Bí ẹbí Fusengbuwa ṣe yọ mí kúrò nínú Ọmọ-Oye fún ìtẹ́ Awujale Ijebu lòdì sófin, KWAM 1 kọ lẹ́tà sí Gómìnà

Oríṣun àwòrán, Prince Dapo Abiodun/X/K1 De Ultimate/Instagram
Gbajugbaja akọrin Fuji, King Wasiu Ayinde Marshal, ti ọpọ mọ si KWAM 1 ti kọ iwe si Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun wi pe kudiẹ-kudiẹ wa ninu ọna ti idile Fusegbuwa fi fẹ yan Awujale Ijebu tuntun.
Ninu lẹta ti K1 fi ranṣẹ si Gomina Abiodun nipasẹ agbẹjọro rẹ, Wahab K. Shittu (SAN) lọjọ kẹjọ oṣu Kinni yii, gbajugbaja olorin Fuji naa sọ pe ki ẹbi Fusegbuwa ṣe agbeyẹwo awọn ofin to rọ mọ iyansipo ọba tuntun sori itẹ Awujale, ki wọn si foun naa lanfaani lati dupo ọhun.
Wasiu ni ẹbi to kan lati jẹ Awujale gbọdọ ṣe nnkan to yẹ ki wọn ṣe, wọn si tun gbọdọ tẹle gbogbo ofin to yẹ ki wọn tẹle.
K1 fẹsun kan awọn adari idile naa wi pe wọn ko fẹ kawọn eeyan kan lanfaani lati wa lara awọn ọmọ-oye to fẹ dupo Awujale.
O ni gbogbo igbesẹ ti ẹbi Fusengbuwa ati ijọba ibilẹ Ijebu Ode ti n gbe lori yiyan Awujale tuntun lo lodi si alakalẹ to yẹ ki wọn tẹle.
Ilumọọka olorin naa tun bẹnu atẹ lu bi idile Fusengbuwa ti sọ pe ki gbogbo ọmọ-oye gba fọọmu, ki wọn si farahan niwaju igbimọ ti yoo ṣayẹwo fun wọn.
K1 ni gbogbo awọn ilana yii lo lodi si ofin awọn lọbalọba ipinlẹ Ogun.
''Awọn olori ẹbi Fusengbuwa ko fẹ kawọn ọmọ-oye kan lanfaani lati kopa ninu iyansipo Awujale tuntun''
Wasiu Ayinde sọ ninu lẹta to kọ si gomina ipinlẹ Ogun pe ''a n fi asiko mu wa si etigbọ yii pe akọwe ijọba ibilẹ Ijebu-Ode kọ iwe si ẹbi Fusengbuwa lati ṣe ipade lati yan Awiujale tuntun laarin ọjọ mẹrinla.
Amọ, iyalẹnu lo jẹ wi pe bi ẹbi yii ti n gbaradi fun ipade ọhun ni ẹnikan ti wọn n pe ni Ọmọba Adeleye Lateef Ademuyiwa to pe ara rẹ ni alukoro ẹbi Fusengbuwa gbe ikede miran jade eyi to sọ pe kawọn ọmọ-oye lọ gba fọọmu, ki wọn si farahan niwaju igbimọ ti yoo ṣayẹwo fun wọn.
Ọjọ kejila oṣu Kinni ọdun yii ni a gbọ pe awọn ọmọ-oye gbọdọ gba fọọmu naa.
A n fi asiko yii sọ pe gbogbo igbesẹ yii ko tọna rara, o si lodi sofin awọn lọbalọba ipinlẹ Ogun.''
Wasiu tun sọ ninu lẹta to kọ naa wi pe awọn olori ẹbi Fusengbuwa ko fẹ kawọn ọmọ-oye kan lanfaani lati kopa ninu iyansipo Awujale tuntun.
K1 tun sọ pe gbogbo ọmọ idile Fusengbuwa lo lẹtọọ lati kopa ninu eto iyansipo Awujale tuntun.
O ni igbiyanju awọn eeyan kan lati gba iwaju gbẹyin lori yiyan Awujale tuntun yoo da wahala silẹ.
Ìdí tí KWAM 1 fi gbé Gómìnà Dapo Abiodun lọ ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ yíyan Awujale Ijebu tuntun tẹlẹ
Ti ẹ o ba gbagbe, loṣu Kejila ọdun to kọja ni gbajugbaja akọrin Fuji, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si KWAM 1 gbe Gomina Dapo Abiodun lọ sile ẹjọ lori ọrọ oye Awujale ilẹ Ijebu.
KWAM 1 beere lọwọ ile ẹjọ giga to wa ni ilu Ijebu Ode lati paṣẹ fun Gomina Abiodun atawọn marun un mii wi pe ki wọn ma le gbe igbesẹ kankan lori ẹni ti yoo jẹ Awujale Ijebu lọwọ yii.
Awọn mii ti ẹjọ naa kan ni alaga ijọba ibilẹ Ijebu Ode, kọmiṣọna ijọba ibilẹ ati ọrọ oye nipinlẹ Ogun, akọwe ijọba ibilẹ Ijebu Ode, alaga igbimọ to n ri si ọrọ to niṣe pẹlu Awujale ati alaga idile ọba Fusengbuwa.
KWAM 1 wa lara awọn eeyan to ti fi erongba wọn han lati jẹ Awujale ilẹ Ijebu lẹyin iku Ọba Sikiru Adetona.
Idile Jadiara to tan mọ idile ọba Fusengbuwa ni agbaọjẹ akọrin Fuji naa loun ti wa.
Amọ, idile naa lawọn o mọ ọ ri, wọn ni Olori Ọmọba Ilẹ Ijebu ko tan mọ awọn rara.
Ninu ẹjọ ti o pe pẹlu nọmba HC3/238/2025, K1 ni ẹjọ naa wa ni ibamu pẹlu aṣẹ 38 abala kẹrin ati aṣẹ 39 abala kinni ile ẹjọ giga Ijebu Ode ati abala kérindinlogoji iwe ofin oriẹlede Naijiria.
Gbajugbaja olorin Fuji naa sọ pe ki ile ẹjọ paṣẹ pe ki gbogbo eeyan to lọwọ ninu yiyan Awujale Ijebu tuntun duro na titi ti ile ẹjọ yoo fi gbẹjọ oun tan.
Ṣugbọn ile ẹjọ ti yi ẹjọ ti K1 pe danu wi pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.
Lẹyin naa si ni gbajugbaja akọrin naa kede pe oun ti yọwọ ninu ọrọ ọba jijẹ ọhun.















