Kà nípa bí ìbínú àbíjù ṣe lè fa rọpárọsẹ̀ àti ikú òjijì

Ko sẹni ti ki i binu, nitori ẹlẹran ara ni gbogbo wa.
Ṣugbọn bi eeyan ba n jẹ ki ibinu ni ikapa lori oun lọpọ igba, ti ko ranti ọrọ Yoruba to ni ibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ, ewu nla lo n bẹ fun iru wọn.
Iwadii ijinlẹ lati ajọ National Institute of Health (NIH), fidi ẹ mulẹ pe o ṣee ṣe kawọn to ba n binu abiju tete ni awọn aisan aṣekupani bii rọparọsẹ ati iku ojiji lati ara aisan ọkan.
Bi eeyan ba ti ni aisan bii itọ ṣuga lara tẹlẹ, iwọnba ni ibinu wọn gbọdọ mọ. Bi eeyan ko si ni aisan yii naa, iwadii awọn dokita fi han pe lasiko ti eeyan ba n binu abisodi, awọn nnkan kan yoo maa ṣẹlẹ lara rẹ to le mu ki ẹjẹ rẹ ru tabi ki ifunpa ga.
Wọn ni ọpọlọ ni kinni naa yoo maa fọwọ kan, yoo si maa mu awọn eroja Adrenalin ati Cortisol jade. Bi o ba si binu ọhun tan, ara ko tun ni i tete balẹ.
Ṣiṣọra fun ibinu abiju, nini amojukuro ati ki eeyan le kapa ibinu rẹ ṣe koko fun ilera ẹda, ki wahala to le fa iku ojiji ma baa ṣẹlẹ.























