Akeugbagold sọ pé pásítọ̀ wà lára àwọn tó n san owó wáàsí òun

Oríṣun àwòrán, others
Ilumọọka onimọ nipa ẹṣin Islam ati oniwaasi agbaye, Sheikh Taofeeq Akeugbagold ti salaye pe musulumi ati Kristẹni lo nifẹ si waasi ti oun maa n ṣe lori redio.Akeugbagold, ẹni to sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto BBC Yoruba kan, tun fikun pe, ọrọ ifẹ, iwa rere ati ibagbepọ alaafia ni oun maa n ṣe waasi le lori.
- Arákùnrin tó jí Ese Oruru gbé ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún 26 he
- Wo ìgbà márùn ún tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ti gé ẹ̀mí ọgá wọn kúrú
- Wọn tí fòfin de iléeṣẹ́ ìròyìn Chris Oyakhilome nítorí ó sọ pé 5G ló ṣokùnfà àrùn Coronavirus
- Femi Adebayo di àgbà àáfà òníláwàní, Iyabo Ojo fi sìgá dárà, Allwell Ademola di ọmọdé padà, tí Wazo si bímọ tuntun
Akeugbagold to ni awọn Kristẹni wa lara awọn eeyan to n ṣe onigbowọ waasi oun lori redio, tun tọkasi pe pasitọ kan wa lara awọn onigbowọ waasi naa.
"Pasitọ to wa lara awọn eeyan to n ṣanwo waasi mi yii nifẹ awọn ọrọ ti mo maa n sọ eyi ti ko da lori ẹṣin. Koda, o sọ fun mi pe awọn waasi ọhun dara to bẹẹ, ti oun maa n fi ṣe waasi ni sọọsi lọjọ ìsinmi."
Oniwaasi agbaye naa, to ni oun maa n ṣe alarena laarin ọkùnrin to n wa aya, tabi obinrin to n wa ọkọ tun ni, o ti to ẹgbẹrun marun-un lọkọ laya ti oun ti so pọ lati ọdun 2017 ti oun ti bẹrẹ eto naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to n sọ nipa ihuwasi awọn ibeji rẹ to bọ lọwọ awọn ajọmọgbe laipẹ yii, Akeugbagold ni ṣe ni awọn ibeji naa n sa si abẹ aga ati tabili ni kete ti wọn ba gburo pe ọkọ wọnu agbala oun, ti wọn si ro pe awọn ajọmọgbe lo tun de.
"Ẹru awọn ajọmọgbe naa ko tii kuro lara awọn ibeji yii, yatọ si pe wọn n sa fun mọto to ba wọle, igbe ma na ẹ, ma pa ẹ, ni wọn tun n kígbe, ti apa lorisirisi si kun ẹyin wọn, koda o le ni ọjọ mẹrin ki wọn to le rin daadaa lẹyin ta ri wọn, to si daju pe awọn ajọmọgbe naa n fi tipa fun wọn ni oogun oorun."
Baba awọn ibeji naa wa kan saara sawọn ọlọpaa fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati kapa iwa ọdaran lawujọ wa, to si rọ ijọba lati ṣanwo gidi fawọn ọlọpaa pẹlu irinsẹ igbalode lati ṣíṣẹ wọn.
Lori bi awọn musulumi ṣe maa n fẹ iyawo pupọ, onimọ nipa ẹṣin Islam naa ni ko si ohun to buru ti wọn ko ba fẹ ju iyawo mẹrin lọ, ti wọn si n ṣe deede laarin wọn.
"Iyawo kan ṣoṣo ni Islam ni ka fẹ amọ kọndisan lo gbe iyoku wa sugbọn ọkùnrin ti ko ba fẹ ki awọn obinrin fi igbọnsẹ ati itọ ṣe òògùn ifẹ fun oun, o dara ko ṣe deede laarin awọn iyawo to ba fẹ sile."
Nigba to n gba awọn adari wa nimọran lori bi ọjọ ọla Naijiria yoo ṣe dara, Akeugbagold rọ wọn lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ, ki wọn si fun wọn ni owo lati da iṣẹ tara wọn silẹ, ki wọn ma baa huwa ọdaran.
