Ohun tí a mọ̀ nípa àfikún ọmọ ogun 200 t'America fẹ́ẹ́ fi ránṣẹ́ sí Naijiria

Aworan awon ologun ilẹ Americ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Orilẹede America ti kede pe oun ṣẹtan lati fi afikun ọmọ ogun igba (200) ranṣẹ si Naijiria, lojuna ati ran Naijiria lọwọ lati ṣẹgun awọn iṣoro aabo to n koju.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ikede kan ti waye lati America, pe oun yoo fi ọmọ ogun ranṣẹ silẹ yii, ti Ọgagun Samuel Uba, agbẹnusọ ileeṣẹ aabo ni Naijiria si fidi ẹ mulẹ fun BBC.

Bawo ni iṣẹ awọn ologun naa yoo ṣe ri ni Naijiria?

Bi Ọgagun Uba ṣe wi:

"Latari ibeere ijọba Naijiria ati ohun ti igbimọ apapọ Naijiria ati US jọ sọ, orilẹede America ti fi ikọ ologun kan ranṣẹ lati ṣe iranwọ fawọn ologun Naijiria nipa lilo awọn irinṣẹ ogun, bẹẹ ni wọn yoo fun wọn nimọran to yẹ.

"Awọn ologun naa ko ni i lọ soju ogun, bẹẹ ni wọn ko ni I ja loju ija."

Ọgagun Uba lo sọ bẹẹ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin ilẹ America si ṣe wi, awọn ṣọja naa yoo balẹ si Naijiria lọsẹ to n bọ, lara iṣẹ wọn si ni lati ran awọn ologun Naijiria lọwọ lori awọn ikọlu inu afẹfẹ ati ti ori ilẹ.

Pẹlu bi America ṣe fi gbogbo nnkan yatọ si Naijiria to, orilẹede mejeeji fẹnuko lori ọrọ aabo, wọn si gbe igbimọ apapọ ti yoo sokun aabo le kalẹ.

Loṣu Kejila ọdun to kọja, orilẹede America kọlu ikọ agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam kan nipinlẹ Sokoto, eyi ti ijọba Naijiria sọ pe oun mọ nipa ẹ.

Loṣu Kin-in-ni ọdun yii ni ọkọ oju omi kan ko awon nnkan ija ogun wọ Naijiria lati America, eyi ti ijọba ibẹ sọ pe o waye lati mu ajọṣepọ Naijiria ati America nipọn si i.