Àwọn ohun méje tí Trump ṣèlérí láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì

A ti mú ìròyìn yàjóyàjó lórí ètò ìdìbò ààrẹ Amẹrika wá sópin báyìí.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Adedayo Owolabi, Olumide Owaduge, Akinlabi Afolabi

  1. Mo ti juwọ́ sílẹ̀ fún Trump - Kamala Harris

    Kamala Harris

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Igbakeji Aarẹ Amẹrika, to tun n du ipo Aarẹ, Kamala Harris ti ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ lẹyin eto idibo to waye nilẹ naa.

    Ile ẹkọ Howard University, to wa ni Wahsington DC ni ọrọ naa ti waye, nibi to ti sọ pe oun ti juwọ silẹ fun Trump gẹgẹ bii ẹni ti araalu dibo fun.

    O ni oun yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu Trump lati gbe ijọba pada fun ti oun ati Aarẹ Joe Biden ba pari saa wọn.

    Ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni iburawọle Trump gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika tuntun yoo waye.

  2. Ìgbà wo ni ìbúrawọlé Trump yóò wáyé?

    Donald Trump

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Lootọ ni Trump ti bori idibo Aarẹ Amẹrika ti yoo si pada si White House gẹgẹ bii Aarẹ ilẹ naa, kii ṣe oun ni Aarẹ lọwọ yii.

    Yoo le ni oṣu meji si asiko yii ki o to pada si ọọfisi Aarẹ Amẹrika.

    Eto iburawọle ilẹ Amẹrika yatọ si bi wọn ṣe n ṣe e ni Naijiria, ilẹ Gẹẹsi, atawọn orilẹede mii kaakiri agbaye.

    Aarẹ Joe Biden ni yoo si wa lori oye bayii titi di igba ti saa ijọba rẹ yoo pari.

    O di ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 ki wọn to burawọle fun Donald Trump gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika tuntun.

  3. Àwọn ohun méje tí Trump ṣèlérí láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì

    Donald J. Trump

    Oríṣun àwòrán, Donald J. Trump

    Donald Trump ti n mura silẹ lati pada sile ijọba ilẹ Amẹrika, White House, lẹyin awọn ileri to ti ṣẹ ṣaaju faraalu.

    Nigba to n sọrọ lori aṣeyọri rẹ ninu ibo Aarẹ, o ni afojusun oun ni lati mu gbogbo awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo bo ṣẹ fun awọn eeyan Amẹrika.

    Oniruru ileri ni Trump ṣe faraalu lasiko ipolongo ibo rẹ, awọn kan fẹran awọn ileri naa, bẹẹ lawọn mii bu ẹnu atẹ lu diẹ lara awọn ohun to ni oun yoo ṣe.

    Iwọnyii ni awọn ohun meje ti Trump ṣeleri pe oun yoo ṣe ti oun ba pada de ipo Aarẹ

    • O ni oun yoo le awọn alejo ti ko ni iwe igbelu pada si orilẹede wọn
    • Trump ṣeleri lati fopin si ọwọngogo to gbode, bẹẹ ni yoo mu adinku ba awọn owo ori kan
    • Lọna ati ṣeranlọwọ fun awọn ileeṣẹ to n ṣe ọkọ l’Amẹrika, Trump ni oun yoo mu adinku ba awọn ofin to nii ṣe pẹlu ayipada oju ọjọ to wa nilẹ tẹlẹ
    • Ileri lati fopin si ogun Ukraine
    • Lodi si ifẹ inu awọn alatilẹyin rẹ kan, trump sọ pe oun yoo fun awọn ipinlẹ ni ore ọfẹ lati yan boya wọn faramọ oyun ṣiṣẹ tabi bẹẹ kọ, amọ ko sọ pe oun yoo gbẹsẹle ofin to gbe lẹyin oyun ṣiṣẹ
    • Idariji fun diẹ lara awọn to kopa ninu ifẹhonuhan ‘Capitol riot’ to waye loṣu Kinni, ọdun 2021
    • Idaduro amofin Jack Smith, to jẹ ọkan lara awọn to pe e lẹjọ ṣaaju
  4. Báyìí ni èsì ìbò Ààrẹ Amẹrika ṣe wọlé láti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan

