''Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti wà lójúfò fáwọn agbébọn tó ṣèlérí láti ṣèkọlù sí Ikoyi-Ile l'Ogbomoso''

Awọn ọlọpaa wọ aṣọ dudu to nila funfun pẹlu fila lori

Oríṣun àwòrán, Oyo Police Command/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe awọn ẹṣọ eleto aabo ti wa lojufo fawọn agbebọn ti wọn kọ lẹta si Ikoyi-Ile nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso nipinlẹ Oyo wi pe awọn n bọ wa ṣekọlu silu naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Benjamin HUndeyin, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.

Hundeyin sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn agbebọn ti wọn lawọn fẹ ṣe ikọlu si Ikoyi-Ile logunjọ oṣu Kinni yii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ẹṣọ eleto ti n lọ kaakiri gbogbo agbegbe ilu naa lati pese aabo to peye fawọn olugbe ibẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn ẹṣọ eleto aabo ti bẹrẹ si ni dawọn ọkọ duro fun ayẹwo.

Hundeyin ni iwadii ti lọ jinna niluu Ikoyi-Ile lati igba tawọn agbebọn ọhun ti kọ lẹta pe awọn n bọ.

Lẹ́yìn ikú aṣọ́gbó márùn-ún, àwọn agbébọn tún ṣèlérí ìkọlù míràn sí Ikoyi ile

Aworan lẹta ti awọn agbebọn kọ ransẹ si awọn araalu

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa

Awọn olugbe Ikoyi Ile, to wa ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo ni ironu ti doju agba wọn kodo pẹlu bii wọn tun ṣe gba lẹeta ihalẹ lati ọdọ awọn afurasi agbebon.

‎Eyi waye lẹyin ọjọ die ti awọn afurasi agbebon ṣe ikọlu si ọfiisi awọn oṣiṣẹ asọgbo ọba ni ibugbe wọn to wa ni agbegbe Oloko ni ijọba ibilẹ Orire nipinlẹ Ọyọ ti eeyan marun-un si padanu ẹmi wọn.

‎Awọn lẹta ọhun to tẹ ileeṣẹ BBC Yoruba lọwọ ni wọn fi silẹ ni ẹyìn ile kan ti o jẹ ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba ìbílẹ tẹlẹ, Fatai Sa'adu, ní Ọjọru, oṣu kìíní, ọdún 2026.

Lẹta ọhun ni wọn kọ ni ede Gẹẹsi ati Yoruba,, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn yoo kọlu ilu naa ni ogunjọ oṣu kiini , ọdun 2026 , wọn n fọnnu pe ko si ohun ti o le da wọn duro lati ṣe ikọlu naa ni ọjọ ti a sọ.

‎Ohun ti Ọwa ninu lẹta naa nii "Lati Odo Bandit, a o wa ni January 20th, 2026. E duro de wa ati pe ki e mu ra wa le. A wa lati wa fun yin ni ibanuje ni orilede yin. Ni Ikoyi-Ile, Ile Oyo State. E mu ra le fun wa."

‎Awọn lẹta naa ni o ti mu ọpọ awuyewuye jẹyọ ni ìjọba ibilẹ Orire, ti ọpọ olugbe si ti n ko aya soke lori ihalẹ awọn afurasi agbebon naa.

‎Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii - DSP Olayinka Ayanlade

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Nígba ti o n sọrọ lori ihalẹ naa, agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, DSP Olayinka Ayanlade, fidi riri lẹta naa mulẹ, to si ṣalaye wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n ba ẹni ti o ri awọn lẹta naa sọrọ lowolowo, lati le ṣe anfani fun iwadii wọn.‎

‎Ninu ọrọ rẹ, Ayanlade ni; "ẹni ti wọn sọ pe o ri awọn akọsilẹ naa wa ni aago wa lọwọlọwọ ti a n si fi ọrọ wa lẹnu wo, ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹẹrẹ iwaadii ni kikun lati mọ orísun lẹta naa, "

‎O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa nipínlẹ Ọyọ mo riri awọn araalu ati ifowosowọpọ wọn, to si tun rawọ be si wọn lati fayegba ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iṣẹ iwaadii wọn bo ae yẹ.

‎Tẹ ba gbagbe, saaju ni awọn agbebon ṣe ikọlu si ọfiisi ajọ asọgbo ọba to wa ni agbegbe Oloka, ijọba ibilẹ Orire nipinlẹ Ọyọ.

‎Ikolu naa to waye ni nnkan bii aago mẹsan alẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹfa, oṣu Kiini, ọdun 2026, ti iṣẹlẹ naa si ṣekupa aṣọgbo marun un.

‎Gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ṣalaye pe iwadii awọn ẹṣọ alaabo fi han pe awọn agbesunmọmi to ti ẹnu ibode ibomiran wa lo ṣe iṣẹ ibi naa.