Wo ọ̀nà tí ogun Middle East fi lè nípa lórí èsì ìbò Ààrẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Rafid Jabouri
- Role, BBC News Arabic
- Reporting from, Michigan
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Bí ètò ìdìbò sípò Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe ń súnmọ́ etílé, àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó jẹ́ ìran Áràbù tó ń gbé ní Michigan ni wọ́n wà ní ìkòríta ohun tí wọ́n yóò ṣe,
Pẹ̀lú bí ìpínlẹ̀ náà ṣe ní ìbò “electoral vote” mẹ́ẹ̀dógún (èyí tó ní ipa lórí èsì ìbò), ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó jẹ́ ìran Áràbù ni jẹbẹtẹ gbé ọmọ lé lọ́wọ́. Ó ṣòro fún wọn láti pinnu lórí ẹni tí wọ́n máa dìbò fún láàárín Kamala Harris àti Donald Trump pàápàá lórí ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ní ẹkùn Middle East.
Àtẹ ìbò tó ti ń jáde ń ṣàfihàn pé àwọn olùdíje méjèèjì súnmọ́ ara wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kamala Harris ń léwájú pẹ̀lú àwọn ìbò ni ìlú tó gbajúmọ̀. Àmọ́ bí ó ṣe wà nínú òfin ìbò Amẹ́ríkà, “electoral college” ni wọ́n yóò fi mọ ẹni tó jáwé olúborí gangan tí Michigan sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ náà.
Àwọn Áràbù, pàápàá àwọn èyí tó ń gbé ní ìlú Dearborn, le mú àyípadà bá èsì ìbò ọdún yìí ní àwọn ìlú tí ìbò wọn kìí nípa tẹ́lẹ̀.
Ìlú tí ìpinnu wọn kò ti papọ̀

Àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó jẹ́ Áràbù tó wà ní Michigan kìí ṣe èyí tó máa ń ní ipa lórí ìbò Amẹ́ríkà. Ìpinnu wọn lórí ìbò tẹ́lẹ̀ máa ń dá lórí ipa tí yóò ní ní Amẹ́ríkà àti àgbáyé lápapọ̀.
Rima Meroueh tó ń darí “National Network for Arab American Communities” ní “Arab Community Centre for Economic and Social Services” ní ìlú Dearborn sọ fún BBC pé ó ṣòro láti sọ pé iye kan báyìí ni ìbò àwọn èèyàn náà le jẹ́.
Ètò ìkànìyàn ní Amẹ́ríkà kò rí àwọn Áràbù bíi ẹ̀yà tó dá dúró, ní èyí tó mú ṣòro láti sọ pé iye báyìí ni wọ́n jẹ́ àmọ́ Meroueh sọ pé àwọn Áràbù tó lè dìbò ní Michigan nìkan tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún.
Láti ṣàfihàn bí èyí ṣe lè wáyé, ìbò 10,000 ni Trump fi borí ní Michigan lọ́dún 2016 àmọ́ ìbò 100,000 ni Joe Biden fi na Trump lọ́dún 2020. Èyí túmọ̀ sí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Áràbù kò tó nǹkan ní Michigan, ìbò wọn le ní ipa bí èsì ìbò ṣe súnmọ́ ara wọn yìí.
Meroueh wòye pé àwọn Áràbù tó ń dìbò kìí ní nǹkankan gbòógì tí wọn yóò dìbò lé lórí àmọ́ tí ìbò ọ̀tẹ̀ yìí yàtọ̀ nítorí ogun tó ń wáyé ní Middle East láti ìgbà ìkọlù Gaza lọ́dún tó kọjá.
Síbẹ̀, ẹnu wọn kò kò nítorí àwọn kan ń ṣe àtìlẹyìn fún Trump fún bí ó ṣe máa ń gbé Amẹ́ríkà síwájú ohun gbogbo tí wọ́n sì gbàgbọ́ pé ó le lo èyí láti fòpin sí ogun náà. Àwọn mìíràn gbàgbọ́ pé Harris ní ọgbọ́n inú láti fòpin sí ogun náà àti pé ó le dènà irú ogún bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Ìpèníjà lórí ètò Middle East