" Ọpọ biliọnu naira ni ijọba n na lati ṣẹgun Boko Haram, airisẹse awọn ọdọ si lo faa, amọ o yẹ ki wọn ro awọn ọdọ lagbara, iru owo Abacha yẹn, wọn le pin N2m fun ọdọ kọọkan lati ro lagbara, ki ipese ina ọba to duro re si wa pẹlu."
Akeugbagold wa gba musulumi, ẹlẹsin ibilẹ ati Kristẹni niyanju lati maa lo ifẹ, ki wọn si tun yago fun iwa ẹlẹyamẹya nitori ijẹọmọniyan ju ọrọ ẹṣin lọ, aisi ifẹ si lo n ṣe okunfa ba ṣe n pa ara wa.
Àwọn ìbejì Akeugbagold kò le rìn dáadáa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dáwọn padà
Onimọ nipa ẹṣin Islam ti wọn ji ibeji rẹ lọ laipẹ yii, Sheikh Taofeeq Akeugbagold tun ti salaye nipa ohun ti oju awọn ibeji rẹ ri ni ọdọ awọn afurasi to ji ibeji rẹ gbe.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣe afihan awọn afurasi to ji awọn ibeji ọhun gbe, ki wọn to ri wọn pada, ti obìnrin kan si wa ni aarin wọn.
Nigba to n kopa lori eto ori redio kan nilu Ibadan ni aarọ Ọjọru, Akeugbagold sọ pe irọ nla ni bi obinrin to wa laarin awọn afurasi naa ṣe sẹ pe, oun ko mọ ohunkohun nipa bi ọkọ rẹ ati awọn afurasi yoku ṣe ji awọn ibeji oun gbe.
A o ranti pe afurasi obinrin naa, Rafiu Modinat, tii ṣe iyawo ọkan lara awọn afurasi yoku, Rafiu Mutiu, lo faake kọri lọdọ awọn ọlọpaa pe oun ko ba awọn afurasi yoku lọwọ ninu iwa ajọmọgbe naa.
Gẹgẹ bi Modinat ti wi, ọkọ oun ko awọn ọmọ mejeeji naa wa sile pẹlu alaye pe, ọrẹ oun kan ati iyawo rẹ lo ja, ti wọn ko si fẹnuko lori ẹni ti yoo ko awọn ọmọ wọn sọdọ, idi si ree ti ọkọ oun ṣe gba lati ko awọn ọmọ naa wale.
Amọ Akeugbagold ni "obinrin naa lo n na awọn ọmọ mi ni anajati lasiko ti wọn wa ni akata rẹ, irọ si lo n pa pe ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa."
"Ni kete ta ri awọn ọmọ naa, la gbe wọn lọ sile iwosan, nibẹ si ni asiri ti tu pe awọn ọmọ mejeeji yii ko le rin daadaa nitori ọgbẹ ti obinrin naa da si wọn lara lasiko to n na wọn ni anadojubolẹ."
Bakan naa tun ni onimọ nipa ẹṣin Islam ọhun tun sisọ loju rẹ pe, Modinat yii lo maa n fun awọn ọmọ oun ni oogun mu lasiko ti wọn wa ni igbekun wọn, ti oun si fura pe, o maa n fi ibinu na awọn ibeji naa lasiko ti wọn ko ba fẹ gba oogun lọwọ rẹ ni ẹrọ.
Amọ ṣa, ojisẹ Ọlọrun naa ni oun ti forijin awọn ajọmọgbe naa patapata gẹgẹ bi Pope mimọ ṣe darijin awọn agbenipa to fẹ gba ẹmi rẹ nijooni.
Inú jìn! Akitiyan ọmọ'ṣẹ́ mi tó wà lára àwọn tó jí ìbejì mi gbé kò kéré nígbà tí á n wá wọn- Akeugbagold
Gbajugbaja onimọ nipa ẹṣin Islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold ti sọrọ nipa iru eeyan ti amugbalẹgbẹ rẹ, Opeyemi Oyeleye jẹ, ẹni tii ṣe afurasi tawọn Ọlọpaa lo ṣe kokari bi wọn ṣe ji ibeji rẹ gbe lọ.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Aje ni Ileesẹ Ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣe afihan oju awọn afurasi to ji ibeji Akeugbagold gbe lọ, ki wọn to ri wọn pada, ti Opeyemi si wa lara awọn afurasi naa.
