Ẹgbẹ́ NDC kéde ipò ààrẹ sí Gúúsù Naijiria ní 2027, 2031 fún Àríwá

Peter Obi ati Rabiu Kwakwanso nibi ipade NDC, ọkunrin kan wa lẹgbẹẹ wọn pẹli awon ero mi-in lẹyin.

Oríṣun àwòrán, NDC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fun apa ibi ti aarẹ yoo ti jade wa ninu ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) ni 2027, ẹgbẹ naa ti kede pe Guusu Naijiria ni (Southern Nigeria).

Ikede yii waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹsan-an oṣu Karun-un ọdun 2026, nibi ipade apapọ ẹgbẹ NDC to waye niluu Abuja.

Bakan naa ni wọn kọ ọ soju opo ayelujara wọn pe:

"Tikẹẹti ipo aarẹ ẹgbẹ NDC n lọ si apa Guusu!!"

Wọn tun kede pe saa ọdun mẹrin pere ni tikẹẹti naa yoo wa fun, wọn ni to ba di 2031, Ariwa Naijiria ni tikẹẹti ipo aarẹ NDC yoo lọ.

Awọn ohun ti NDC fẹẹ bojuto bi ipade apapọ ṣe waye

Awon olukopa nibi ipade apapọ NDC

Oríṣun àwòrán, NDC/X

Ipinnu NDC yii waye bi awọn agba ẹgbẹ bii Peter Obi, Rabiu Kwankwaso atawọn mi-in ṣe kora jọ sibi ipade apapọ naa.

Ipade ọhun ni wọn lo wa fun lati yẹ awon ipinnu kan ti awon alaṣẹ ẹgbẹ ṣe wo.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ti wọn fi ṣọwọ si awon akoroyin ṣe wi, lara awọn ọrọ ti NDC yoo bojuto ni :

Pinpin ibi ti ipo yoo bọ si, fifi ontẹ lu ofin ẹgbẹ, ati didibo yan awon alaṣẹ ẹgbẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ṣẹṣẹde ẹgbẹ ni NDC, ṣugbọn laaarin ọjọ diẹ to de ni awọn oloṣelu kan, paapaa awon alatako ti n rọ wọ ibẹ.

Awọn eeyan ti won wa ninu ADC ati PDP ti wọn ti rọ wọ NDC ko kere laarin ọjọ perete ti ẹgbẹ naa gbera sọ.

Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to n pari lọ yii, ko din ni ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin mẹtadinlogun (17) to darapọ mọ NDC.

Ọjọ Aiku to kọja si ni Peter Obi ati Kwankwaso kede pe awon ti fi ADC silẹ, NDC ni awon n ba lo.

Ni bayii ti wọn ti kede apa ibi ti wọn ti fẹ fa aarẹ kalẹ, awọn alakalẹ eto to ku yoo maa tẹle e lẹsẹẹsẹ bi wọn ṣe sọ.

Awon wo ni NDC gan-an?

Peter Obi ati Rabiu Kwakwanso nibi ipade naa.

Oríṣun àwòrán, NDC/X

Gẹgẹ bi wọn ṣe juwe ara wọn, Nigeria Democratic Congress (NDC), jẹ ẹgbẹ kan ti erongba rẹ jẹ lati dide, gbe ijọba to ni ẹ̀kọ́ kalẹ.

NDC sọ pe awon wa fun eto ti yoo pẹ, ati akoyawọ lẹka gbogbo.

" Awa ni ẹgbẹ apapọ to wa fun ijọba awarawa to leto, to si ni etigbọọ si awujọ."

Gẹgẹ bo ṣe wa loju itakun ayelujara wọn.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ, gomina tẹlẹ kan nipinlẹ Bayelsa lo da ẹgbẹ oṣelu NDC yii silẹ, ni 2017.

Ṣugbọn INEC to n ri si eto idibo ilẹ wa ko gba a wọle, afi nigba to di oṣu Keji ọdun 2026 yii.

Igbawọle naa waye lẹyin ọpọlọpọ igbẹjọ to ti waye lori idasilẹ NDC, ki wọn too gba a wọle loṣu mẹta sẹyin. Ẹgbẹ naa lo si di abẹnu aasaasi fun awọn oṣelu alatako bayii.