    US Election 2024
  5. Àwọn olórí ìjọba káàkiri àgbáyé ti ń ki Trump kú oríire

    Donald Trump

    Oríṣun àwòrán, Donald Trump

    Awọ olori ijọba kaakiri agbaye ti bẹrẹ si n ki Donald Trump ku oriire lẹyin aṣeyọri rẹ ninu idibo Aarẹ ọdun 2024.

    Lara awọn to ti ki Aarẹ ana naa ku oriire ni Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu.

    Ninu atẹjde kan ti agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga, fi lede, Tinubu ni oun ni ireti pe ibasẹpọ to da mọran ju ti atẹyinwa lọ yoo waye laarin Naijiria ati ijọba ilẹ Amẹrika.

    Awọn mii to tun ti ki Trump ku oriire ni olootu ijọba Israel, olootu ijọba Hungary ati olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi

  6. Donald Trump ló ń léwájú nínú èsì ìbò Ààrẹ Amẹrika

    Donald J. Trump

    Oríṣun àwòrán, Donald J. Trump

    Aarẹ ilẹ Amẹrika tẹlẹ, Donald Trump lo n lewaju ni bi esi ibo Aarẹ ṣe n wọle lọwọ bayii.

    Pupo ninu esi naa to n wọle ti fi han pe Trumo n da siria lọwọ fun Harris, bo tilẹ jẹ pe Harris funrẹ naa ni ọpọlọpọ ibo.

    Wayi o, Trump ti kede pe oun ti jawe olubori, awọn alatilẹyin rẹ si ti n ki ku oriire kaakiri agbaye.

    Lara awọn to ti bẹrẹ si n ki Trump ku oriire ni awọn olori ijọba kaakiri agbaye bii olootu ijọba Israel, olootu ijọba Hungary ati olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi.

  7. Èsì ìbò Ààrẹ Amẹrika ti ń wọlé

    us election

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Esi ibo Aarẹ Amẹrika ti n wọlẹ bayii lẹyin ti ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan tu jade lati dibo kaakiri ilẹ naa.

    Gẹgẹ bii eto idibo Amẹrika ṣe maa n waye, apapọ ibo 270 ni eyikeyi ninu awọn oluije naa gbọdọ ni ki wọn to le jawe olubori.

    Lọwọ yii, Aarẹ ana, Donald Trump ti ni ibo 230, nigba ti igbakeji Aarẹ to tun du ipo Aarẹ, Kamala Harris ni ibo 182 lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

    Pẹlu idunnu ati ayọ lawọn ololufẹ Trump fi n yọ nigba ti iroyin ni Trump ni yoo gba North Carolina.

    Bẹẹ naa lọrọ ri fun awọn ololufẹ Harris nigba ti aridaju wa pe oun ni yoo bori ni Virginia.

    Lọwọ yii, esi ibo naa ṣi n wọlẹ lọwọ, a o si maa mu gbogbo bo ba ṣe n wọle wa fun yin loju opo yii.

  8. Báwo ni kíkà ìdìbò ààrẹ America yóò ṣe lọ?

    Aworan oludibo

    Oríṣun àwòrán, source,EPA-EFE/REX/Shutterstock

    Awọn esi idibo naa ko tii le jẹ gba ontẹ titi wọn o fi ka gbogbo gbogbo ibo, ti wọn yoo si ṣe ayẹwo wọn.

    Awọn igbesẹ yii le gba to ọpọlọpọ ọjọ ki gbogbo rẹ to pari.

    Ni awọn ipinlẹ to jẹ ibi agbara awọn oludije mejeeji, fini-fini ni wọn yoo ṣe ayẹwo esi ibo.

