Ipa wo ni bí Peter Obi àti Kwankwaso ṣe darapọ̀ mọ́ NDC yóò ní lórí ìbò ààrẹ ọdún 2027? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, NDC/X
Awuyewuye si n lọ lori bi oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu LP tẹlẹ, Peter Obi ati Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ ri, Rabiu Kwankwaso, ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) lanaa ọjọ Aiku ọjọ kẹta oṣu Karun un yii.
Lati inu ẹgbẹ oṣelu ADC to jẹ ọkan lara ẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria ni Obi ti darapọ mọ NDC.
Ọpọ eeyan lo ti woye pe bi Obi ati Kwankwaso ṣe darapọ mọ NDC le ṣakoba fun ẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria ṣaaju ibo aarẹ ọdun 2027.
Ninu ọrọ rẹ, Obi sọ pe igbesẹ oun ṣe pataki nitori orilẹede Naijiria nilo atunṣe ni kiakia lagbo oṣelu.
''Igbesẹ mi yii kii ṣe fun emi nikan tabi fun oṣelu, amọ, o ni i ṣe pẹlu kiko awọn eeyan ti wọn le doola Naijiria jọ lọwọ yii ninu iṣoro ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, eto aabo to mẹhẹ ati iyapa to wa laarin awọn ọmọ Naijiria.
A gbagbọ pe a le doola Naijiria ti a ba jọ ṣiṣẹ pọ.
Obi ati Kwankwaso yoo ko awọn alatilẹyin wọn lọ si inu ẹgbẹ NDC, ọpọ awọn ọdọ lati ẹkun guusu ati aarin gbungbun Naijiria lo n ṣatilẹyin fun Obi.
Kwankwaso naa yoo kawọn ololufẹ rẹ lati ẹkun ariwa lọ si inu ẹgbẹ oṣelu NDC.
Kwankwaso ti figba kan ri dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, ki o to fi ẹgbẹ ọhun silẹ.
Obi lo ṣe ipo kẹta ninu ibo aarẹ ọdun 2023, nigba ti Kwankwaso ṣe ipo kẹrin ninu eto idibo naa.
Amọ, nnkan ti eyi tumọ si ni pe ko ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ ADC nibi ti Obi ti kuro mọ.
ADC ni ọpọ eeyan ti ri gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu alatako to le koju APC ninu ibo aarẹ ọdun 2027 tori awọn eekan lagbo oselu bii Sẹnẹtọ David Mark, Ọgbẹni Rauf Aregbesola, Alhaji Atiku Abubakar ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn ọpọ lo ti n woye pe ẹgbẹ oṣelu alatako le ma lagbara tọ bẹ mọ pẹlu bi Obi ti fi ẹgbẹ ADC silẹ lọ NDC.
''Ata akara ti kan ran ikọ ni bi Obi ṣe darapọ ẹgbẹ NDC''
Ileeṣẹ aarẹ ti sọrọ lori bi Obi ati Kwankwaso ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NDC.
Agbẹnusọ fun Aarẹ Bola Tinubu sọ pe kii ṣe nnkan tuntun ni bi Obi ati Kwankwaso ṣe darapọ ẹgbẹ mii.
O ni iru nnkan to maa n ṣẹlẹ lagbo oṣelu ni.
''A ko le fẹ ibaṣepọ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu ku, amọ, ijọba to wa lode yoo tẹsiwaju pẹlu atunṣe eto ọrọ aje Naijiria.
Ijọba ko si tun ni dẹkun akitiyan rẹ lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ.
Oniruuru ẹgbẹ oṣelu lo maa n dije ninu eto idibo lati ọdun 1999 ti Naijiria ti pada si eto ijọba awarawa.
Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu APC lo ti n lewaju fun bi ọdun meloo sẹyin bayii papaa julọ lati ọdun 2015 di akoko yii.
''Obi-Kwankwaso n sọ nipa iṣoro ati anfaani ẹgbẹ alatako ninu eto oṣelu Naijiria''
Ẹwẹ, awọn onwoye lagbo oṣelu ti sọ pe bi Obi ati Kwankwaso ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NDC n sọ nipa anfaani ati iṣoro ti ẹgbẹ oṣelu alatako n koju ninu eto oṣelu Naijiria.
Wọn ni loootọ ni eyi le tumọ si pe ẹgbẹ alatako yoo lanfaani lati koju ẹgbẹ oṣelu ijọba to wa lode, amọ, wọn ṣalaye pe iru ẹgbẹ oṣelu alatako bayii le koju iṣoro pẹlu irufẹ awọn oloṣelu ti wọn jọ n ṣiṣẹ pọ.
Eleyii le ṣẹlẹ tori irufẹ awọn oloṣelu to wa ninu ẹgbẹ alatako ati ẹkun ti wọn ti wa ṣe pataki ju ofin ẹgbẹ lọ lagbo oṣelu Naijiria.