Bákan náà ni àwọn ẹgbẹ́ mìíràn wà tí wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú, Green Party, Jill Stein nítorí bí ó ṣe máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu àtìlẹyìn tí Amẹ́ríkà ń ṣe fún Israel, tó sì jẹ́ ohun tó dùn mọ́ wọn.
Kamala Harris ti ṣèlérí fáwọn èèyàn Áràbù náà pé òun máa ṣiṣẹ́ láti ri pé ogun dópin ní Middle East tó sì tún tẹmpẹlẹmọ ìbáṣepọ̀ ọjọ́ pípẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú Democratic Party àti Israel. Bákan náà ló ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn Palestine tó sì ń pè fún ààbò àwọn èèyàn ẹkùn náà.
Sam Abbas tó jẹ́ oníṣòwò oúnjẹ ní ìlú Dearborn gbàgbọ́ pé Biden àti Harris lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn tó ń wáyé ní Middle East àti pé gbogbo àwọn ènìyàn òun kò ní dìbò fún Harris.
Fún Abbas, ìkòríta ńlá ni ètò ètò ìdìbò yìí jẹ́ nítorí ó jẹ́ ọ̀nà láti yan èṣù tó kéré ni. Ó ní òun kò ì tíì pinnu lórí ẹni tí òun máa dìbò fún àti pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ ìbò gangan ni òun máa mọ ẹni tí òun máa dìbò fún.
Trump ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀ – pẹ̀lú àwọn ìpinnu rẹ̀ lórí ètò bí àwọn èèyàn ṣe ń wọ Amẹ́ríkà tí ọ̀pọ̀ rí bíi lílòdì sáwọn Mùsùlùmí àti Áràbù àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Olóòtú ìjọba Israel Benjamin Netanyahu - ṣì ń rí àtìlẹyìn àwọn Áràbù tó yani lẹ́nu.
Àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ pé kò sí ogun kankan tó wáyé nígbà tí òun wà nípò Ààrẹ Amẹ́ríkà àti pé ogun tó ń wáyé ní Ukraine àti Middle East kò bá má ṣẹlẹ̀ ká ní pé òun ṣì wà nípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.
Yíyí ìpinnu padà
Adarí ẹgbẹ́ kan tó ń pè fún kíkọ àwọn ẹgbẹ́ tó bá ń ṣe àtìlẹyìn fún Israel sílẹ̀ ní àwọn kò bínú olùdíje kankan.
Ọ̀kan nínú àwọn adarí ẹgbẹ́ náà, Hassan Abdel Salam ní àwọn gbàgbọ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú méjèèjì ni ọwọ́ wọn kò mọ́ àti pé àwọn Mùsùlùmí Amẹ́ríkà nílò láti dìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn yàtọ̀ sí àwọn méjèèjì tó gbajúmọ̀.
Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Green Party, Jill Stein ni wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn. Abdel Salam ní ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn kò ṣe dada sáwọn Mùsùlùmí àti Áràbù.

Samara Luqman tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Yemen àti Amẹ́ríkà ti máa ń ṣe àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ Democrats fún ìgbà pípẹ́ àmọ́ tó pinnu láti dìbò fún Donald Trump níbi ètò ìdìbò yìí.
Luqman ní bí ikọ̀ ìpolongo Trump ṣe kàn sí àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó jẹ́ ìran Áràbù àti bí wọ́n ṣe kàn sí òun láti ṣèpàdé pẹ̀lú Trump jẹ́ nǹkan tó yí ọkàn òun padà.
Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ tí sọ nípa fífi òpin sí ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Middle East lásìkò tí àwọn ń sọ̀rọ̀ wà lára nǹkan tó yí ìpinnu òun nípa Trump padà.
Ó ní òun gbàgbọ́ pé ìbò òun àtàwọn míì yóò jẹ́ ìfẹ̀hónúhàn sí ẹgbẹ́ Democrats.
Ṣé Harris le borí ìbò lọ́dọ̀ Áràbù?

Pẹ̀lú bí àwọn tó ń ṣe àtìlẹyìn fún Trump ṣe ń pọ̀ si ní Michigan, ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats kò káàárẹ̀ ọkàn. Ó ní àwọn alátìlẹyìn láàárín àwọn Áràbù pàápàá láti ìgbà ìkọlù ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kẹsàn-án.
Sami Khalidi tó jẹ́ olórí Democrats ní Michigan ní ìgboyà pé Harris ṣì lè borí ìbò lọ́dọ̀ àwọn Áràbù.
Ó sọ fún BBC pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Harris tí ń pè fún ṣíṣe àtúntò Gaza àti láti pèsè ìrànwọ́ si ní Palestine.
Khalidi ní ẹgbẹ́ òṣèlú náà nìkan ló fún àwọn Áràbù ní ààyè àti àtìlẹyìn tó yẹ àti pé òun gbàgbọ́ pé bí Kamala Harris ṣe máa mú ọ̀rọ̀ ogun tó ń lọ ní Middle East máa yàtọ̀ sí ọwọ́ tí Joe Biden fi mu.
Ó ní ọ̀pọ̀ ni kò mọ ìhà tí Harris kọ sí ọ̀rọ̀ yìí àti pé ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats nílò láti máa ṣàlàyé àwọn ìwòye Harris fún wọn.

Fún àwọn míì, kò sí nǹkan tó le yí ìpinnu wọn padà. Jẹni ẹ Yassin tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine àti Amẹ́ríkà ní òun kò ní dìbò rárá.
Yassin ní ètò US lórí Israel kìí ṣe nǹkan tí èèyàn le dá sí rárá.
Ó fẹ̀sùn kan àwọn olùdíje méjèèjì pé wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́ tí Israel ń ṣe sí àwọn ọmọ Palestine.
Ó wòye pé ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats kò ní ìmọ̀ pé fún àwọn tó jẹ́ ìran Áràbù, Palestine ni nǹkan tó jẹ́ àwọn lógún jùlọ àti pé wọ́n kò lè sọ pé àwọn ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin nígbà tí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ ní Palestine.
Yassin gbàgbọ́ pé àyípadà máa wà lọ́jọ́ iwájú pẹ̀lú bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ti ń tako àwọn ìgbésẹ̀ US tó ń ṣe àtìlẹyìn fún Israel.