    Aago mẹfa irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ni idibo yoo bẹrẹ si i pari.

    Ni ọpọ igba, o le gba to ọpọlọpọ ọṣẹ, paapaa nitori ofin ipinlẹ kọọkan.

    Bakan naa ni kika ilana fun yatọ si ara wọn - iru ilu to wa ati iru irinṣẹ́ ti wọn lo.

    Ni awọn ijọba ibilẹ kan, ẹrọ ayaworan 'scanner' ni wọn n lo, ti awọn mii si n lo àwọn ẹrọ to n ṣaami si iwe idibo, lati ṣe akọsilẹ ibo.

    Ibo kika le falẹ nipasẹ ọrọ ofin tabi ti awọn kan ba da ibo ru. Orisirisi awuyewuye lo ti n waye, eyi to ba ofin mu.

  9. Davido wà lára àwọn ọmọ America tó ti dìbò ààrẹ

    Gbajugbaja akọrin takasufe, to tun jẹ ọmọ orile-ede Naijiria ati ọmọ America, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido, wa lara àwọn oludibo to ti dibo wọn ninu ibo aarẹ.

    Oju opo ayelujara X rẹ ni Davido ti kede pe oun ti dibo, fun igba akọkọ.

    Ninu aworan to fi sita lo ti mu kaadi idibo kan dani, eyi to fihan pe Georgia lo ti dibo.

    Davido

    Oríṣun àwòrán, Davido/X

  10. 'Àwọn ọmọ Russia ló wà nídìí ayédèrú ìròyìn nípa ìdìbò'

    Awọn àjọ ọtẹlẹmuyẹ ni orile-ede America ti sọ pe awọn ọmọ orile-ede Russia lo wa nidi ayederu iroyin nipa idibo.

    Àjọ naa sọ pe awọn 'iranṣẹ lati Russia' lo wa nidii ayederu fidio kan to fi ẹsun kan pe, magomago idibo waye ni Arizona.

    Ko din ni igba 200,000 eeyan ti awọn eeyan ti wo fidio ọhun, ti wọn fi sori ayelujara X.

    Fidio naa ṣe afihan ọkunrin kan to ni oun ni amugbalẹgbẹ nigba kan fun Akọwe ijọba Arizona, Adrian Fontes, to fi ẹsun kan pe oun ri ẹ̀rí to fihan pe Donald Trump ṣe magomago.

    Fontes sọ pe irọ ni iroyin naa.

    Wọn ni gbogbo ẹ̀rí lo fihan pe imọ ẹrọ AI ni wọn fi ṣe pàtàkì ohùn to wa ninu fidio naa.

    Ikọ Foundation to Battle Injustice (“FBI”) to wa ni Russia, lo ṣe fidio naa.

    Ẹni to da a silẹ lọdun 2021, ni Yevgeny Prigozhin. Ṣaaju iku rẹ, wọn ti fi ofin de e ni US nitori pe o n da si ọrọ idibo.

    Aworan lati inu fidio naa

    Oríṣun àwòrán, Russian Foundation to Battle Injustice

    Àkọlé àwòrán, Aworan lati inu fidio naa
  11. Ètò ìdìbò Amẹrika bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu

    US Election

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Eto idibo Aarẹ ilẹ Amẹrika ti bẹrẹ bayii ni pẹrẹwu.

    Nnkan bii aago marun un idaji ni eto naa bẹrẹ ni Vermont, to wa lagbegbe East Coast ilẹ naa.

    Lẹyin eyii ni idibo yoo bẹrẹ lawọn agbegbe mi bii New York ati Virginia.

    Laarin awọn wakati diẹ si asiko yii ni gbogbo ilẹ ọhun yoo ji ti awọn eeyan yoo si bẹrẹ si n dibo wọn.

    Nnkan bii miliọnu mejidinlọgọrin eeyan ni ireti wa pe wọn yoo dibo laari oni yii si ọla.

