Ẹ̀mí èèyàn méjì tún bọ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Others
Ọrọ di bo lọ yaa mi bi awọn agbebọn se kọlu ilu Gbugbu nijọba ibilẹ Edu nipinlẹ Kwara.
Iṣẹlẹ naa waye lalẹ ọjọ aiku ọjọ kejilelogun oṣu Keji ọdun 2026, ni nnkan bi ago mẹjọ alẹ.
Gẹgẹ bi ẹnikan ti iṣẹlẹ naa soju rẹ se wi, Ọgbẹni Ganiyu Ndako, ọmọ bibi ilu Gbugbu sọ pe, gbogbo ilu naa lo pa rọrọ lalẹ ana.
O salaye pe, sa dede lawọn gbọ ti ibọn n dun kikan kikan ti awọn eeyan si ti lẹkun mọ ri nigba tawọn mi sa wọ inu igbo lọ.
Ndako fikun pe, wọn o ti mọ iye awọn eeyan ilu naa ti wọn jigbe, ṣugbọn eeyan meji ni wọn sekupa ti ọmọ kekere kan si farapa.
Titi di asiko yii ti a n ko iroyin yii jọ, awọn agbofinro o ti sọ kankan lori iṣẹlẹ naa.
BBC Yorùbá kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Toun, ṣugbọn ko ti sọ kankan lori iṣẹlẹ naa titi di asiko yii.
Ọgbẹni Aliu Ndako wa parọwa si ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Kwara lati ran awọn lọwọ nipa kiko awọn ọmọ Ologun sọwọ si agbegbe naa.
Kini ni ohun to ṣẹlẹ tẹlẹ
Lati bi osu melo kan sẹyin ni ilu Gbugbu ni ijọba ibilẹ Ẹdu ipinlẹ Kwara ti n foju wina ikọlu awọn agbebọn.
Lọdun to kọja ni ijọba ibilẹ naa kede titi gbajugbaja Ọja ilu naa ti gbogbo eeyan n pe ni Ọja Gbugbu pa nitori ibẹru ikọlu awọn agbebọn.
Gbajugbaja Ọja Gbugbu lawọn eeyan ma na yika ilẹ Nigeria ati lawọn apakan ilẹ Olominira Benin.
O jẹ gbajugbaja Ọja to tobi ni ipinlẹ Kwara
Laipẹ yii lawọn agbesunmọmi tun kọlu ilu Bacitagi lagbegbe naa nibi ti wọn ti ji eeyan meji gbe, ti wọn si yinbọn pa olori ikọ vigilante agbegbe naa.
Ilu Gbugbu wa labẹ Lafiagi Emirate ni ijọba ibilẹ Ẹdu ipinlẹ Kwara.

























