BBC 100 Women 2020 list: Uyaiedu Ikpe-Etim, Aisha Yesufu wà lára àwọn obìnrin 100 tó pegedé jùlọ ní 2020

Oríṣun àwòrán, @Aisha
Orúkọ Aisha Yesufu náà wọ inú BBC 100 Women tí a fi ń sọri àwọn obìnrin tó pegedé ní 2020
BBC 100 Women 2020 list: Aisha Yesufu to sagbatẹru ifẹhọnuhan ENDSARS wa lara awọn obinrin 100 to pegede julọ ni ọdun 2020
Awọn obinrin wọnyii ni wọn kopa to lamilaaka lasiko ti awọn nkan ko rọrun lagbaye.
Orukọ arabinrin Aisha Yesufu to n ja fun ipadabọ awọn ọmọbinrin Chibok ti ikọ Boko Haram jigbe lọ naa wọ inu iwe akọsilẹ awọn obinrin to lamilaaka naa.
Orukọ Aisha wa pẹlu awọn obinrin bii Olootu orilẹede Finland, Sanna Marin to gbe ẹgbẹ oṣelu ti awọn obinrin dari rẹ kalẹ.
Bakan naa ni Michelle Yeoh to wa ninu fiimu tuntun, Avatar pẹlu Dokita Sarah Gibert to saaju igbogunti ajakalẹ arun Coronavirus, ti wọn si pese abẹrẹ ajẹsara lati ileewe giga Oxford.

Oríṣun àwòrán, @Aisha
Aisha Yesufu to sagbatẹru ifẹhọnuhan ENDSARS
Ileeṣẹ BBC ni Aisha Yesufu gbe oriyin fun ipa ribiribi to ko ninu ifẹhọnuhan ENDSARS to tako ifiyajẹni awọn ara ilu lati ọwọ awọn ọlọpaa.
Ifẹhọnuhan ENDSARS yii jasi opin ikọ ọlọpaa SARS lorilẹede Naijiria ti wọn fi ẹsun ipaniyan, ifipabanilopọ ati ole jija kan.
- MC Oluọmọ gbé ara rẹ̀ ṣépè nítorí ìwọ́de #ENDSARS
- "A ti já gbogbo ojú òpó ìjọba Nàìjíríà gbà lórí Twitter láti ṣàtìlẹyìn ìwọ́de End SARS" - Anonymous
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
- Ọ̀rọ̀ ajé dẹnu kọ̀lẹ̀ yíká Nàíjíríà, àkẹ́kọ̀ọ́, olókoòwò àti òṣìṣẹ́ ọba jókòó sílé
- Àwọn ọmọ Naijiria kó owó wọn kúrò ní Access Bank lẹ́yìn tó gbẹ́sẹ̀lé àpò owó àwọn olùwọ́de EndSARS
Awọn miran lati ile Afrika ti orukọ wọn wa ninu awọn obinrin 100 to lamilaaka ni ọdun 2020.
Kii ṣe Yefusu nikan lo wa nibẹ, arabinrin Uyaiedu Ikpe-Etim to jẹ ọmọ Naijiria wa lara wọn.
O n ja fun idọgba laarin ọkunrin ati obinrin to si n ṣe ọpọlọpọ fiimu jade lati sagbatẹru fun awọn obinrin to n fẹ obinrin ẹgbẹ wọn (LGBTQ+ activist).

