Ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé: Ìdí tí wọ́n fi yan ọjọ́ àkọ́kọ́ oṣù Karùn-ún?

Aworan oṣiṣẹ to n gbin ododo niwaaju patako ikede ọjọ awọn oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ yii ni wọn ya sọtọ lati mọriri igbiyanju ati ilakaka awọn oṣiṣẹ kaakiri agbaye.

Lọdọọdun, ti ọjọ yii ba pe, ifẹhonuhan maa n waye kaakiri agbaye.

Awọn oṣiṣẹ, aṣoju wọn gbogbo yoo maa beere itọju to peye.

Nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ, awọn ajafẹtọọ ọmọniyan, atawọn ti wọn n pe fun ayipada lo maa n lọwọ si ayajọ yii.

Bakan naa si lawọn ẹgbẹ oṣiṣe kan maa n da si i.

Bo tilẹ wa jẹ pe orilẹ-ede Amẹrika ni wọn ti n fẹhonu han ju lori awọn oṣiṣe, ọjọ Mọnde akọkọ ninu oṣu kẹsan-an ni wọn maa n ṣe tiwọn.

Báwo ló ṣe bẹ̀rẹ̀ gan-an?

Aworan igba ti wọn ju ado oloro lasiko ifẹhonuhan Haymarket lọjọ kẹrin oṣu karun-un ọdun 1886

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni 1886, awọn aṣoju oṣiṣẹ l'Amẹrika bẹrẹ iyanṣẹlodi. Wọn n beere wakati mẹjọ lojumọ lati ṣiṣẹ.

Wọn ṣe eyi ni ibamu pẹlu atunto ti oyinbo Gẹẹsi kan, Robert Owen, gbe kalẹ.

Robert lo gbe eto iṣẹ ati isinmi lẹyin iṣẹ kalẹ, o pe e ni Wakati mẹjọ iṣẹ, mẹjọ idaraya ati mẹjọ isinmi. ( "eight hours’ labour, eight hours’ recreation, eight hours’ rest".)

Ṣe nigba naa, iṣẹ laago n ṣe ku ni, ko si aaye isinmi rara ni awọn ileeṣẹ gbogbo.

Iyanṣẹlodi to waa lagbara julọ, waye lọjọ akọkọ oṣu karun-un. Ko si din ni ẹgbẹrun lọna ogoji oṣiṣẹ (40,000 workers) ti wọn kora jọ lati daṣẹ silẹ.

Ni gbogbo igba naa, Chicago ni okun ọrọ aje Amẹrika, ibẹ si ni awọn onileeṣẹ pọ si julọ.

Idaṣẹsilẹ awọn oṣiṣẹ naa ko waa tu irun kan lara awọn to gba wọn siṣẹ, wọn ko da wọn lohun.

Lẹyin ọjọ diẹ, ẹgbẹrun awọn oṣiṣẹ mi-in tun darapọ mọ idaṣẹ silẹ naa.

O pada di ohun ti ifẹhonuhan waye, ti ẹnikan padanu ẹmi nigba tawọn ọlọpaa ṣina ibọn bolẹ, eeyan pupọ si farapa.

Ifiyajẹni awọn ọlọpaa yii lo mu awọn olori oṣiṣẹ ṣeto ifẹhonuhan mi-in, eyi to waye lọjọ kẹrin oṣu karun-un, ni gbagede gbajugbaja ọja Chicago, Haymarket Square.

Nibẹ lẹnikan ti wọn o mọ donii yii ti ju bọmbu lu awọn ọlọpaa, ọlọpaa meje ku, metadinlọgọrin (67) si farapa.

Bakan naa, mẹrin ninu awọn to ju bọmbu naa padanu ẹmi, eeyan ọgbọn (30) mi-in si farapa.

Lẹyin rogbodiyan ti wọn pada fi sọri ọja Haymarket yii, eeyan mẹjọ ni wọn dajọ iku fun ninu awọn to bẹrẹ ifẹhonuhan naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ridi ẹ fi mulẹ pe wọn jẹbi ẹsun ipaniyan, sibẹ, ẹmi wọn lọ si i.

Nigba to waa di 1889, ọdun kẹta iṣẹlẹ naa, ipinnu kan waye lati ṣeranti awọn iṣẹlẹ naa lọjọ awọn oṣiṣẹ.

Gbogbo awọn ajafẹtọọ ọmọniyan tọrọ naa kan lo peju, aṣoju oṣiṣẹ si wa lari orilẹ-ede ogun (20 countries).

