Adebayo Salami, Joke Silva ṣèdárò àgbà òṣèré Pete Edochie tó jáde láyé

Oloogbe Pete Edochie wọ aṣọ ati fila pupa, o mu abẹbẹ lọwọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn alẹnulọrọ lagbo oṣere si n daro agbaọjẹ oṣere Nollywood, Pete Edochie, to dagbere faye.

Lara awọn agba oṣere to n ṣedaro lẹyin Edochie ni agbaojẹ oṣere ori itage, Adebayo Salami.

Agba oṣere naa kẹdun loju opo Instagram rẹ pe ''gbogbo nnkan ni asiko wa fun un.

Asiko lati gbe ile aye ati asiko lati fi ile aye silẹ, gbogbo rẹ lo si ni idi.''

Adebayo Salami wa kẹdun pẹlu ẹbi Edochie lori iku rẹ.

O ṣapejuwe Edochie gẹgẹ bii gbajugbaja oṣere ti Eledua fun ni ẹbun nigba aye rẹ.

O wa gbadura pe ki Ọlọrun duro ti ẹbi to fi silẹ lọ, ki Eledua si tẹ ẹ safẹfẹ rere.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Agba oṣere mii, Joke Silva, naa n ṣedaro lẹyin ẹni ire to lọ.

Ilumọọka oṣere naa sọ loju opo Instagram rẹ pe oun yoo ṣafẹri awada ti Edochie maa n ṣe.

Oun naa si gbadura wi pe ki Eledua tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Gbajugbaja oṣere n ni, Funke Akindele, naa ko gbẹyin ninu awọn ti n ṣedaro Edochie.

Funke loun ranti igba toun wo Edochie ninu ere Things Fall Apart lori ẹrọ amohunmaworan nigba toun n dagba.

Bakan naa tun ni Akindele tun sọ pe oun ranti igba toun ṣere pọ pẹlu Edochie ninu ere Egg of Life.

Funke wa dupẹ lọwọ oloogbe lori bi ''o ṣe la ọna ti ọpọ oṣere n tọ bayii.''

O ni iṣẹ ti oloogbe ti ṣe silẹ ko le parẹ laelae, bo tilẹ jẹ pe o ti dagbere fun aye yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kókó méje nípa ìgbé ayé Pete Edochie, àgbà òṣèré tíátà tó dágbére fáyé

Oloogbe Pete Edochie wọ asọ oke alawọ omi aro ati goolu, o si de fila rẹ

Agba ọjẹ oṣere tiata, to tun jẹ ilumọka, Pete Edochie ti jade laye ni ọdun mọkandinlọgọrin, 79.

Iroyin yii lo tẹ wa lẹti ninu atẹjade kan ti ọmọ rẹ, Leo Edochie, fi sita ni owurọ Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2026 pe oloogbe naa jade laye nipinlẹ Enugu.

Bakan naa ni atẹjade naa tun fidi rẹ mulẹ pe aisan jẹjẹrẹ ti n ba oloogbe naa finra ko to di pe o jẹ ipe Olọrun.

Awọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbé ayé Pete Edochie, àgbà òṣèré tíátà tó jáde láyé

Yoruba ni awaye ku ko si, tori bo pẹ titi, gbogbo ẹda ni yoo tọ iku wo.

Wọn bi Pete Edochie ni ọjọ keje oṣu kẹta ọdun 1947 nipinlẹ Enugu

Baba rẹ jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ Reluwe Naijiria, to si jẹ iṣẹ baba rẹ lo gbe lọ si ipinlẹ Kaduna, ibi to ti dagba.

Pete Edochie lọ si ile ẹkọ Saint Patrick's and Saint James Primary Schools ni Zaria, ko to tun morile Saint John Secondary School, Kaduna, ni 1960.

Lẹyin ọdun mẹrin, o dara mọ baba rẹ nidi iṣẹ Reluwa ṣugbọn mọlẹbi naa kuro nipinlẹ Kaduna saaju ki ogun abẹle to bẹrẹ

Ni ẹni ogun ọdun, Pete Edochie bẹrẹ iṣẹ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Eastern Nigerian Broadcasting Corporation.

Ni ọdun 1980, Pete Edochie lọ si ile ẹkọ British Broadcasting Corporation fun imọ si, to si pada di ọga agba akọkọ fun ileeṣẹ ijọba Anambra Broadcasting Service 3FM Stereo ni ọdun 1987.

Aworan Pete Edochie

Irinajo Pete Edochie sagbo osere tiata

Lẹyin eyi ni Pete darapọ mawọn osere tiata, to si kopa ninu ọpọ sinima.

Amọ ere to mu ko di ilumọọka ni ere Things Fall Apart nibi to ti kopa bii Okonkwo.

Ileesẹ mohunmaworan ilẹ wa, Nigerian Television Authority, NTA si lo se ẹda iwe naa bii ere tiata loju iworan rẹ.

Ipa ti Pete Edochie ko gẹgẹ bii jagunjagun fun ẹya Igbo ninu ere tiata naa lo mu ko di gbajumọ ati ọkan lara awọn osere tiata to n lewaju nilẹ Naijiria.

Ere yii lo jẹ ohun ti gbogbo agbaye tẹwọgba, koda, ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC gan fi ọrọ wa lẹnu wo nipa ipa to ko ninu ere naa.

Lara awọn ere sinima ti Pete ti kopa ni Igodo, Rituals, Billionaire's Club ati Lionheart, ninu eyi to ti kopa bii Oloye Ernest Obiagu.

Pete Edochie fẹ́ agbẹjọ̀ro ni aya, ọmọ rẹ meji ninu mẹfa jẹ osere tiata

Bakan naa ni Edochie ti gba ọpọ ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, ti aarẹ ana, Oloye Olusegun Obasanjo si da lọla pẹlu oye Member of the Order of the Niger (MON).

Oloogbe naa tun gba ami ẹyẹ Africa Magic fawọn osere tiata, ti Afica Film Academy naa si tun fun ni ami ẹyẹ osere tiata to pegede.

Amofin Josephine Edochie ni aya Pete, ti Ọlọrun si fi ọmọ mẹfa ta wọn lọrẹ.

Lara wọn ni Yul ati Linc Edochie ti awọn mejeeji naa jẹ gbajumọ osere tiata bii baba to bi wọn.

Ọpọ igba ni awuyewuye ti waye nipa ẹbi Pete Edochie, ti ọpọ eeyan ko si le gbagbe awọn ohun to suyọ nipa igbeyawo Yul, ẹni to fẹ Judy bii iyawo keji.