Ilẹ̀kùn Al-Jannah máa ń ṣí sílẹ̀, ilẹ̀kùn ọ̀run àpáàdì máa ń wà ní títì pa lásìkò ààwẹ̀ Ramadan - Imaamu Agba

Olujọsin kan wọ agbada funfun, o de fila buluu niwaju awọn olujọsin mii tawọn naa wọ oriṣiiriṣii aṣọ buba
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ olujọsin lo gbagbọ wi pe ibukun to pọ yanturu lo wa ninu oṣu aawẹ Ramadan.

Onimọ nipa ẹsin Islam to tun jẹ imaamu agba ile ẹkọ giga fasiti Al-Hikmah nipinlẹ Kwara, Ọmọwe Sanusi Lafiagi, naa ti sọ nipa pataki oṣu Ramadan ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe laipẹ yii pẹlu iwe iroyin Punch.

Imaamu Lafiagi ni oṣu Ramadan yatọ sawọn oṣu yooku nitori oṣu itaniji ninu ẹmi lo jẹ fawọn olujọsin.

Ọmọwe Lafiagi ṣalaye pe lara nnkan to jẹ ki oṣu Ramadan yatọ ni pe Anabi sọ pe nigba kugba ti oṣu Ramadan ba ti de ni gbogbo ilẹkun to wọ Al-Jannah maa n wa ni ṣiṣi silẹ.

Bakan naa ni o tun sọ pe ilẹkun ọrun apaadi maa n wa ni titi pa lasiko aawẹ Ramadan, ti awọn ẹmi Esu si maa n wa ni siso mọlẹ.

Imaamu agba fasiti Al-Hikmah fikun ọrọ rẹ pe o rọrun fun awọn olujọsin lati wọ Al-Jannah lasiko oṣu Ramadan ju awọn oṣu yooku lọ tori ilẹkun Al-Jannah maa n ṣi silẹ lasiko naa.

''O nira fawọn olujọsin lati da ẹṣẹ to le gbe wọn lọ inu ina lasiko aawẹ Ramadan tori gbogbo ilẹkun ọrun apaadi lo ti wa ni titi pa.

Ati pe awọn ẹmi Eṣu ti wọn maa n jẹ kawọn eeyan da ẹsẹ to le gbe wọn lọ inu ina ti wọn wa ni dide mọlẹ,'' Ọmowe Lafiagi lo sọ bẹẹ.

''Igbagbọ ti ko fẹsẹ mulẹ lo maa n jẹ keeyan pada sinu ẹṣẹ lẹyin Ramadan''

Onimọ nipa ẹsin Islam naa sọ pe ọkan eeyan ko leegun, ati pe eeyan nilo iranwọ Ọlọrun ki o ma ba maa da ẹṣẹ.

Ọmọwe Lafiagi ni ''o rọrun lati maa da ẹṣẹ, ko sẹni ti ko le ṣubu sinu ẹṣẹ.

Gbogbo wa ni a maa n da ẹṣẹ kan tabi omiran, bi a ṣe maa n da ẹṣẹ lo kan yatọ sira wọn.

Dida ẹṣẹ gan an tumo si pe ọkan wa ko ni eegun ni, idi niyi ti a ṣe maa n da ẹṣẹ.

Eyi tun tumọ si pe ẹran ara n lo wa ni.

Ti eeyan ba wa pada si igbe aye ẹṣẹ to n gbe tẹlẹ lẹyin oṣu Ramadan, o tumọ si pe iru eeyan bẹẹ kan gba aawẹ lasan ni, ko jẹ ki Ramadan ni ipa kankan laye rẹ.''

Imaamu agba naa sọ pe ko yẹ ki ẹnikẹni to ba gba aawẹ Ramadan pada sinu igbe aye ẹṣẹ mọ, tori ọkan rẹ yoo ti fa mọ Ọlọrun.