Àwọn ajínigbé yìnbọn fún dẹ́rẹ́bà, jí èrò mẹ́fà gbé lọ ní Kogi

Ọkọ akero tawọn ajinigbe ṣe ikọlu si, oju ọta wa lara rẹ

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ajinigbe ti ji okere tan, eeyan mefa gbe lọ ni ilu Ijagbe ni ijọba ibilẹ Mopamuro ni Ipinlẹ Kogi.

Isẹlẹ yii lo waye ni opopona Ijọwa si Ijagbe.

Ọkọ bọọsi Toyota akero kan ni a gbọ pe o n ko ero lọ, ti awọn onisẹ ibi yii si yinbọn mọ dẹrẹba lẹyin ti wọn da ọkọ naa duro.

Lẹyin naa ni wọn dari awọn ero mẹfa ti wọn ba ni inu ọkọ naa wọ inu igbo lọ.

BBC News Yoruba kan si ọkan ninu awọn olugbe agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, arakunrin Olubasiri Babatunde, o si sọ ohun ti o mọ nipa rẹ.

Aráàlú ṣàlàyé bí wọ́n ṣe jí wọn gbé?

Olubasiri sọ pe, "ohun to kọkọ sẹlẹ ni pe, ni alẹ Ọjọbọ mọjumọ ọjọ Ẹti ni wọn kọkọ ji ọkunrin Fulani kan gbe ti a o si tii gbọ nnkankan nipa rẹ.

"Amọ igba to tun di bii ọwọ ago mẹta ọsan ọjọ Ẹti ni a tun gbọ pe wọn ji eeyan mẹfa mii gbe lọ.

"Ọkọ akero kan lo n bọ lati ọna Kabba lọ si Ẹgbẹ, bi o se de Ijọwa si Ijagbe ni awọn atilawi yii yọ jade lati inu igbo.

"Wọn si n yinbọn sinu afẹfẹ, wọn da ọkọ naa duro, wọn si yinbọn fun dẹrẹba ọkọ naa.

"Lẹyin eyi ni wọn wa dari ero mẹfa ti wọn ba ninu ọkọ wọ inu igbo lọ.

"Awọn ero yii jẹ ọkunrin marun-un ati obinrin kan. Titi di asiko yii, a o tii gbọ nnkankan nipa wọn."

'Iwájú ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba kan tí wọ́n kọ́ patì ni wọ́n ti ṣoṣẹ́'

Ọkọ akero tawọn ajinigbe ṣe ikọlu si, oju ọta wa lara rẹ

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT/FACEBOOK

Olubasiri Babatunde tun sọ pe, nigba ti ọkọ naa de iwaju ileẹkọ ijọba kan ti wọn pati ni awọn agbebọn naa jade.

O salaye pe, "ile-ẹkọ ọun ti wa di ẹru jẹjẹ lagbegbe wa bayii nitori ibẹ ni awọn onisẹ ibi yii máa n rí sa si.

Igba mii gan-an, wọn maa n ko awọn ohun elo wọn ati awọn ti wọn ba ji gbe sibẹ

"A rọ ijọba ki wọn tete wa nnkan ṣe lori ile ẹkọ ti wọn kọ pati yii."

O woye pe igbiyanju ijọba ko to lori wiwa ojutuu si ipenija eto aabo bi o ṣe sọ pe awọn ika eniyan yii n pọ si, wọn si tun buru ju atẹyinwa lọ.

"Igba mii, wa kan dede yinbọn pa awọn eeyan, lai ji wọn gbe lai bere owo itusilẹ.

Inú oko kasú làwọn agbébọn tun sá pamọ́ sí báyìí

Olubasiri sọ pe pabanbari lọwọ yii ni pe, oko kasu ni wọn n tun lọ bayii lati ji awọn agbẹ onikaṣu.

O ni nitori pe asiko kaṣu ni awa, pe awọn to si lọ n sa koro kaṣu ni wọn n jigbe.

O sọ pe ẹkọọkan ni ijinigbe maa n sẹlẹ tẹlẹ, a mọ o ti dii lemọmọ bayii ni agbegbe naa.