Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera JOHESU padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlè ìyanṣẹ́lódì fún bíi oṣù mẹ́ta

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera to wọ aṣọ funfun n gbe alailera lọ sibi kan nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Agbarijọpọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera labẹ asia ẹgbẹ JOHESU ti pada sẹnu iṣẹ lonii ọjọ Aje ọjọ kẹsan an oṣu Kinni yii lẹyin ti wọn ti gunle iyanṣẹlodi fun ọjọ mẹrinlelọgọrin.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ JOHESU pinnu lati pada sẹnu isẹ nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Ẹgbẹ JOHESU kede ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade ti wọn ṣe naa pe awọn yoo so iyanṣẹlodi naa rọ lati le fun ijọba lanfaani lati ṣiṣẹ lori awọn nnkan tawọn n beere fun.

Ẹgbẹ JOHESU sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita naa eyi ti alaga ẹgbẹ naa, Kabiru Minjibir ati akọwe ẹgbẹ ọhun, Martin Adekunle, buwọlu pe awọn dupẹ lọwọ araalu fun ifarada wọn ati fun bi ọrọ naa ṣe ye wọn.

Wọn tun rawọ ẹbẹ sawọn eeyan ti iyanṣẹlodi naa ti ṣe ipalara fun wi pe ki wọn fiye denu tori ẹtọ awọn lawọn n ja fun lo jẹ kawọn gunle iyanṣẹlodi naa.

Iyanṣẹlodi naa to pe ọjọ mẹrinlelọgọrin lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ṣakoba fun eto ilera lawọn ile iwosan kaakiri orilẹede Naijiria.

Koda, ọpọ ẹbi awọn alaisan lo gbe awọn eeyan wọn kuro nile iwosan ijọba lọ si ile iwosan aladaani.

Ẹgbẹ JOHESU ko ṣai dupẹ lọwọ Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Godswill Akpabio, adari ile aṣoju-ṣofin l'Abuja, Tajudeen Abbas, awọn alaga igbimọ ile to jokoo lori ọrọ iyanṣẹlodi naa to fi mọ Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi fun ipa ribi ribi ti wọn ko lati ri pe awọn pada sẹnu iṣẹ.

Ẹgbẹ JOHESU tun dupẹ lọwọ apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC fun atilẹyin wọn.

JOHESU: Wo àwọn tó rí owó oṣú Kín-ín-ní ọdún yìí gbà pẹ̀lú ìyanṣẹ́lódì

Aworan abala kan nileewosan to da paroparo

Oríṣun àwòrán, Others

Iyanṣẹlodi ti awọn oṣiṣẹ to n ran awọn eleto ilera lọwọ, Joint Health Sector Unions (JOHESU) gunle ko yipada. Oni ọjọ Ẹti lo pe ọjọ mẹrinlelọgọrin ti wọn ti n ba a bọ.

JOHESU to kun fun akojọpọ awọn ẹka oṣiṣẹ to n ran abala awọn oṣiṣẹ ilera lọwọ nileewosan n beere fun afikun owo oṣu gẹgẹ bi ilana atunṣe (Consolidated Health Salary Structure ), eyi to fi kun owo awọn dokita ati nọọsi.

Wọn ni ko si bi ọbọ ṣe ṣori ti inaki ko ṣe.

Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni wọn ti fowo kun owo oṣu awọn dokita ati nọọsi ti wọn ko fi kun ti awọn oluranlọwọ yii bi wọn ṣe wi.

Ohun ti wọn ṣe gunle iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ bayii niyẹn.

Ṣugbọn ijọba apapọ ninu ipinnu rẹ, sọ pe bi awọn JOHESU ba da iṣẹ silẹ lai ṣe, wọn ko ni i ri owo oṣu gba fun gbogbo asiko ti wọn ba fi daṣẹ silẹ naa.

Oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ti pari, awọn oṣiṣẹ ti gba owo oṣu, ṣugbọn ṣe JOHESU ri gba.

" JOHESU labẹ ijọba Eko ri owo oṣu Kin-in-ni gba, ṣugbọn ijọba apapọ ko sanwo fun awọn JOHESU abẹ wọn''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati mọ ohun to n ṣẹlẹ ni JOHESU, BBC News Yoruba ba Akọwe ẹgbẹ naa fun ipinlẹ Eko, Kabiawu Gbolahan Adegboyega, sọrọ laaarọ oni ti i ṣe ọjọ Ẹti, ọjọ kẹfa, oṣu Keji ọdun 2026.

Kọmureedi Kabiawu ṣalaye pe: "Fun awọn oṣiṣẹ to wa labẹ ijọba apapọ, a gbọ pe wọn ko sanwo oṣu fun wọn loṣu to kọja yii, ṣugbọn fun awa ti a wa labẹ ijọba Eko, awa gba owo oṣu tiwa.

"Yatọ si awọn dokita ati awọn nọọsi ti wọn sanwo fun, awọn oṣiṣẹ yoku leto ilera ko rowo gba. Awọn bii awọn to n ṣiṣẹ ni yara ayẹwo ẹjẹ, awọn to wa lẹka oogun tita ati bẹẹ lọ, ko rowo oṣu wọn gba lọdọ ijọba apapọ.

"Ṣugbọn a ko le sọ, to ba ya nisinyi, wọn le ni awa naa ti a jẹ ti ijọba ipinlẹ ko ni i rowo gba, wọn maa n bẹrẹ kẹrẹkẹrẹ ni. Ko jẹ tuntun si wa, a mọ pe wọn le sun un de ipinlẹ naa.''

Lori igbesẹ to kan fun JOHESU lati gbe, Kabiawu sọ pe awọn ko duro.

