'Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe dùn tó,' Lateef Adedimeji sọ̀rọ̀ lórí ọmọkùnrin mẹ́ta tí Elédùà fi ta ẹbí rẹ̀ lọ́rẹ

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Facebook
Gbajugbaja oṣere ori itage, Lateef Adedimeji, ti sọ pe ti wọn ba gẹṣin ninu oun, wọn o le kọsẹ nibi ti inu oun dun de bayii lẹyin ti Eledua fi ibẹta jinki ẹbi rẹ.
Lati igba ti Lateef ati aya rẹ, MoBimpe, ti kede pe Eledumare fi ibẹta ta idile oun lọrẹ ni ọpọ eeyan ti n yọ ayọ ọmọ pẹlu wọn.
Oriṣiiriṣii atẹjiṣẹ lawọn eeyan fi n ranṣẹ si wọn lori itakun ayelujara, lẹyin ti wọn ti woju Ọlọrun fun bi ọdun marun un lati di ọlọmọ laye.
Adedimeji sọ loju opo Facebook rẹ wi pe ''awọn eeyan ti fi ifẹ nla han si wa, o si jẹ nnkan to dara gan an.
Mi o mọ bi mo ṣe le ṣapejuwe bi inu mi ṣe dun to lasiko yii lori oore ti Eledua ṣe fun idile mi.
Gbogbo atẹjiṣẹ, gbogbo adura ati ọrọ ikini ti ẹ fi ranṣẹ si wa ni a ri, a si mọ riri rẹ pẹlu.
Ẹ ṣe gan an ni, a dupẹ, lati ibi gbogbo lawọn eeyan ti n yọ ayọ ọmọ pẹlu wa.
Ẹ ṣeun fun ifẹ ti ẹ ni sawọn ọmọkunrin ti Eleduwa fi jinki wa.
A mọ riri rẹ o, inu wa si dun gidi gan an, ọkan wa kun fun ayọ.''
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
'Mi ò tiẹ̀ mọ ibi ti mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀,' MoBimpe sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó bí ìbẹ́ta
Inu ẹni ki I dun ka pa a mọra, paapaa nigba ti oore ojiji ti awọn kan ko fi gbogbo ara gbagbọ ba ṣẹlẹ sini.
Lori ikede ọmọ mẹta lẹẹkan ṣoṣo ti Lateef Adedimeji ati Bimpe Oyebade (Mo Bimpe) iyawo rẹ fi sita lọjọ Ẹti, Mo Bimpe ti jade sori ayelujara lati dupẹ lọwọ awọn to n ba wọn yọ latigba ti iroyin ayọ naa ti gbode.
Ana ode yii ti I ṣe ọjọ Abamẹta ni Mo Bimpe kọ ọrọ idupẹ si oju opo Facebook rẹ.
O kọ awọn ọrọ idupẹ naa lati fi bi inu rẹ ṣe dun to si awọn to n ba a yọ han, ko si tun le jẹ aridaju fun awon to n ṣiyemeji pe ṣe loootọ ni oṣere tiata naa bi ibẹta lẹyin ọdun marun-un igbeyawo.
Loju opo Facebook rẹ to ti fi ẹmi imoore han ni Mo Bimpe ti kọ ọ pe:
"Àwọn ọrẹ, ẹbi titi kan awon ti a ko tiẹ mọ ri lo n ba wa yọ. Awọn kan tiẹ n sunkun paapaa. Mi o tiẹ mọ ibi ti mo ti le bẹrẹ.
"Mi o mọ bi mo ṣe fẹẹ dupẹ lọwọọ yin tan. Ifẹ ati idunnu lo yi mi kan.
" Ẹ jọwọ ẹ fun mi lasiko ki n le fi imoore han si kaluku."
Bẹẹ ni Mo Bimpe kọ ọ soju opo Facebook rẹ naa, to si tun fi aworan ibi ti oun ati Lateef ti gbe awon ibẹta naa si ẹsẹ han, pẹlu ibusun ti wọn ṣe fun awọn ọmọ mẹtẹẹta.
Bawo ni ikede ayọ naa se de ori ayelujara?
Baba ibẹta, Lateef Adedimeji lo fi ikede naa sori ayelujara ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ ni owurọ oni, ọjọ kini osu karun ọdun 2026.
Ninu fidio naa la ti ri Lateef ti aya rẹ fi ọwọ kọ lọrun, ti wọn si dijọ de fila ti wọn kọ akọle Baba ati Mama si lori.
Iya ibẹta, to so ọwọ mejeeji mọ ọkọ rẹ lọrun, lo mu ayẹwo ọmọ mẹta lọwọ, pẹlu aworan fila mẹta, ibọsẹ mẹta ati ibọwọ mẹta.
Koda, orin awa ti bimọ, dandan ni ka yọ fun Ọlọmọ ni wọn kọ sori fidio naa.
Lara ohun ti Lateef kọ sinu fidio naa niyi:
"Awọn ọmọ Adedimeji, a ti n fi nnkan pamọ fun yin.
Lọdun 2026 yii, Ọlọrun fun wa ju ohun ti a beere lọwọ Ọlọrun.
Obinrin yii ti fun mi ni ọmọ mẹta ti maa pe ni awọn ọmọ mi, ọba mẹta ti wọn jẹ ojuse mi"
Ọpọ eeyan si lo ti n ki baba ati iya mẹta naa ku oriire.




