Àwọn orílẹ̀-ede mí-ìn náà tẹ́wẹ́ gba àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́

Rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Chicago yii lo jẹ iwuri ati iṣipaya fawọn yooku ti wọn ko ti i darapọ mọ wọn tẹlẹ. Awọn naa si bẹrẹ si i sami ọjọ yii.

Ni Guusu orilẹ-ede Yuroopu, awọn eeyan Slovenia ati Croats ni wọn kọkọ ṣayẹyẹ ọjọ awọn oṣiṣẹ.

Iṣẹ aṣelaagun fun ọpọlọpọ wakati pẹlu owo taṣẹrẹ ti wọn n san fun wọn, lo mu awọn eeyan Serbia ṣeto iwọde tiwọn ni 1893.

Ayajọ awọn oṣiṣẹ gan-an ni wọn gbe iwọde naa si.

Lẹyin ti Ogun Agbaye akọkọ pari, ti ayipada rere ti n ba awọn oṣiṣẹ, ti idagbasoke ti n de pẹlu iyanju awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ni Russia, o dohun ti awọn oṣiṣẹ n beere ohun gbogbo to tọ si wọn kaakiri aye.

Ni Germany, ayajọ oṣiṣẹ di ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ, ni 1933, lẹyin igba ti ẹgbẹ Nazi gbajọba.

Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn

Aworan awọn eeyan nibi ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ ni Belgrade, 1950

Oríṣun àwòrán, Museum of Yugoslavia

Lẹyin ti Ogun Agbaye keji pari, to di ajaye, ohun gbogbo yipada lori atẹ agbaye.

Eto oṣelu ati ọrọ aje dohun ti wọn sami rẹ daadaa.

Fun ọpọlọpọ ọdun ni wọn fi n ṣayẹyẹ ọjọ awọn oṣiṣẹ ni awọn orilẹ-ede bii Cuba, Soviet Union aye ọjọun ati China.

Wọn ya a sọtọ bii ọkan ninu awọn ọjọ isinmi pataki.

Bi wọn yoo ba ṣayẹyẹ naa, gbagede to tẹju ni wọn maa n lo. Bii iru eyi ti wọn ṣe ni gbagede Red Square, ni Moscow.

Awọn eeyan nla nla niluu lo maa n peju sibẹ, o si tun duro bii agbara ologun awọn Soviet.

Awọn ajafẹtọọ gbagbọ pe sisami ọjọ oṣiṣẹ ati yiya ọjọ naa sọtọ fun isinmi yoo jẹ kawọn oṣiṣẹ Europe ati Amẹrika parapọ lati beere ẹtọ wọn.

Bakan naa lo ri ni Yugoslavia, awọn naa kede ayajọ oṣiṣẹ ni 1945.

Wọn yan bii ologun ṣajọyọ rẹ ni, wọn si kede rẹ fungba pipẹ.

Kaakiri aye lonii, niṣe ni awọn oṣiṣẹ maa n beere ẹtọ wọn ni gbogbo ayajọ ti wọn fi sọri wọn yii. Awọ ko ka oju ilu.

O ṣe pataki lati fun wọn lohun to tọ si wọn, pẹlu bi ìṣẹ́ ati oṣi ṣe pọ nilẹ, ti awọn mi-in ko si riṣẹ kankan ṣe.

Ọpọ orilẹ -ede lo jẹ pe afikun owo oṣu ti wọn n san fun oṣiṣẹ ko mu iyatọ kankan ba, nitori ojoojumọ ni ohun ti wọn nilo n wọn si i gẹgẹ bi ajọ International Labour Organization (ILO) ṣe ṣalaye ninu afojusun wọn fun ọdun 2024.

Lọdun to kọja, wọn ni onka awọn oṣiṣẹ ti wọn n gbe ninu iṣẹ ati oṣi to lagbara tun gunke si i ni.

Awọn ti owo wọn ko to dọla meji aabọ lọjọ kan ṣoṣo.

Ni ti awọn ti iya to n jẹ wọn mọ niwọn ninu awọn oṣiṣẹ, ILO sọ pe awọn naa n pọ si i ni . Iyẹn awọn ti owo wọn ko to dọla mẹta aabọ ($3.65) lojumọ.

Ida mẹjọ aabọ miliọnu (8.4m) ni ajọ ILO pe wọn bayii.