Gani sọ nínú àtẹjáde kan to fisíta pé Fayose sọ ọ̀rọ̀ àbùkù lásìkò ti Fayose ni òun n gba àwọn ọdọ ẹgbẹ́ níyànjú tó le mú kí àwọn ọdọ ẹgbẹ́ kọjú ìjà sí àwọn àgbà ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Eko.
- Tani Akeredolu tó ń díje dupò gómìnà fún ìgbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo
- Ikọ̀ Boko Haram àti gbogbò àwọn tó ń sàtìlẹyìn fún wọn kò ní rí ọdún 2021 - Pásítọ̀ Adeboye
- INEC kéde agbègbè ẹsẹ̀ odò 270 ti èrú ìbò ti le wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Ayé má níkà o! Tottenham ya aṣọ iyì mọ́ Manchester United lára nírọ̀lẹ́ ọ̀jọ́ ìsinmi
Lásìkò ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ìpolongo fún àtúndi ìbò sẹnatọ ni ẹkun ìlàoorùn ìpínlẹ̀ Eko to wáye ni ọjọ ìṣẹ́gun tó kọjá, níbi tó tí gba àwọn ọdọ́ nímọ̀ràn pé kí wọ̀n fún igbákejì alága ẹgbẹ́ nígbàkan rí olóyè Bode George ní ìsìnmi kúrò nínú ètò òṣèlú.
Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde tí akọ̀wé Fayose Lere Olayinka fi síta, to pe àkọlé rẹ ni " PDP gbọdọ̀ sọ pé kí ìgbákejì alága ẹgbẹ́ PDP nígbàkan ri olóyè Bode George lọ fẹ̀yìntì kí ẹgbẹ́ báa le ní ìlọsíwájú kí wọ́n sì jáwé olúborí nínú ìdìbò tó n bọ ní ìpińlẹ̀ Eko".
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP rọ Fayose láti ma jẹ́ àwòkọ́ṣe òdì fún àwọn ọdọ́ nínú ẹgbẹ́.
Láti ọja ajé, ọjọ́ kejila, oṣù kẹwàá, ọdún 2020, Fayose kò ni láànfàni láti kópa nínú ètò kankan nínú ẹgbẹ́ PDP, àyàfi tó bá wá túbá lórí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ.
Bákan náà ni Gani rọ Fayose láti dẹkun àwọn ọrọ to le dá wàhálà sílẹ̀ láàrin àwọn àgbà ẹgbẹ́, tàbí èyíkéyìí tó lo dènà ìlọsíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni ìhà Iwọ̀oorù-Gúúsù Naìjíríà.



















