Kà nípa Li, ọkùnrin aláàbò ara tó tọrọ báárà àmọ́ tó padà di dókítà

Oríṣun àwòrán, Dr Li Chuangye
- Author, Benny Lu
- Role, BBC Chinese
- Author, Dr Li Chuangye
- Author, Vibeke Venema
- Role, BBC World Service
- Author, Dr Li Chuangye
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Dokita ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni Li Chuangye ti iroyin nipa bo ṣe fẹran ati maa gun oke nla milẹ titi ni China. O ba arun polio finra, eyii to mu ko maa tọrọ bara lọmọde ko to di ẹni to bẹrẹ si n kawe lọmọ ọdun mẹrindinlogun.

Oríṣun àwòrán, Dr Li Chuangye
Agbegbe Henan ni wọn bi Li Chuangye si lọdun 1988 ko to lugbadi arun polio nigba to pe ọmọ oṣu meje.
Arun naa lo gba ẹsẹ lọwọ rẹ to si di ẹni to n rakoro.
Gẹgẹ bii ọmọde, Li ni afojusun lati kawe ati lati maa gbe baagi iwe sẹyin bii awọn akẹgbẹ rẹ amọ lọpọ igba ni wọn maa n fi ṣe yẹyẹ.
Nigba to wa lọmọ ọdun mẹsan an, awọn obi rẹ gbọ pe yoo le rin lẹyin iṣẹ abẹ kan, wọn si ya owo lati ṣiṣẹ abẹ naa.
Ṣugbọn lẹyin iṣẹ abẹ ọhun, pabo lo pada ja si, eyii to mu ko fẹ fi ironu pa ara rẹ.
Iya rẹ sọ fun pe ko ma sọ ireti nu o si di ọrọ iyanju naa mu.
Lẹyin eyii ni alejo kan ni oun nilo awọn ọmọde ti ko le rin lati maa ta lọfinda ninu tẹmpili, ọkunrin ọhun si ṣeleri pe oun yoo maa fi owo ranṣẹ si awọn obi wọn.
O ni "Awọn obi mi ko kọkọ faramọ amọ mo ri gẹgẹ bii anfani lati pa owo wọle lati ran awọn obi mi naa lọwọ."
O ni lẹyin naa loun gba lati tẹle ọkunrin ọhun.

Oríṣun àwòrán, Dr Li Chuangye
Iṣẹ bambiala loju titi
O ṣeni laanu pe irọ ni, ko si iṣẹ kankan nibikankan.
Li ni niṣe lọkunrin ọhun bẹrẹ si n fi oun atawọn ọmọde mii ṣiṣẹ bambiala loju titi fun odidi ọdun meje gbako.
Lọjọ akọkọ to de akata ọkunrin ọhun, o ni ọkan lara awọn ọmọ ti oun ba nibẹ kilọ fun oun pe ki oun ṣiṣẹ karakara, bi bẹẹ kọ oun yoo jiya, eyii to ri bẹẹ nikẹyin.
Laarọ ọjọ keji ni wọn gbe Li sita ti wọn si fi ẹsẹ rẹ kọ ọrun rẹ ki awọn eeeyan le maa ṣaanu rẹ lati pa owo.
Gẹgẹ bii ọmọde, ko mọ eredi ti awọn eeyan ṣe n fi owo sinu igba to wa niwaju oun titi di igba ti ẹnikan bere eredi to fi n tọrọ owo lasiko to yẹ ko wa nile ẹkọ,
O ni "ni abule wa, ohun itiju ni ki eeyan maa tọrọ owo, mi o mọ pe mo ti n tọrọ bara ki n to mọ, eyii to ba mu ninu jẹ gidi.
Gbogbo owo ti Li n pa lojumo lo n lọ sapo ọga rẹ.
Lẹyin to mọ pe bara loun tọrọ, Li gba lati maa ṣe iṣẹ ọhun lọ lọna ati tọju awọn obi rẹ ti ko rọwọ jọri.