  12. Ta ni ọkọ Kamala Harris?

    Kamala Harris

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Lọdun 2014 ni Harris ṣe igbeyawo pẹlu Doug Emhoff to jẹ amofin, awọn mejeji si wa gẹgẹ bii tọkọtaya titi di oni yii.

    Ile igbimọ aṣofin ni Harris wa lọdun naa lọhun.

    Ọmọ meji, Cole ati Ella ni Doug bi ṣaaju igbeyawo oun ati Harris, o si gba lati maa tọju awọn ọmọ naa gẹgẹ bii ọmọ ara rẹ.

    Harris ni “Nigba ti emi ati Doug fẹ ara wa, a jọ ni adehun pe Cole ati Ella ko ni ri mi bii iyawo baba wọn, amọ wọn yoo ri mi bii iya wọn.”

    Cole, Ella ati baba wọn, Doug, wa lara awọn to wa yẹ Harris si lasiko ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu Demorcat to waye ninu ọdun yii.

    Awọn aburo Harris, Maya ati Meena naa wa nibi ipade ẹgbẹ ọhun.

    Ọjọgbọn kan nipa eto oṣelu ni fasiti Purdue, Nadia Brown, sọ pe ipasẹ awọn eeyan bii Fannie Lou Hamer, Ella Baker ati Septima Clark ni Harris n tẹle.

  13. Ta ni Kamala Harris, akínkanjú obìnrin tó ń du ipò Ààrẹ Amẹrika?

    Kamala Harris

    Oríṣun àwòrán, Kamala Harris

    Ilu Oakland, ni California ni wọn ti bi Kamala Harris.

    Ọmọ orilẹede India ni iya rẹ ti baba rẹ si jẹ ọmọ orilẹede Jamaica.

    Awọn obi rẹ pin gaari nigba to wa lọmọ ọdun marun un pere, ti iya rẹ, Shyamala Gopalan, nikan si bẹrẹ si n tọju rẹ.

    Gbogbo igba ni Harris maa n tẹle iya rẹ lọ siluu wọn ni India, nitori naa o mọ nipa aṣa orilẹede naa daadaa.

    Amọ nigba to lọ kẹkọoọ ni fasiti Howard ni Harris mọ irufẹ ẹni to jẹ ati ohun to le gbele aye ṣe gẹgẹ bii obinrin.

  14. Adájọ́ fi ààyè gba Elon Musk láti máa pín owó fawọn olùdìbò

    Ellon Musk

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Adajọ ipinlẹ Pennsylvania kan ti ni aaye ṣi wa fun baba olowo rẹpẹtẹ nni, Elon Musk, lati maa pin owo fawọn oludibo lasiko ṣiwaju idibo America.

    Amọ ṣa oni yii ni opin ọjọ ti Musk le maa pin owo faraalu.

    Aarẹ Donald Trump ni Elon Musk n ṣatilẹyin fun ninu ibo naa bi gbogbo aye ṣe mọ.

    Nipasẹ ẹgbẹ America PAC ti Musk da silẹ lo ti n pin owo fawọn oludibo to forukọ silẹ ni awọn ipinlẹ kan.

    Iwa yii le tumọ si pe eeyan n ru ofin, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ṣe wi, ṣugbọn Musk sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.

    Lawrence Krasner loun fẹ ki kootu paṣẹ, pe Musk gbọdọ dawọ owo to n pin kiri naa duro, ki ibo to n bọ yii too waye.

  15. Ìsẹ́gun tó lágbára jùlọ nínú ìtàn Amẹ́ríkà ni ìbò yìí yóò jẹ́fún mi - Trump, Donald Trump: Kò yẹ ká máà gbé ìgbé báyìí ní Amẹ́ríkà

    Donald J. Trump.

    Oríṣun àwòrán, Donald J. Trump.

