Ibadan State Creation: Sẹ́nẹ́tọ̀ Kola Balogun jíṣẹ́ tí CCII ran, ó gbé àbá ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ibadan lọ sí Abuja

Gbọngan Mapo nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, @YorubaHistory

Sẹnẹtọ Kola Balogun, to n ṣoju ẹkun guusu ipinlẹ Oyonile asofin agba nilu Abuja, tun ti gbe ẹbẹ fun idasilẹ ipinlẹ Ibadan lọ siwaju ile.

Niwaju igbimọ to n ri si ayẹwo ati atunṣe iwe ofin orilẹede Naijiria, ti igbakeji aarẹ ile, Sẹnẹtọ Omo Ovie Omo Agege jẹ alaga rẹ, ni Kola Balogun gbe iwe ẹbẹ naa si.

Sẹnẹtọ Balogun sọ pe, oun ti jiṣẹ igbimọ CCII to ranṣẹ si oun wi pe, ki oun gbe aba naa lọ siwaju ile aṣofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ẹkun Ibarapa naa yoo wa lara ipinlẹ Ibadan tawọn n beere fun, ba le ṣeeṣe.

Sẹnẹtọ Kola Balogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Senator Kola Balogun

Sẹnẹtọ Balogun ni, ina ilu Ibadan n jo ajo rẹyin ninu awọn ilu to jẹ olu ilu ijọba alagbada, lẹyin ti Naijiria gba ominira tan.

Sẹnẹtọ naa sọ pe, oun yoo ṣa gbogbo agbara oun lati rii pe ile aṣofin jiroro lori idasilẹ ipinlẹ Ibadan, nigba ti o ba ya.

Oloye Balogun ni oun ko tii bẹrẹ si ni ro nipa ati dije ninu ibo gbogbogbo ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Ojú àwọn èèyàn Ondo ti là pé ìnira ni ẹgbẹ́ APC mú wá - Jegede PDP

Sẹnẹtọ Balogun ni ohun to jẹ oun logun bayii ni lati ṣe gbogbo ohun ti oun ṣeleri fawọn araalu, to dibo fun oun.