Kí ló mú kí ọkọ̀ kan ré bọ́ láti orí afárá sí ìsàlẹ̀ èyí tó pa èèyàn mọ́kànlá l‘Ogun?

Bọọsi kan run jege tori ijamba ọkọ, awọn eeyan mẹrin duro yika rẹ

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ko din eeyan mọkanla to ti padanu ẹmi wọn ni opopona ipinlẹ Eko si Abeokuta latari ijamba ọkọ to waye ni opopona ọhun.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, niṣe ni ọkọ kan ṣadede yẹ kuro lori afara Eruku eyi to ṣokunfa ijamba naa.

Atejade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ ni Naijiria, FRSC, tẹka ipinlẹ Ogun, Afolabi Odunsi fi lede lọjọ Aiku sọ pe alẹ ọjọ Aiku ni ijamba ọkọ naa waye.

FRSC ṣalaye pe ọkọ Toyota kan ti nọmba rẹ jẹ GGE722KJ gbe okiti ni ẹẹmẹta ko to di pe o jabọ lati ori afara to wa.

"Ọkọ Toyota GGE722KJ lo gbokiti, ko to jabọ lati ori afara ti awọn eeyan to wa ninu rẹ ko si le jade tori ilẹkun pade mọ wọn"

Odunsi sọ pe gbogbo awọn eeyan mọkanla, to fi mọ awọn ọkunrin mẹwaa ati obinrin kan, to wa ninu ọkọ naa, lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.

Odunsi ni kete ti ileeṣẹ FRSC gbọ si iṣẹlẹ naa ni awọn fi awọn oṣiṣẹ ranṣẹ sibẹ lati mojuto iṣẹlẹ naa.

"Ijamba ọkọ naa lo ṣẹlẹ si ọkọ Toyota to ni nọmba idanimọ GGE722KJ eyi to gbokiti ni ko to di pe o jabọ lati ori afara.

O ni eyi lo ṣokunfa bawọn eeyan to wa ninu ọkọ naa ko ṣe ri bi kuro ninu rẹ nitori ilẹkun pade mọ wọn.

"Gbogbo awọn eeyan mọkanla to wa ninu ọkọ naa lo ba iṣẹlẹ naa padanu ẹmi wọn," atẹjade naa ṣalaye.

Odunsi fi kun pe awọn ti ko awọn oku awọn eeyan naa lọ mọṣuari pẹlu atilẹyin awọn eeyan to wa ni agbegbe naa eyi to ba wọn ṣe akitiyan bi wọn ṣe pada ri ilẹkun ọkọ naa ja.

O ni mọṣuari ile iwosan ijọba ipinlẹ Ogun to w ani if oni wọn gbe awọn oku naa si.

O ni iwadii ti awọn kọkọ ṣe ṣafihan pe awakọ to wa ọkọ naa ti mu ọti ko to bẹrẹ si ni wa ọkọ ati pe o ko ero to pọ ju bo ṣe yẹ lọ, to si ni o ṣeeṣe ko jẹ pe ohun to fa ijamba naa niyẹn.

FRSC sọrọ lori ijamba naa

Nigba to n sọrọ lori ijamba naa, ọga agba ileeṣẹ FRSC ipinlẹ Ogun, Oludare Ogunjobi gba awọn awakọ to n gba ọna Abeokuta si Eko nimọran lati maa ṣe jẹjẹ ti wọn ba n gba ọna naa.

Bakan naa lo ba awọn ẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa kẹdun.

Ọpọ igba ni ijamba ọkọ ti maa n waye ni ipinlẹ Ogun tawọn oṣiṣẹ ajọ FRSC si maa n ṣe ikilọ fawọn awakọ lati dena ere asapajude, mimu oti ki wọn to wakọ, ati gbigbe ero ju bo ṣe yẹ lọ.

Àrá sán pa olọ́pàá lẹ́nu iṣẹ́

Ara to n san lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kayeefi nla ni iku ọlọpaa kan, Abdulkadir Garba, ṣi n jẹ fun awọn eeyan to gbọ pe àrá kan to san l'Ọjọru ran an lọ sọrun ojiji nigba to wa lẹnu iṣẹ lọwọ.

Maiduguri ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Borno ni Garba tawọn eeyan tun mọ si Buratai, ti pade iku ojiji nigba ti ara naa san.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno, ASP Nahum Daso, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ara san to si pa Buratai, oun nikan kọ ni ara to san naa kan.

O ni o tun kan ọga rẹ kan, ASP Wazani Adamu, ṣugbọn iyẹn ko ku ni tiẹ.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Borno naa ṣe wi, o ni nigba ti ojo naa n rọ, awọn ọlọpaa mejeeji gbiyanju lati sa sibi kan, ṣugbọn ara naa san ki wọn too de ibi ti wọn fẹ sa si.

Atẹjade ti Daso fi kede iṣẹle naa ṣalaye pe:

"Ibukun ni ojo maa n saba mu wa, ṣugbọn ibanujẹ ni eyi mu wa.

"Atẹgun bẹrẹ si I fẹ, awọn ọlọpaa mejeeji gbiyanju lati wa ibi kan sa si ki ojo naa too bẹrẹ si I rọ.

" Ṣugbọn lojiji, ara nla kan san, o si ba awon ọlọpaa mejeeji to ṣi wa lẹnu iṣẹ naa."

Alukoro tẹsiwaju pe ASP Wazani Adamu ti ko ku, ri aanu gba ni, ṣugbọn Buratai ni ara naa sọlẹ le lori ju, ara rẹ bo, eyi to fa iku rẹ.

"Inspekitọ Abdulkadir Garba ko padanu ẹmi rẹ sọwọ jagidijagan tabi wahala, ṣugbọn ara to san lo mu un lọ.

"Ọlọpaa to gbajumọ to si n ṣiṣẹ rẹ daadaa ni, o si jẹ apẹẹrẹ itẹpamọṣẹ."

Bẹẹ ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Borno sọ nipa akẹgbẹ rẹ to rọrun nipasẹ ara to san lojiji.