    Oludije sipo aarẹ nilẹ Amẹrika, Donald Trump ti ipolongo rẹ to waye ni Grand Rapids, nipinlẹ Michigan.

    Ọpọlọpọ eeyan si lo peju sibẹ lati fi ifẹ wọn han fun Trump, ẹni ti wọn n sa ni mẹsan-mẹwa.

    Ilu Grand Rapids yii naa ni Trunp ti so eto ipolongo ibo rẹ rọ lọdun 2016 ati 2020.

    “Nigba to n sọrọ, Trump ni ko rọrun rara lati se eto ipolongo ibo mẹrin bii iru eyi ni ọjọ kan soso amọ o fikun pe bawọn araalu se n fi ọyaya tẹwọgba oun, mu ki adinku ba isoro ipolongo ibo naa.

    Aarẹ tẹlẹ nilẹ Amẹrika naa pẹ fun bii wakati meji ko to de sibi eto ipolongo ibo naa, eyi to yẹ ko bẹrẹ ni aago mọkanla abọ.

    Trump wa rọ awọn awọn eeyan to wa nibi ipolongo ibo naa pe se igbe aye wọn dara si lasiko yii ju ti ọdun mẹrin lọ, ti awọn ero nibi ipolongo ibo naa si ni rara.

    “Isẹ ti mo ni fun yin ati awọn eeyan ilẹ Amẹrika yoku kere jọjọ, ko yẹ ka maa gbe igbe aye bayii.”

    “Eyi ni isẹgun to lagbara julọ lagbo oselu ninu itan orilẹede yii.”

  16. Mo ti ṣetán láti di Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika - Kamala Harris

    Kamala Harris

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Oludije sipo Aarẹ ilẹ Amẹrika, Kamala Harris ti ba awọn oludibo sọrọ fun igba ikẹyin ṣaaju eto idibo Aarẹ ilẹ naa.

    O bẹrẹ pẹlu ọrọ idupẹ fun awọn alatilẹyin rẹ fun gbogbo atilẹyin wọn lasiko ipolongo ibo.

    O ni “Lasiko ipolongo ibo wa, a ti mọ nnkan ti awọn eeyan Amẹrika n fẹ, inu wa si dun pe a ti mọ aṣeyọri ti a le jọ ṣe papọ.”

    Harris pari ọrọ rẹ pe awọn oludibo ti ni anfani bayii lati ṣe ayipada ninu oṣelu ilẹ naa nipa fifi ibo wọn gbe oun wọle.

  17. Kínni àwọn ọmọ ilẹ̀ Africa ń fẹ́ nínú ètò ìdìbò ààrẹ America?, Kínni àwọn ọmọ ilẹ̀ Africa ń fẹ́ nínú ètò ìdìbò ààrẹ America?

    us

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Àkọlé àwòrán, us election

    Annette Njau to jẹ amofin lati orilẹede Sierra-Leone l'Amẹrika sọ pe ohun ti ọpọ alawọdudu to n gbe lorilẹede Amerika n fẹ ni pe ki wọn lanfaani lati maa ṣe okowo wọn, ki wọn si dibo bakan naa.

    Njau jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹrun lọna ọdunrun un ọmọ ilẹ Afirika to n gbe ni Texas lorilẹede Amerika.

    Wọn si ti sa ipa wọn lati ri wi pe gbogbvo awọn ọmọ ilẹ Afirika to ti to ibo di ni yoo dibo lọjọ Iṣẹgun ọjọ karun un oṣu Kọkanla yii.

    Nneka Achapu, ọmọbibi orilẹede Naijiria to n gbe orilẹede Amerika sọ pe ‘’oriṣiiriṣii iyapa ati inunibini lo wa l’Amẹrika lori ọrọ ẹlẹyamẹya ati wiwa si orilẹede Amẹrika lati ilẹ okeere.

    Eleyii si n ni ipa to lagbara gidi gan an lori awujọ wa lorilẹede Amẹrika.’’