Ohun mánigbàgbé méje nípa àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ May 1 lágbáyé

Awọn oṣiṣẹ nibi aṣeyẹ kan

Oríṣun àwòrán, other

Ni ọjọ kini oṣu karun ọdun ni ayajọ awọn oṣiṣẹ kaakiri agbaye.

Naijiria pẹlu darapọ gbogbo agbaye lati sami ayajọ yii lọdun 2023, eyi ni awọn koko meje kan to ṣe pataki lati mọ nipa ayajọ oṣiṣẹ, eyi ti a ya sọtọ lati fọnrere awọn ipa pataki ti awọn oṣiṣẹ n ko.

  • Ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni ayajọ awọn oṣiṣẹ maa n jẹ ni ọpọlọpọ orilẹede jakejado agbaye. Ọdun 1886 ni itan sọ pe ayajọ yii jẹyọ̀ lasiko ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ni orilẹede Amẹrika fi gunle iyanṣẹlodi lati beere pe awọn oṣiṣe ko gbdọ ṣe iṣẹ ju wakati mẹjọ lọ mọ lojumọ.
  • Gẹgẹ bi itan ṣe sọ, ni nnkan bii igba ọdun sẹyin ni ọrọ ayajọ oṣiṣẹ bẹrẹ si ni gbilẹ sii nigba ti awọn oṣiṣẹ bẹrẹ si nii beere fun igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, owo oṣu to ṣe e mu yangan, ati adinku iye wakati ti oṣiṣẹ fi n ṣiṣẹ lojumọ.
  • O le ni ọgọrin orilẹede ti ajọyọ ayajọ oṣiṣẹ ti maa n waye ninu eyi ti orilẹede bii Cuba, India ati China wa. Ọpọ awọn oṣiṣẹ lorilẹede wọnyi ni o maa n ṣe eto yiyan bi ologun lọjọ naalati fi sami ayajọ ọhun fun pipe akiyesi si awọn ẹtọ oṣiṣẹ ati lati daabo bo wọn lọwọ iyanjẹ.
Awọn oṣiṣẹ nibi aṣeyẹ kan

Oríṣun àwòrán, other

  • Ni jọ kini oṣu karun un ọdun 1886 ni eto ayajọ yii bẹrẹ nilẹ Amẹrika nigba ti awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Chicago gunle iyanṣẹlodi lati beere fun wakati mẹjọ gẹgẹbi wakati fun iṣẹ lojumọ. Amọṣẹ awọn oṣiṣẹ kaakiri orilẹede Amẹrika darapọ pẹlulati ja fun eto igbayedun to tubọ mọnyan sii lẹyin ti ado oloru kan bu gbamu lasiko iwọde awọn oṣiṣẹ ni gbagede Haymarket Square.
  • Ni ọdun 1889 agbarijọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu Socialist party lagbaye ko ara jọ pọ fun ipade ni ilu Paris nibẹ ni wọn si ti yan ọjọ kini oṣu karun un gẹgẹbi ọjọ ti wọn yoo ma ṣami ayajọ awọn oṣiṣẹ.
  • Ni jọ kini jọ karun un ọdun 1923 ni wọn kọkọ sami ayajọ ni ni Chennai. ẹgbẹ oṣelu Labour party ni Hindustan lo ṣetan naa. Kọmureedi Singaravelar lo ṣe aayan ayajọ naa nigba naa pẹlu ipade meji to gbe kalẹ fun sisami ayajọ rẹ.
  • Kaakiri agbaye ni wọn maa n sami ayajọ awọn oṣiṣẹ lati pe akiyesi si ẹt awọn oṣiṣẹ ati lati daabo bo wọn lọwọ iyanjẹ gbogbo. Bakan naa lo n nduro gẹgẹ bi iranti fun ipa ribiribi ti awọn oṣiṣẹ n ko lawujọ.