Bí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Iran kan ṣe ń dunnú, làwọn míràn ń kẹ́dún lórí ikú Ayatollah Ali Khamenei olórí Iran

Àkọlé fídíò, Bí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Iran kan ṣe ń dunnú, làwọn míràn ń kẹ́dún lórí ikú Ayatollah Ali Khamenei olórí Iran
Bí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Iran kan ṣe ń dunnú, làwọn míràn ń kẹ́dún lórí ikú Ayatollah Ali Khamenei olórí Iran

Ado oloro ti Amérika ati Israel yin ti ṣeku pa adari orilẹede Iran, Ayatollah Ali Khamenei.

Ileeṣẹ iroyin orilẹede Iran sọ pe ado oloro ti Amẹrika ati Israel yin laaarọ ana ọjọ Abamẹta lo ṣeku pa Khamenei.

Aarẹ Donald Trump ni Khamenei jẹ ọkan lara awọn oniṣẹ ibi to buru julọ lagbaaye ninu itan.

Trump wa rọ awọn eeyan Iran lati gba orilẹede wọn pada lẹyin iku Khamenei.

Idunnu ṣubu layọ fun ọpọ eeyan lawọn ilu kan lorilẹede Iran pẹlu iku adari orilẹede naa, nigba tawọn kan si n kẹdun rẹ.

Ẹnikan sọ fun BBC Persia wi pe ile aye yoo tun dara si i ni bayii ti Khamenei ti ku.

Iroyin sọ pe ko din ni igba eeyan to ti ku bayii ni Iran.

Iroyin naa ni o kere tan eeyan mejidinlaadọfa (108) lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti ado oloro Amẹrika ati Israel kọlu ile ẹkọ awọn obinrin kan ni Iran.

Aarẹ Trump ni ikọlu si Iran yoo tẹsiwaju titi ti alaafia yoo fi jọba lẹkun Middle East ati ni gbogbo agbaye.