Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde àfikún owó ọkọ̀ BRT, Wo iye tó jẹ́, ìgbà tí yóò bẹ̀rẹ̀ àti ìdí abájọ

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede afikun owo ọkọ bọọsi ij|oba ti opọ mọ si BRT pẹlu ida 13% bẹrẹ lati ọjọ Aje ọsẹ to n bọ ọjọ keji oṣu Kẹta ọdun yii.
Ijọba fidi ọrọ yii mulẹ loju opo X ajọ LAMATA to n ri si okowo ọkọ ero ijọba ipinlẹ Eko nirolẹ ọjọ Aje ọjọ kẹtalelogun oṣu yii.
Ajọ LAMATA ṣalaye pe afikun owo ọkọ BRT ko ṣẹyin bi gbogbo nnkan ti gbowo lori lasiko yii.
Bakan naa tun ni ajọ ọhun ṣalaye pe fifi ọkọ ero ṣiṣẹ nipinlẹ Eko ti nilo owo to pọ si i.
Ijọba ipinlẹ Eko sọ pe afikun owo ọkọ yii yoo ṣeranwọ fun ajọ LAMATA lati le bori awọn iṣoro ti ajọ naa n koju lẹnu okowo fifi ọkọ ero ṣiṣẹ ni ipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi atẹjade to wa loju opo LAMATA naa ṣe sọ, afikun owo ọkọ yii tun wa ni ibamu pẹlu alakalẹ ti ijọba buwọlu lati maa ṣagbeyẹwo owo ọkọ BRT lọdọọdun.
Awọn oṣiṣẹ ajọ LAMATA naa sọ pe afikun owo ọkọ ọhun tun da lori odiwọn bi nnkan ṣe wọn si ni Naijiria eyi to gbẹnu le ida 15% nipari ọdun 2025.
Ajọ naa tun sọ pe owo ti wọn fi n tun awọn ọkọ naa ṣe ti pọ si i, to fi mọ iye ti wọn n ra ẹya ara ọkọ bayii.
Bakan naa ni ajọ LAMATA sọ pe owo oṣu awọn awakọ BRT naa ti le sii papaa julọ pẹlu bi ijọba ti ṣe bẹrẹ sisan owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ.
LAMATA tun sọ ninu atẹjade to fi sita naa pe afikun owo ọkọ naa yoo tun jẹ ko rọrun lati ko awọn ọkọ tuntun jade eyi ti yoo tubọ mu irọrun bawọn ero.
Amọ, ijọba ko ṣai fi da araalu loju wi pe awọn ko ni jẹ ki owo ọkọ ti wọn yoo maa san ko gara.
Ajọ LAMATA wa rọ awọn araalu wi pe ki wọn fọkan si ọjọ Aje to n bọ ti afikun owo ọkọ naa yoo bẹrẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

























