Àwọn ará Ondo bínú lórí bí àjọ NSCDC ṣe lo ìwà ipá pẹlu obìnrin kan tó pọnmọ sẹ́yìn àti ọkọ rẹ lórí ọ̀rọ̀ títa afẹ́fẹ́ gáàsì

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti ń suyọ lori fọnran fidio to gba ori ẹrọ ayelujara ni ọjọ kẹwaa, oṣu Keji ọdun yii, nibiti awọn ẹsọ Aabo Ara Ẹni Labo Ilu (NSCDC) ti n fi ipa mu okunrin kan torukọ ẹ n jẹ Alaba Balogun ati iyawo rẹ; Adenike Balogun lori ọrọ tita afẹfẹ gaasi.
Ọpọlọpọ olugbe ipinlẹ Ondo lo ti benu ate lu igbese ajọ NSCDC, bi wọn ṣe lo iwa ipa pẹlu awọn ara ilu.
Ọkan lara awọn ọdọ Ipinlẹ Ondo, Seyi Ogundipe, salaye pe igbesẹ ti wọn gbe tako ofin, o si yẹ ki awọn ikọ naa foju wina ofin.
O salaye pe wọn ko lẹtọ lati fi iwa ipa gba ohunkohun lọwọ ara ilu.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan an?
Ninu fọnran fidio naa, awọn ikọ NSCDC yabo Opopona St Luke, nijọba ibilẹ Guusu ilu Akure, nibi ti Alaba ti n ta gaasi, ti wọn si n fipa ko gbogbo ohun to ni ninu ile itaja naa.
Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni Adenike ti gbogbo eeyan gbagbọ pe aya okunrin naa ni, n gbiyanju lati ran ọkọ rẹ lọwọ pẹlu ọmọ lẹyin rẹ.
Ikọ NSCDC naa fipa ko gbogbo ẹru Alaba, iyawo rẹ si n gbiyanju lati gba a pada .
Obinrin naa gbagbọ pe awọn ikọ NSCDC ko lẹtọ lati hu iru iwa bẹẹ, nitori awọn ti san gbogbo owo to yẹ kawọn san sapo ijọba.
Bẹẹ ni Alaba paapaa to ni ile itaja n pariwo pe ohun ti san gbogbo owo to tọ lati san.
Kí ni àjọ NSCDC sọ lórí ọ̀rọ̀ náà?
Ninu atejade latọwọ Alukoro ajọ naa Daniel Aidamenbor fi sita, o salaye pe awọn ikọ ajọ naa ti bẹrẹ iṣẹ ni ibamu pẹlu ofin.
Ogbeni Aidamenbor salaye pe ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo rọbi ati afẹfẹ gaasi (NMDPRA) padi apo pọ pẹlu NSCDC lati se imuṣẹ awọn ofin ati ilana tita afẹfẹ gaasi.
O satenumọ rẹ pe NSCDC ko ni aṣẹ lati fun ẹnikẹni ni iwe aṣẹ moyege lati ta gaasi ni aarin ilu, sugbọn ojuṣe wọn ni lati ri i daju pe wọn ṣe imuṣẹ ofin ti NMDPRA là kalẹ nitori awọn lo ni aṣẹ lati fun awọn eniyan ni iwe ẹri naa.
Ogbeni Aidemenbor salaye pe ajọ NSCDC sabewo si ibudo ti wọn ti n ta gaasi naa ni ibamu pẹlu ofin, o ni ohun to yẹ ki okunrin naa ṣe ni pe ko mu iwe ẹri mo yege rẹ jade.
O salaye pe enikeni to ba kọ lati mu iwe eri jade, ẹtọ ajọ naa ni lati gba awọn irinṣẹ rẹ.
Alukoro naa sọ pe bi wọn ṣe kọ lati yọnda awọn irinṣẹ wọn lo mu kawọn ikọ naa lo ipa pẹlu wọn.
Bakan naa lo ni ikọ yii ko tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ, nitori wọn ṣe iṣẹ wọn ni ibamu pẹlu ofin ni.
























