Àwọn agbébọn ṣekúpa àgbè, aráàlú faraya, ṣe ìfẹ̀hónúhàn ní Ondo

Aworan ifẹhonuhan to waye nipinlẹ Ondo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn olugbe ilu Ayede Ogbese gbe igi di opopona marose Akure si ilu Owo lati se ifehonuhan tako iṣẹlẹ ijinigbe ati Ipaniyan to n waye ni ilu naa ati agbegbe rẹ.

Ifehonuhan yi waye lẹyin ti awọn agbebọn sẹkupa agbe kan to n bọ lati oko rẹ ni alẹ ana, ọjọ keji Oṣu keji ọdun 2026.

Awọn olugbe Ogbese gbe paali pẹlu oniruru akọle si lara, bi wọn ṣe fi aidunu wọn han, lori iṣẹlẹ ijinigbe ati Ipaniyan to n waye, wọn ni idi rẹ niyi ti wọn fi gbe igi di opopona ki ijọba le da si ọrọ naa.

Wọn kesi ijọba ati awọn esọ alaabo lati ri daju pe oriko awọn ologun wa ni ilu naa lati le dena ọrọ ipaniyan ni agbegbe wọn.

Ki lo sẹlẹ gan an?

Aworan ifẹhonuhan

Lara awọn olugbe ilu Ogbese to ba BBC YORUBA sọrọ salaye pe, agbe kan ati enikeji rẹ n bọ lati oko ni bi ago mẹsan alẹ ni ọjọ Aje ọjọ keji oṣu yi ti awọn agbebọn si se ikọlu si wọn.

Wọn salaye pe lasiko ti wọn se ikọlu naa, ẹni to wa okada ti wọn wa lori rẹ moribọ sugbọn ẹni ekeji to wa lẹyin ni awọn agbebọn naa mu.

Loju kan naa ni wọn pa agbe naa, to si jẹ pe oku rẹ ni wọn ba ni ọna oko lẹyin ti awọn ara ilu de bẹ.

Wọn salaye pe iyalẹnu ni iṣẹlẹ naa jẹ nitori pe oriko ti awọn Ọlọpaa ma n duro si ko ju opo ina meji sì ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ọkan lara awọn to ṣe ifehonuhan naa ti ko fẹ ki orukọ rẹ di mimọ sọ pe igba meji ọtọtọ ni awọn ajinigbe ti wa gbe iyawo ohun.

O salaye pe igba mejeeji ni ohun si ti san millionu mẹta naira, ti gbogbo owo ti ohun san si ti le ni millionu mẹfa naira.

O sọ fun BBC YORUBA pe ohun o le sun ile mọ nitori awọn ajinigbe naa, O sọ pe ile itura ni o n sun si lati oṣu kejila ọdun to kọja.

O rawọ-ẹbẹ si ijọba lati wa ojutu si isoro eto abo ti Ogbese ati awọn ilu to wa ni agbegbe rẹ n koju, ki awọn ara ilu le sun pẹlu alaafia.

Ki ni ijọba sọ lori ọrọ yii?

Lẹyin awuyewuye to ti n jẹyọ lori ọrọ ijinigbe ati Ipaniyan, ijọba Ipinlẹ Ondo ti paṣẹ fun awọn esọ alaabo lati se ikọlu si awọn to n sagbetẹru ijinigbe nipinlẹ Ondo.

Ijọba ninu atejade latọwọ Kọmisọna feto iroyin Idowu Ajanaku sọ pe awọn ẹniyan kan lo wa nidi oro ti oro fi ń ke.

Won ni ijọba mọ pe awọn to n sagbatẹru awọn iṣẹlẹ yi fẹ da omi alafia Ipinlẹ yi ru ni, ti ijọba ko si ni faye gba wọn.

Ajanaku sọ pe ijọba ti pàṣẹ fún gbogbo awọn esọ alaabo lati bẹrẹ isẹ otelemuye ki wọn si bẹrẹ si ni lọ si awọn oriko ti awọn ajinigbe ati awọn to n sagbetẹru wọn wa, ki wọn si fi panpẹ ọba mu wọn lati fi wọn jofin.

Kọmisọna sọ pe ijọba ti ro awọn esọ alaabo lagbara nipa ipese ọkọ, ati awọn ohun elo miran bẹẹni wọn tun gba awọn ikọ 500 tuntun lati darapọ mọ ajọ Amotekun nipinlẹ Ondo.

Ijọba rọ gbogbo awọn ori ade lati mojuto awọn agbegbe wọn daradara ki wọn si ma fi iroyin ohun to n sẹlẹ to awọn esọ alaabo leti.