Oríṣun àwòrán, others
Sierra- Leone - Yvonne Aki-Sawyerr gba Ami Ẹyẹ fun iṣẹ ribiribi to ṣe fun ọrọ ayika ati oju ọjọ, nibẹ lo ti ṣe agbatẹru gbingbin igi miliọnu kan laarin ọdun meji kaakiri orilẹede naa.
Somaliland - Ubah Ali na lo ṣe oludasilẹ 'Ajọ Somaliland Girls' to n tako abẹ dida fun obinrin( Female Genital Mutilation) ni awọn igberiko lorilẹede naa, nipa idanilẹkọ ati ipese ohun amayedẹrun.
Zimbabwe - Tsitsi Dangarembga to jẹ onkọwe ti kọ awọn iwe to si ti gba Ami Ẹyẹ lorisirisi fun ipa to n ko lawujọ lati gbogun ti iwa ajẹbanu ati ijọba ti ko naani araalu.
O pẹlu awọn eniyan ti wọn timọle nitori o darapọ mọ awọn afẹhọnuhan tako ijoba.
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
- Taa ni Ọọni àná tí Ọba Ogunwusi forúkọ ọmọ rẹ̀ sọ?
- Ìbálòpọ̀ ọ̀lọ́jọ́ méje mú kí ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́wàá ká ní Ibadan
Benin - Angélique Kidjo ti gba Ami Ẹyẹ Grammy fun igba kẹrin fun awọn orin rẹ to ti lamilaaka kaakiri agbaye.
Angelique tun jẹ ẹni to n ṣe atilẹyin fun awọn ọmọ kekeke lawujọ paapaa eto ẹkọ fun awọn obinrin nilẹ Afrika.
Somalia - Ilwad Elman jẹ adari awọn obinrin to n saaju ipe fun alaafia lorilẹede Somalia nitori ajijagbara fun alaafia ni.
Tanzania - Rebeca Gyumi jẹ agbẹjọro to ja fun didọgba laarin akọ ati abo.
Ọdun 2019 ni ajọ rẹ bori nile ẹjọ tako igbayawo awọn ọmọdebirin, ti ijọba si sọ di ofin pe ọdun mejidinlogun ni iye ọjọ ori to kereju lati gbeyawo fun awọn obinrin.
Kenya: Jemimah Kariuki jẹ dokita to ṣe ipese ọkọ pajawiri fun awọn alaisan lẹyin to riwi pe ọpọlọpọ eniyan n ku nitori aisi ọkọ lati tete gbe wọn lọ si ileewosan.
Egypt - Nadeen Ashraf jẹ akẹkọọ imọ 'philosophy' to ṣi oju opo ikansiraẹni Instagram nibi ti awọn obinrin ti n sọ nipa ifiyajẹni ati ifipabanilopọ ti wọn n dojukọ lorilẹede Egypt.
Ethiopia - Loza Abera Geinore jẹ gbajugbaja agbabọọlu ninu ikọ agbabọọlu 'Ethiopia national women team', to si ti gba ami ẹyẹ lọpọlọpọ.
Egypt - Maggie Gobran ti ọpọ eniyan mọ si Mama Maggie Gobran ti fi gbogbo aye rẹ gbọ ti awọn ọmọ ti wọn ti pati lorilẹede Egypt.
O n ṣe itọju wọn nipa fifun wọn ni ẹkọ ati riran wọn lọ si ileewe fun eto ẹkọ lati di eniyan pataki lawujọ.
- Ìbálòpọ̀ ọ̀lọ́jọ́ méje mú kí ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́wàá ká ní Ibadan
- Fatai Rolling Dollar, Ọmọ ìdílé oyè tó gbé igbá orin tí Ebenezer Obey ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀!
- Kí lo mọ̀ nípa ìbẹta kan ṣoṣo tí Alaafin Oyo bí? Wọ́n pé ọdún méjìlá báyìí
- Elon Musk, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ SpaceX, Tesla CEO ń bá Bill Gates du ipò ẹni tó lówó jùlọ ṣèkejì lágbayé
Zambia - Mulenga Kapwepwe wa ninu awon to ṣe idasilẹ ile ohun alumọni to jẹ ti obinrin si 'Zambian Women History Museum'.
To si tun ṣe idasilẹ awọn ile ikawe fun awọn ọmọde si olu ilu orillẹede Zimbabwe, Lusaka.
Mozambique - Josina Machel naa jẹ obinrin to ja fun ẹtọ awọn obinrin to si n pese ile igbe fun awọn obinrin ti wọn n koju ifiyajẹni ninu igbeyawo wọn.
South Africa - Bulelwa Mkutukana jẹ gbajugbaja olorin to n fi orin rẹ ja fun ẹtọ awọn obinrin ni awujọ.
DR Congo - Douce Namwezi N'Ibamba jẹ akọroyin to n ṣe agbatẹru idagbasoke awọn obinrin ninu ajọ rẹ, Uwezo Afrika Initiative.
Kenya - Phyllis Omido ni oludasilẹ Justice Governance and Environmental Action (CJGEA), to n ja fun idagbasoke agbegbe ati awọn ilu ti awọn ileeṣẹ nla ti bajẹ lorilẹede Kenya.
Uganda - Vanessa Nakate to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun naa n ja fun oju ọjọ nilẹ Afrika, to si ma n kaakiri ileto si ileto lati ṣe idanilọyẹ lori ipa ti oju ọjọ to n yipada ni lori ilẹ Afrika.
Uganda - Ethelreda Nakimuli-Mpungu to jẹ akẹkọ imọ eto iwosan n ṣiṣẹ takuntakun lati pese eto alaafia fun awọn to ni arun kokoro HIV ati aisan ọkan to n rẹwẹsi.
South Africa - Ishtar Lakhani jẹ ajafẹtọ obinrin , to si n kopa ribiribi ninu eto 'Free di Vaccine campaign' lati ri wi pe abẹrẹ ajẹsara lati gbogun ti arun Coronavirus ko sọwọn fun awọn eniyan lati ra ni iye owo ti awọn mẹkunu le ra.
- Ganiyat tó fi irin gbígbóná àti àdá ya ara ọmọ àbúrò ọkọ rẹ ti dèrò àgọ́ ọlọ́pàá l' Ogun
- Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé
- Ọmọbìnrin tó tayọ nínú ìdànwó WAEC ọdún 2019 pẹ̀lú A1 méje ti kú
- Àwọn olóṣèlú, àti àwọn Ọba n gbàbọ̀dè fún ìpínlẹ̀ Ekiti lórí ọ̀rọ̀ àwọn tó n fi ipá bánilòpọ̀- Kọmísọ́nnà ètò ìdájọ́
- Nàìjíríà fohùn ránṣẹ́ padà sílé aṣofin UK pé ọ̀rọ̀ EndSars kò sí lẹ́nú wọn láìgbọ́ ìwádìí tán!


















