Kí nídìí táwọn olùwọ́de fi gba gbogbo ìgboro orílẹ̀ èdè Iran?
- Author, David Gritten
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùfẹ̀hónúhàn káàkiri orílẹ̀ èdè Iran ni wọ́n ń ṣe ìwọ́de ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà àtàwọn ìlú míì.
Ìfẹ̀hónúhàn alálàáfíà náà ló ń wáyé ní ìlú Tehran àti Mashhad ní ìrọ̀lẹ́ lọ́jọ́bọ̀, táwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kò sì gbìyànjú láti tú wọn ká gẹ́gẹ́ bí fídíò kan tí iléeṣẹ́ ìròyìn BBC Persian rí kan ṣe fihàn.
Láìpẹ́ rẹ̀ ni ojú òpó ayélujára kò ṣiẹ́ mọ́ níbẹ̀.
Nínú fídíò náà làwọn olùwọ́de ti ń pè fún gbígba ìjọba lọ́wọ́ olórí orílẹ̀ èdè náà, Ayatollah Ali Khamenei, tí wọ́n sì ń pè fún ìpadàbọ̀ Reza Pahlavi, ọmọ shah tẹ́lẹ̀ tó tis á kúrò nínú ìlú, ẹni tó rọ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ láti ṣèwọ́de káàkiri gbogbo ìlú.

Oríṣun àwòrán, X
Ọjọ́bọ̀ ló pé ọjọ́ kejìlá tí ìwọ́de ti ń wáyé ní orílẹ̀ èdè náà látàrí bí owó ìlú náà ṣe ti já wálẹ̀ lọ́jà àgbáyé, tí ìwọ́de náà sì ti tàn káàkiri àwọn ìlú tó lé ní ọgọ́rùn-ún káàkiri ẹkùn mọ́kànlélọ́gbọ̀n tó wà ní orílẹ̀ èdè náà gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ṣe sọ.
Àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùjókòó, Human Rights Activist News Agency (HRANA) sọ pé èèyàn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé márùn-ún ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìwọ́de náà.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mẹ́jọ ló ti jáde láyé, táwọn ọlọ́pàá sì ti nawọ́ gán olùwọ́de 2,270.
Àjọ ajáfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn Iran Human Rights tó fi Norway ṣe ibùjókòó ní àwọn olùwọ́de márùndínláàádọ́ta tó fi mọ́ àwọn ọmọdé mẹ́jọ làwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti ṣekúpa.
BBC Persian ti fìdí ikú èèyàn méjìlélógún múlẹ̀, tí àwọn aláṣẹ Iran sì ti kéde ikú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mẹ́fà.
Ìwọ́de yìí ló lágbára jùlọ ní Iran láti ọdún 2009, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Iran ṣèwọ́de tako èsì ìbò kan tó wáyé nígbà náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ alátìlẹyìn ẹgbẹ́ alátakò ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìwọ́de náà, tí wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ sí àhámọ́.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́bọ̀, àwọn fídíò tó gba orí ayaélujára tí BBC Persian rí ṣàfihàn ọ̀pọ̀ àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń rìn káàkiri òpópónà Mashhad, ní àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn olùwọ́de náà ń kọrin "kí ẹ̀mí shah gùn", òpin ìjà nìyí, Pahlavi máa padà.
Nígbà tó di àsìkò kan, àwọn olùwọ́de kan ń gun orí òkè láti yọ gbogbo ẹ̀rọ ayàwòrán tó wà ní àwọn òpópónà náà.
Bákan náà ni fídíò míì ṣàfihàn ọ̀pọ̀ àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń yíde ní ìlà oòrùn Tehran.
Àwọn fídíò míì ṣàfihàn báwọn olùwọ́de ṣe ń kọrin pé "ikú sí àpàṣẹ wà á ní ìlú Isfahan. Ní Tabriz, àwọn olùwọ́de ń kọrin pé, "ẹ má bẹ̀rù, a jọ wàpọ̀ ni."
Wọn kò fààyè gba BBC àtàwọn iléeṣẹ́ ìròyìn láti máa kọ ìròyìn ní Iran, àwọn nǹkan tó wà lórí ayélujára ni à ń gbọ́kànlé láti fi mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Middle East Images / AFP via Getty Images
Ìwọ́de náà ló ń wáyé lẹ́yìn tí Reza Pahlavi, tí wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ lọ́dún 1979, tó ń gbé ní Washington DC, tó sì rọ àwọn èèyàn Iran láti ṣèwọ́de láti bèèrè ẹ̀tọ́ wọn.
Bákan náà ló tún ní kí ìwọ́de náà tún tẹ̀síwájú ní aago mẹ́jọ alẹ́ lọ́jọ́ Ẹtì.
Àwọn àjọ ajáfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn mẹ́tàdínlógún, tó fi mọ́ Narges Mohammadi nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde ní orílẹ̀ èdè náà nílò láti yípadà kúrò ní ìjọba tí wọ́n ń lò nítorí ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè Iran.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ti ìjọba Iran sọ pé ìwọ́de kò wáyé ní àwọn agbègbè kan tí wọ́n sì ṣàfihàn àwọn àdúgbò tí kò sí olùwọ́de kankan níbẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, àjọ NetBlocks sọ pé ìwádìí fi hàn pé kò sí ojú òpó ayélujára ní Iran lọ́wọ́ yìí.
Kò dín ní èèyàn mẹ́tàdínlógún táwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti ṣekúpa ní Ilam, Kermanshah àti Lorestan. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ ẹ̀yà Kurdish tàbí Lor gẹ́gẹ́ bí àjọ ajáfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn Hengaw ṣe sọ.
Ní ọjọ́bọ̀ ni ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti tẹmpẹlẹmọ ìdúnkokò rẹ̀ láti ṣèkọlù sí Iran táwọn aláṣẹ bá fi lè pa àwọn olùwọ́de kankan.
Ó ní mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá àwọn olùwọ́de, èyí tó ṣeéṣe kó wáyé, tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa kọlù wọ́n gidi," ó sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú Hugh Hewitt Show.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò míì, akọ̀wé ìsúná Amẹ́ríkà, Scott Bessent sọ pé ètò ọrọ̀ ajé Iran wà lórí okùn.
Ó fi kun nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pé Trump kò fẹ́ kí wọ́n ṣe ìkọlù sáwọn olùwọ́de kankan mọ́.
Ààrẹ Iran, Masoud Pezeshkian ti ṣáájú sọ fáwọn òṣìṣẹ́ ààbò láti ri dájú pé wọ́n ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń ṣe é pẹ̀lú àlááfíà.
Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 2025 ni ìwọ́de bẹ̀rẹ̀ ní Iran lẹ́yìn táwọn ọlọ́jà bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de nítorí owó orílẹ̀ èdè náà tó já wálẹ̀ ní ọjà àgbáyé.
Lẹ́yìn náà láwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì darapọ̀ mọ́ ìwọ́de náà, tó sì tàn wọn àwọn ìlú míì.
Nínú àtẹ̀jíṣẹ́ kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí BBC, obìnrin kan ní Tehran sọ pé ìpọ́njú ló fa ìwọ́de náà nítorí ayé kò dún-ún fáwọn mọ́.
Ẹlòmíràn sọ pé òun ṣe ìwọ́de nítorí ọjọ́ ọ̀la ni wọ́n ti jí ma òun lọ́wọ́.