Oríṣun àwòrán, Dr Li Chuangye
Ọna abayọ nipa eto ẹkọ
Lẹyinorẹyin, ayipada ọtun de ba aye Li lẹyin to ri iwe iroyin kan to si ṣakiyesi pe oun ko le ka a.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni lasiko naa, o si pinnu lati lọ sile ẹkọ.
O ni "Mi o le kọ, mi o le ka, mo si woye pe nipa eto ẹkọ nikan ni mo le fi tun aye mi ṣe."
Pẹlu atilẹyin awọn obi rẹ, Li bẹrẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ pẹlu awọn ọmọ to fi ọdun mẹwaa ju lọjọ ori.
O ni lọjọ akọkọ oun nile ẹkọ, niṣe lawọn akẹkọọ to ku bẹrẹ si n wo oun tiyanu-tiyanu amọ oun ko ri ro.
Li mura si ẹkọ rẹ bo tilẹ jẹ pe ko rọrun rara.
Laarin ọdun mẹsan an, o pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama.
Nigba ti asiko to fun lati lọ sile ẹkọ giga, o yan lati kẹkọọ imọ iṣegun.
O ni oun ro o pe ti oun ba kọ iṣẹ naa, oun yoo le ṣe iwadii ijinlẹ nipa arun to sọ oun di ẹni ti ko le rin.
Ati pe oun yoo le ṣeranwọ fun awọn ẹlomiran to wa ninu irufẹ ipo oun.

Oríṣun àwòrán, Dr Li Chuangye
Nigba to pe ẹni ọdun marundinlọgbọn, Li wọ ile ẹkọ giga lati kẹkọọ imọ iṣẹgun.
O ni o ṣoro fun lati maa sa kiri lọ tọju awọn alaisan lasiko ikẹkọọ naa bii awọn akẹgbẹ oun, amọ oun fori ti i.
Yatọ si iwe kika, Li tun fẹran lati maa gun awọn oke nla-nla lasiko isinmi ikẹkọọ.
Ni bayii, o ti ni ile iwosan kekere kan si abule Xinjiang nibi to ti n tọju awọn eeyan lọsan ati loru.
Itan arakunrin naa ti di ohun iwuri fun ọpọ eeyan kaakiri ilẹ China bayii, eyii to ni oun gbagbọ pe yoo ṣe atunṣe si oju ti awọn eeyan fi n wo awọn akanda.
O ni "Ọpọ eeyan lo n wo awọn akanda bii ẹni ti ko le jẹ nnkankan.
"Nigba mii ti mo ba lọ sile ounjẹ, awọn kan maa n ro pe onibara ni mi, wọn a si sọ fun mi pe ko si ounjẹ.
"Ṣugbọn awọn miran n wu iwa to dara si mi."

Oríṣun àwòrán, Dr Li Chuangye
Igbeaye to yatọ lai ro ohun atijọ
Ọpọ eeyan lo ti bere lọwọ Li eredi ti ko fi pe ọkunrin to fi tọrọ bara lẹjọ.
Nigba to n fesi, o ni ọrọ naa ti di afisẹyin ti Egungun n fi aṣọ, oun ko si fẹ pada sibẹ mọ bo tilẹ jẹ pe ara itan aye oun ni.
Li sọ pe "Nigba ti mo ni anfani lati lọ kawe, mi o bikita mọ nipa nnkan ti ẹnikẹni ba n sọ tabi ro. Mo ṣakiyesi pe awọn ọrọ naa ko lẹsẹ nilẹ."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọpọ awọn akanda ni ẹru maa n ba lati tẹsiwaju ninu igbe aye wọn latari pe wọn n bẹru ohun ti araye yoo sọ.
"Amọ fun emi o, mi o ro bẹẹ rara, niṣe ni mo n fi idi mi wọlẹ laakiri ile ẹkọ ati igbi gbogbo ti mo n lọ lai tiju, mo si n ran awọn akanda ẹgbẹ mi lọwọ pẹlu.
"Pẹlu igboya ni mo fi n ṣe bẹẹ, mi o tiju, bẹẹ ni mi o bikita ohun ti awọn eeyan n sọ."
Dr Li Chuangye ba Outlook sọrọ lori ikannni BBC World Service















