Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìkú 'Obesere' olórí ọ̀dọ́ tí agbébọn jí gbé l'Ondo

Awọn ọlọpaa n rin kiri ninu igbo kan.

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni oun ti fi ṣikun ofin mu ẹnikan lori iku olori ọdọ kan lagbegbe Isua Akoko.

Oloogbe naa, Ojo Abbey ti ọpọ mọ si Obesere ni wọn ni awọn agbebọn ji gbe lasiko to n bọ lati agbegbe kan nipinlẹ Edo.

Iroyin ni ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2026 ni wọn ji ọkunrin naa gbe ti wọn si gbe lọ sibikan ti ẹnikẹni ko mọ ki wọn to gbẹmi rẹ.

Ara ilu kan ti orukọ rẹ n jẹ Tunji sọ fun awọn akọroyin pe awọn ọdọ ilu, to fi mọ awọn fijilante lo ya wọ igbo lati ṣawari rẹ.

Lẹyinorẹyin, oku rẹ to ti n jẹra ni wọn ṣawari ninu igbo Igara to wa nipinlẹ Edo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Abayomi Jimoh, lo fidi iroyin iku ọkunrin naa mulẹ.

O ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi kan, afurasi ọhun si ti n ran awọn lọwọ lati mọ kulẹkulẹ iṣẹlẹ naa.

O fi kun ope kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal, ti paṣẹ ki wọn ṣewadi kulẹ kulẹ lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si ri daju pe gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ lo foju wina ofin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn afurasi darandaran lo ji ọkunrin naa gbe ninu oṣu Keji ọdun 2026 yii.

Jimoh sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ba mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, wọn si ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe irufẹ iṣelẹ bẹẹ ko waye mọ l'Ondo.

Ẹwẹ, iṣẹlẹ ijinigbe bayii ti di tọrọfọnkalẹ nipinẹ Ondo, o si fẹ ẹ jọ bii pe gbogbo igba ni wọn n ji eeyan gbe nibẹ.

Inu oṣu Keji naa kan ni awọn agbebọn ji awọn to n ṣe iṣọ oru gbe lọ ni ṣọọṣi CCC kan niluu Uso, lẹba ilu Owo.

Lalẹ ana, ọjọ Aje, afurasi darandaran tun gbẹmi ọkunrin agbẹ kan loju ọna oko rẹ, eyii to fa ifẹhonuhan niluu Ayede Ogbese, loju ọna marosẹ ilu Akure si Owo laarọ oni ọjọ Iṣẹgun.