Ìkọlù Israel sí Hezbolla ti gbẹ̀mí èèyàn 31 ní Lebanon

Aworan eefin to n ru lagbegbe kan ni Beruit, orilẹede Lebanon.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọmọogun Israel atawọn ọmọogun Hezbolla lorilẹede Lebanon ti ju ọpọlọpọ ado oloro si ara wọn pẹlu bi ogun ti wọn n gbe ti orilẹede Iran ṣe tubọ n fẹju sii.

Lowurọ ọjọ Aje ni orilẹede Israel bẹrẹ si nii fi ado oloro kọlu awọn ibudo to pe ni ibuba awọn ọmọogun Hezbollah lorilẹede Lebanon lẹyin ti ikọ agbebọn naa yin ado oloro si Israel.

Nibayii ileeṣẹ eto ilera lorilẹede Lebanon sọ pe ikọlu Israel si Beirut atawọn ẹkun gusu orilẹede Lebanon ti ṣekupa eeyan mọkanlelọgbọn, ti awọn mọkandinlaadọjọ miran si tun ti farapa.

Ileeṣẹ alaabo orilẹede Israel tun sọ pe awọn ti kọlu ọkan lara awọn agba ọjẹ ẹgbẹ Hezbollah ni ilu Beirut.

Ninu ọrọ rẹ,olori awọn ọmọ ogun ileeṣẹ alaabo orilẹede Israel, IDF ọgagun Eyal Zamir ṣalaye pe ikọlu ti wọn n ṣe si Hezbolla le gba ọpọlọpọ ọjọ.

"A ti bẹrẹ si nii kogun kọlu ikọ Hezbollah,"

"A nilo lati gbaradi fun ija ti yoo gba ọpọlọpọ ọjọ."

Ki lawọn alaṣẹ ijọ ni Lebanon sọ̀?

Olotu ijọba orilẹede Lebanon, Nawaf Salam ti ṣekilọ fun awọn to n ju ado oloro lati ẹkun gusu orilẹede naa pe ki wọn dẹkun ṣiṣe bẹẹ "lainaani ẹgbẹ oṣelu to le wa lẹyin wọn, jiju ado oloro lati ẹkun Lebanon kii ṣe iwa to bojumu rara, iwa to si lee da ẹmi eto abo orilẹede Lebanon legbodo ni, eleyii to n fun orilẹede Israel ni idi to gbọngbọn lati maa kogun ja Labanon."

Bawo ni ija yii ṣe bẹrẹ?

Aworan ikọlu ni Tehran, orilẹede Iran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orilẹede Iran ni ikọ ọmọogun Israel dojukọ ki awọn ọmọ ogun Hezbollah, ikọ agbebọn kan ti orilẹede Iran n ṣe atilẹyin ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu dọla fun to yin awọn ado oloro si ilu Haifa lorilẹede Israel.

Israel naa da a pada pẹlu ọkan-o-jọkan ado oloro ati ikọlu lati ofurufu. Awọn ẹkun gusu ni Beruit ti wọn jẹ ibuba awọn ọmọogun Hezbolla ni Israel dojukọ atawọn agbegbe to sunmọ papakọ ofurufu ilu naa.

Lẹkun gusu orilẹede Lebanon, ikọ ọmọogun orilẹede Israel ti ṣe ikilọ ṣaaju fun awọn olugbe awọn ilu bii aadọta lo wa nibẹ pe ki wọn fi ibẹ silẹ, ado oloro tun dun nibẹ pẹlu.

Bi o tilẹ jẹ wi pe agbara ikọ Hezbollah ti dinku pẹlu ikọlu ti Israel gbe koju rẹ ni nnkan bii oṣu mejidinlogun sẹyin, amọṣa pẹlu ajọṣepọ to ni pẹlu orilẹede Iran, o di dandan ki wọn fa oun naa wọ̀ wọ ija to n waye laarin Israel pẹlu Iran.

Ninu awọn atẹjade miran ti ikọ ọmọogun alaabo orilẹede Israel fi sita, o ni lara awọn ibi ti wọn kọlu pẹlu ado oloro ni awọn ibudo ikonkan-pamọ-si atawọn ibudo miran kaakiri orilẹede Lebanon.