Taiwo Adegbodu, olórin ẹ̀mí ẹgbẹ́ Adegbodu Twins jáde láyé

Awọn ibeji naa wọ aṣọ funfun

Oríṣun àwòrán, Adegbodu Twins Fans Page

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Taiwo Adegbodu, to jẹ ọkan lara awọn ibeji olori ẹmi nni, Adegbodu Twins, ti jade laye.

Ekeji rẹ, Kehinde Adegbodu lo fi ikede iku Taiwo lede lonii ọjọ Isinmi.

Ninu atẹjade kan to fi lede pẹlu ibanujẹ ni ọkunrin naa ti kẹdun iku ekeji rẹ ọhun loju opo Facebook rẹ.

O ni "Taiwo, kilode ti o fi maa fi emi atawọn ọmọ rẹ silẹ lọ lai kọkọ dagbere?

"Ọkan mi gbọgbẹ, Oluwa bawo ni o ṣe fẹ ki n gbe igbeaye mi lai si ekeji mi? Ọlọrun Kilode? Eyii kọja agbara mi!!!"

Wayi o, ọkunrin naa ko sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku Taiwo tabi akoko pato to jade laye.

Ikede iku oloogbe naa

Oríṣun àwòrán, Adegbodu Twins Fans Page

Taiwo ati Kehinde Adegbodu jẹ gbajumọ olorin ẹmi ti ọpọ eeyan fẹran lati maa gbọ.

Ọpọ lo fẹran orin wọn latari awọn ọrọ iṣiti to wa nibẹ, to fi mọ awọn aṣa alujo wọn pẹlu.

Yatọ si ilẹ Yoruba, awọn eeyan tun maa n gbadun, bẹe ni wọn maa n j o si orin wọn kaakiri Naijiria ati lagbaye.

Lara awọn orin Adegbodun Twins to milọ titi ni Adura mi gba, Igbagbọ dun, Unchangeable changer, Oruka igbeyawo, Ẹmi mimọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.