Pẹlu bi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 ṣe ku bii oṣu mẹsan an bayii, ko sẹni to le sọ bo ya didarapọ mọ ẹgbẹ alatako yoo so eso rere tabi ko ni so eso rere.
Ohun ti a mọ ni pe igbesẹ Obi ati Kwankwaso tun ti jẹ kawọn eeyan maa sọ pe o ṣoro lati sọ nnkan to le ṣẹlẹ ninu eto idibo ọdun 2027.
Peter Obi àti Kwankwaso darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú NDC

Oríṣun àwòrán, @CrownprinceCom2
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Peter Obi, ati ojugba rẹ lati ipinlẹ Kano, Rabiu Musa Kwankwaso, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC).
Obi, to dije du ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP), nigba ti Kwankwaso du ipo labẹ aisai ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People's Party (NNPP) lọdun 2023 ti gba kaadi gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu NDC lonii ọjọ Aiku.
Awọn agba oloṣelu mejeji ti wọn kuro ninu ẹgbẹ African Democratic Congress (ADC), ni gomina ipinlẹ Baylesa tẹlẹ, Seriake Dickson gba wọle sinu ẹgbẹ NDC.
Igbesẹ yii lo n waye ni imurasilẹ fun eto idibo Aarẹ ti yoo waye lọdun 2027.
Ṣaaju ni Obi ti kọkọ sọ pe kii ṣe ẹtanu Atiku Abubakar ati David Mark lo mu oun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, bi ko ṣe pe awọn to da ẹgbẹ oṣelu Labour ru naa ti n rapala wọ inu ẹgbẹ ọhun.
Peter Obi fi ẹgbẹ́ òṣèlú ADC sílẹ̀, ṣàlàyé èrèdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀

Oríṣun àwòrán, Peter Obi
Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo ọdun 2023 ti kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn iṣoro abẹle to n ba ẹgbẹ ọhun finra lo jẹ ki oun kuro nibẹ.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade ti Obi fi lede loju opo X rẹ lọjọ Aiku.
Ninu atẹjade naa, o mẹnuba bi eto oṣelu Naijiria ṣe buru to, ati bi awọn araalu ṣe maa n gbogun ti awọn gbajumọ lawujọ.
O ni oun ko fi ẹgbẹ oṣelu ADC silẹ latari ẹtanu pẹlu awọn eekan inu ẹgbẹ ọhun bii alaga rẹ, David Mark, tabi igbakeji Aarẹ Naijiria rẹlẹ, Atiku Abubakar.
Peter Obi ṣalaye pe rogbodiyan inu ẹgbẹ ADC, eyii to n farajọ ohun toun dojukọ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour lo mu oun fi ẹgbẹ naa silẹ.
Gomina ipinlẹ Anambra nigba kan ri naa sọ pe "Awọn alagbara Naijiria kan ti wọn da rogbodiyan abẹle silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ti mo fi kuro ninu ẹgbẹ ọhun tun ti n wọ inu ẹgbẹ oṣelu ADC."
O mẹnuba bi oniruru igbẹjọ to n waye lemọlemọ, ipinyna laarin awọn ọmọ ẹgbẹ, bi awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe n fura si ara wọn ṣe n mu oju ẹgbẹ naa kuro ninu ohun to yẹ ko gbajumọ.
Ninu ọrọ rẹ, o tun ṣalaye pe awọn eeyen n wo otitọ ṣiṣẹ ati iwa irẹlẹ gẹgẹ bii iwa ojo, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu ẹnikẹni to ba fẹ ṣe ohun to tọ ati ati eyii to yẹ.
Obi ni "Koda, laarin ibi ti eeyan ti n ṣiṣẹ takuntakun, wọn n ṣe onitọhun gẹgẹ bii alejo."
O tẹsiwaju pe oun atawọn alatilẹyin ni lawọn eeyan maa n sọ oko ọrọ si bo tilẹ jẹ pe wọn m gbiyanju tiwọn ki nnkan le dara.
O tẹsiwaju pe oun ko du ipo Aarẹ nitori oun n wa agbara, bikoṣe pe oun n wa orilẹede ti ara yoo ti tu gbogbo mutumuwa.
"Mi o fi tipatipa sọ pe mo fẹ di Aarẹ, igbakeji Aarẹ tabi agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, ohun to ka mi lara ni orilẹede ti gbogbo nnkan yoo ti dẹrun fun gbogbo araalu."
Obi ko mẹnuba inu ẹgbẹ mii to n lọ bayii amọ o ti sọ pe bo tilẹ jẹ oun ti fi ADC silẹ, ohun to jẹ oun logun ni ki Naijiria dara.




