O ni aago mẹwaa aarọ ọjọ Ẹti naa ni ipade kan fẹ waye lọdọ awọn JOHESU lati jiroro, ati pe wọn ṣi n ba ijọba paapaa sọrọ.

O ni awọn alaga JOHESU lẹka ijọba apapọ ni yoo ni yoo sọ ohun ti yoo sẹlẹ, sugbọn ko ti i si gbedeke igba ti iyanṣẹlodi naa yoo wa sopin.

Afi tawon ba gbọ ohun ti awọn aṣoju to ba ijọba sọrọ naa ba sọ.

O ni 2014 ni awon ti wa lenu ebe afikun yii, ki i se ohun tawon ṣẹṣẹ bẹrẹ rara.

Ẹ o ranti pe latigba ti iyanṣẹlodi JOHESU yii ti bẹrẹ ni oju awọn alaisan ti n ri to ni awọn ọsibitu ijọba, latari ai si awọn to le kun iṣẹ awọn dokita ati nọọsi lọwọ naa.

Ìjọba ní kò sówó oṣù fẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera JOHESU tó ń yanṣẹ́ lódì nílé ìwòsàn, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yarí

Agarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilera, JOHESU, ti koro oju si aṣẹ ti ijọba apapọ pa wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa to gunle iyanṣẹlodi alailọjọ ko ni gbowo oṣu niwọn igba ti wọn ba si n yan iṣẹ lodi.

Ẹgbẹ JOHESU ni aṣẹ ti ijọba pa naa lodi si ofin, ati pe o tun lodi si ọna ti ijọba n gba pẹtu si aawọ to ba ṣẹlẹ laarin awọn oṣiṣẹ ati ijọba.

Akọwe agba ẹgbẹ JOHESU, Kọmureedi Martin Egbanubi, sọ pe ijọba ko laṣẹ labẹ ofin lati ṣe bẹẹ.

''A fun ijọba ni asiko to to ki a to bẹrẹ iyanṣẹlodi wa, gbedeke ọjọ mẹẹdogun ni a fun ijọba gẹgẹ bi ofin ti la a kalẹ ki a to bẹrẹ iyanṣẹlodi wa.

Ijọba o lagbara lati ma sanwo oṣu fun wa tori a ko ṣiṣẹ, niwọn igba ti ijọba ko tii ṣe nnkan ti a n beere fun.

O digba ti a ba ti lo gbogbo ọna lati yanju ọrọ to wa nilẹ tan ti ko si ọna abayọ mii mọ ni ijọba le gbe iru igbesẹ yii.

Asọyepọ ni a nilo, kii ṣe idunkoko mọ ni, igbesẹ ijọba lati ma sanwo oṣu oṣiṣẹ lasiko iyanṣẹlodi lodi sofin.

Ijọba ni lati tẹle alakalẹ ofin, ki o si wa ojutuu si nnkan ti n a beere ki a le pada sẹnu iṣẹ,'' Egbanubi lo sọ bẹẹ.

Ṣaaju lọjọ kẹjọ oṣu Kinni ọdun yii ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri eto ilera paṣẹ fun gbogbo awọn ọga agba awọn ile iwosan ijọba wi pe ki wọn ma sanwo oṣu fawọn oṣiṣẹ to n yanṣẹ lodi.

Ileeṣẹ ijọba tun rọ awọn adari awọn ile iwosan naa lati wa ọna ti wọn yoo fi di alafo awọn oṣiṣẹ to n yanṣẹ lodi lawọn ile iwosan.

Bakan naa ni ijọba tun sọ pe kawọn adari ile iwosan gba awọn ẹṣọ eleto aabo sawọn ile iwosan ijọba lati le dẹkun iwa ipa tawọn oṣiṣẹ to n yanṣẹ lodi ba fẹ hu sawọn to n ṣiṣẹ.

Lọjọ kẹrinla oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni ẹgbẹ JOHESU to so awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn kii ṣe dokita ati nọọsi pọ gunle iyanṣẹlodi.

Nnkan ti ẹgbẹ JOHESU n yanṣẹ lodi le lori ni aigbe igbesẹ ijọba lori awọn adehun nipa sisan owo oṣu ni ilana CONHESS fawọn oṣiṣẹ eleto ilera ti kii ṣe dokita ati nọọsi.

Ẹgbẹ JOHESU tun n lo iyanṣẹlodi yii lati beere fun awọn nnkan amayedẹrun mii lẹnu iṣẹ bakan naa.

Ibẹru-bojo gbalẹ lawọn ile iwosan latari iyanṣẹlodi ẹgbẹ JOHESU

Lati bi oṣu meloo kan bayii ti ẹgbẹ oṣiṣẹ JOHESU ti gunle iyanṣẹlodi ni ibẹru-bojo ti gbalẹ lawọn ile iwosan ijọba ni Naijiria.

Ọpọ ile iwosan lo da paro paro latari iyanṣẹlodi ti agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ eleto ilera ọhun gunle.

Nigba ti iyanṣẹlodi yii ti jẹ ki iṣẹ pọ fawọn dokita atawọn nọọsi, ko tun jẹ ki ọkan awọn ẹbi awọn alailera naa balẹ.

Nnkan ti ijọba apapọ n sọ ni pe ọpọ nnkan tawọn oṣiṣẹ eleto ilera yii to n yanṣẹ lodi n beere fun lawọn ti n ṣiṣẹ le lori.

Ọpọ eeyan ni a gbọ pe wọn ti n gbe awọn alailera ti wọn gbe lọ sile iwosan ijọba kuro nibẹ lati lọ gba itọju nile iwosan aladaani bayii nitori iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ.