Ìjàmbá iná ṣọṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì àwọn olówò nàbì ní Ilorin, oníbàárà kan jóná mọ́lé

Ilé tó jó kùbbc
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọ buruku esu gbomimu ni ọjọ Ọjọbọ, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, osu Keji, ọdun 2026 jẹ fun awọn oṣiṣẹ ile itura kan ni Ilorin to jẹ olu ilu fun Ipinlẹ Kwara bi ijamba ina ṣe waye ni ile itura naa.

Orukọ ile itura yii ti iwadii fidi rẹ mulẹ pe o jẹ ti awọn olowo nabi ni Lafia (Hotel) to wa ni opopona Coca Cola lagbegbe Unity.

Ohun to ṣe ni laanu julọ ni pe, ọkunrin kan ti ko tii si ẹni to mọ orukọ rẹ jona mọ otẹẹli naa o si ku loju ẹsẹ.

Arakunrin naa ti wọn woye pe yoo le lẹni aadọta ọdun ni wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ onibaara awọn olowo nabi, o si wa lati gbadun ara rẹ ki iku to kaa mọ.

Bí iná mọ̀nọ̀mọ́ná ṣe dé ni iná sẹ́yọ - Ará àdúgbò

Àwòrán páànù ilé ìtùra tó jó

BBC News Yoruba kan si agbegbe ti iṣẹlẹ ijamba ina naa ti waye ti arakunrin kan to jẹ olugbe agbegbe naa ti a forukọ bo lasiri sọ pe bi ina ọba ṣe de mi ni otẹẹli naa bẹrẹ si n jo.

Ninu ọrọ rẹ, "ina ọba de ni nnkan bi ago mọkanla abọ alẹ, bi ina naa ṣe de naa ni ijamba ina sẹyọ ni otẹẹli ọhun.

"Ko pẹ ti ina ọhun sẹyọ lo ran mọ gbogbo ile, gbogbo yara ati awọn nnkan ilo to wa nibẹ si jo raurau.

"Mo gbọ pe onibaara kan ko ri anfaani ati sa asala fun ẹmi ara rẹ, oun nikan naa ni mo lero pe o ku nibi ijamba naa.

"Ohun ti emi ri to fa ijamba yii ni bi wọn ṣe so awọn waya ina mọrawọn.

"Ti ẹ ba wo o lati ita, gbogbo waya to wọ inu ile itura naa lori jakajaka.

"Emi ro pe nnkan to ba n pa owo fun eeyan, o yẹ ki eeyan maa tun-un ṣe ni amọ wọn o tun ile itura yii se rara."

O kọminu pe gbogbo awọn nnkan bayii lo yẹ ki awọn oṣiṣẹ wole-wole maa bojuto lati dẹkun irufẹ isẹlẹ bayii.

Gbogbo nǹkan tí mo ṣiṣẹ́ fún ni iná ti jó mọ́lé - Olówò nàbì kan

Arabinrin olowo nabi kan ti a forukọ rẹ pamọ salaye pe, ko si ohun to ku oun ku mọ nitori gbogbo ohun toun fi owo toun pa ra naa ni wọn ti jo mọle.

O sọ pẹlu ọgbẹ ọkan pe ori lo ko oun yọ nibi ijamba naa nitori oun kan jade sita lati lọ ra nnkan lasiko ti ina naa bẹrẹ to si jẹ pe igba ti oun de pada lo ba ti ina ti n jo, tawọn eeyan si ti fọn sita.

"Mi o ni nnkankan mọ lẹyin ẹrọ ibanisọrọ ọwọ mi ati aṣọ ti mo wọ sọrun.

"Kayeefi lọrọ naa jẹ tori, o si n ṣe mi bi ala lọwọlọwọ"

'Àwọn ohun tó jó yóò lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù náírà (N50m)'

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa toun naa ni ka ma darukọ oun sọ pe, iye owo gbogbo nnkan to jo mọ ile itura naa ni o ṣeeṣe ko le ni aadọta millionu naira (N50m).

O sọ pe yatọ si ẹmi to ṣofo, iye owo to run si ibẹ yoo le ni aadọta millionu naira.

"Awọn firiiji, amohunmaworan, ohun mimu ẹlẹrindodo, gbohungbohun, ibusun ati awọn nnkan mi ni wọn run sibẹ.

"Isẹlẹ naa jẹ ohun to gba omije loju ẹni."

Kíni iléeṣẹ́ panápaná sọ?

Ojú fèrèsé tí iná jó kù

Ẹwẹ, ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Kwara ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Ninu atẹjade lati ọwọ agbẹnusọ ajọ naa, Hassan Hakeem Adekunle ni wọn ti sọ pe awọn panapana kọja lọ sibi ijamba ina ọhun lẹyin ti wọn gba ipe pajawiri lati ile itura Lafia.

O ni ijamba ina naa bẹrẹ lẹyin ti ina mọnamona de ati pe o ṣe ni laanu pe ẹmi kan lọ si iṣẹlẹ naa.

O ni ọkunrin naa to ku naa yoo to ẹni ọdun mejilelaadọta.

Ninu atẹjade naa ni adari agba fun ajọ panapana ni Kwara ti rọ awọn olotẹẹli lati ma ṣe ayẹwo to peye lori awọn ohun elo wọn lẹyin ti wọn ba ti fi awọn ojulowo irinsẹ pilẹ wọn.

O sọ pe, o se pataki fun wọn lati maa lo ẹrọ ti o maa n tete sọ ti eefin ba ti n fin nitori eefin gan-an lo maa n fa ki awọn eeyan ma ni agbara to lati sa asala fun ẹmi wọn ni igba ti ile ba n jo.