Ramadan: wo èrèdí tí o gbọ́dọ̀ ṣinu pẹ̀lú èso 'Déètì'

Ọdọbinrin meji ti wọn wọ ijaabu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Kate Bowie
    • Role, Global health
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ awọn Musulumi kaakiri agbaye ni yoo ṣinu awẹ wọn pẹlu date, eyii to ti bẹrẹ loni ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2026 yii.

Lasiko awẹ naa ni wọn maa n gbadura ti wọn si maa n fi sunmọ Ọlọrun pẹlu aijẹ ati aimu titi di irọlẹ ọjo awẹ, eyii to jẹ ọkan lara awọn opo ẹsin Islam.

Anọbi Muhammed sọ pe dates dara lati ṣinu awẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe mimọ awọn Musulumi, Quran.

Yatọ si awọn Musulumi, anfani nla lo wa ninu date jijẹ fun awọn to n gbaawẹ.

Anfani to wa ninu jijẹ rẹ

Awọn ohun aṣaraloore to wa ninu rẹ jẹ ko jẹ ohun jijẹ to dara lẹyin awẹ.

Shehnaz Bashir, to jẹ onimọ nipa ohun jijẹ sọ pe "ti o ba n ṣinu awẹ rẹ, agọ ara rẹ yoo gbiyanju lati pese eroja glucose, nitori oun lo nilo fun agbara.

"Ṣuga to wa ninu dates yoo ran ṣuga inu ẹjẹ agọ ara rẹ lọwọ lati tete le gbera siṣẹ.

"Dates dara pupọ nitori ṣuga inu rẹ, bẹẹ ni wọn tun ni eroja carbohydrates ninu pẹlu."

Eyii n tumọ si pe eso naa yoo maa fun agọ ara rẹ ni agbara lasiko awẹ ti o ko lanfani ati jẹun fun igba pipẹ.

Yatọ si eyii, wọn tun ni eroja vitamin B6, A, K ati iron ninu, eyii to n ran agọ ara lọwọ lati ni awọn eroja to yẹ lasiko to yẹ.

Jijẹ omi wa ninu ara rẹ

Bo tilẹ jẹ pe eso gbigbẹ ni dates jẹ, o le ma jẹ ki omi gbẹ lara rẹ lasiko awẹ.

Wọn ni eroja electrolyte potassium ninu, eyii to maa n fa omi sinu agọ ara.

Dietitian Shehnaz Bashirjoko siwaju ita ile rẹ, o n rẹrin si ẹrọ ayaworan

Oríṣun àwòrán, Shehnaz Bashir

Oru amuju

Awọn mii maa n ru lasiko awẹ Ramadan – amọ eeyan tun le sanran asanju ti o ba jẹ ounjẹ to pọ lapọju lasiko to ba n ṣinu.

Ẹni to n gbaawẹ yoo kọkọ jẹ eso dates ko to lọ gbadura lẹyin eyii ti yoo lo jẹ ounjẹ iftar.

Bi agọ ara ba ṣe n pin eso dates naa ni yoo maa din oru inu ara ku.

Bashir sọ pe o maa n fun agọ lanfani lati le pin ounjẹ naa ki o le ṣe awọn iṣẹ to yẹ ko ṣe lasiko to yẹ.

Eso dates gbigbẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O maa jẹ ki ounjẹ tete ṣiṣẹ

Eso dates ni eroja fibre ninu, eroja naa si maa n ran igbọnṣe lọwọ lati kọja ninu ifun daadaa.

Ileeṣẹ eto ilera ilẹ Gẹẹsi gba araalu nimọran pe ki wọn maa jẹ ọgbọn giraamu eso naa loojọ.

Ti mi o ba fẹran eso naa nkọ?

Yatọ si Ramadan, awọn eeyan ti bẹrẹ si n gbawẹ laye ara wọn nitori ilera ara wọn.

Bashir ni "o farajọ bi wọn ṣe n gbaawe lasiko Ramadan."

Ti o ko ba fẹran dates, oniruru ọna ni o le gba lati maa jẹ.

Bashir sọ pe "oriṣiriṣi rẹ lo wa, awọn kan ṣe e jẹ lẹnu, awọn mii rọ, bẹẹ lawọn mii le koko, bẹẹ ni inu awọn mii rọ."

Ti jijẹ lẹnu rẹ ko ba ṣiṣẹ fun ọ, o lẹ lọ ọ mọ awọn eso mii lati mu bii ẹlẹrindodo.