Akeugbagold, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Isegun lori iṣẹlẹ naa salaye pe, ọmọkunrin to ni laakaye ni afurasi naa, o ni ọpọlọ, to si maa n ronu kọja ọjọ ori rẹ.
"Ọmọkunrin naa ni ẹkọ gan-an ni, o gbọn pupọ, eyi to mu ki n tete fa a mọra, koda o n dun mi pe o fẹ fi gbogbo ẹbun rere ti Ọlọrun fun ṣofo ni, tori mo ti fi oju ṣun-un pe ọjọ iwaju rẹ yoo dara."
Onimọ nipa ẹṣin Islam naa ni, inu oun maa n dun lati ṣun mọ ẹni to loye, ti oun si fa afurasi naa mọra debi pe, oun nikan lo maa n wọ yara ibusun oun, ti awọn si dijọ maa n jẹun ninu awo kan ṣoṣo lasiko isinu aawẹ.

Oríṣun àwòrán, Akeugbagold
" Gbogbo ba ṣe n wa awọn ibeji mi, ko si eleyi ti kii gbọ, idi si ree to fi nira lati tete ri wọn mu, adura mi si lo gba, ta fi tete ri wọn mu."Akeugbagold ni awọn eeyan to lọwọ ninu bi wọn ṣe ji ibeji oun gbe ni awọn nilo owo ni awọn ṣe huwa naa, ti awọn si gbọ pe oun lowo lọwọ, oun kan n fi ara pamọ ni.
" Ọkan ninu wọn lo maa n tẹle mi lọ gba owo tawọn eeyan ba fẹ sanwo Hajj tabi owo ilẹ tori mo n ta ilẹ ati ile, mo tun ni oko nla ta ti n ṣe nkan ọsin, afurasi yii si lo maa n ba mi gba owo, awọn nkan yii si lo ko si wọn loju."

Oríṣun àwòrán, Akeugbagold/Facebook
Nigba to n salaye pe oun kii fi owo jẹ awọn oṣiṣẹ oun niya, agba Alfa naa tun sísọ loju rẹ pe, ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira ni oun maa n ṣan fun awọn mejeeji to n ṣe akoso oju opo itakun agbaye oun lẹyin aawẹ Ramadan.
"Mo tun maa n fun wọn ni ẹgbẹrun meji naira ẹni kọọkan ni ojoojumọ, wọn yoo sinu aawẹ lọdọ mi, lọdun to kọja, wọn gbe irẹsi, miliki, ororo lọ sile amọ Coronavirus ko jẹ ko ri bẹẹ lọdun yii."
O tun tẹsiwaju pe ti waasi ita gbangba ba wa lasiko aawẹ Ramadan, ọkọọkan wọn yoo mu to ẹgbẹrun lọna ogun naira lọ sile, sugbọn o ni Covid-19 ko jẹ ki waasi aawẹ ṣee ṣe lọdun yii, eyi to lee mu ki owo wọn to na.
Nigba to n salaye bo ṣe ṣe alabapade afurasi naa, to fi de ọdọ rẹ, Akeugbagold ni lati ipasẹ eeyan kan to ni orukọ rere laarin ilu, to si n ṣe daadaa ni oun ti mọ ọmọdekunrin naa.

Oríṣun àwòrán, others
O ni oun nilo ẹni ti yoo maa ṣe akoso oju opo ayelujara oun lasiko aawẹ, ni oun fi gba sọdọ, lai mọ pe ọmọkunrin naa ti ṣe aidaa ri lọdọ ọga rẹ tẹlẹ.
"Ni ọjọ ti wọn ji awọn ibeji mi gbe lọ, emi pẹlu rẹ la dijọ wa ninu mọto, bi wọn si ṣe pe mi lati ile pe wọn ti ji awọn ọmọ gbe lọ, a dijọ n le gbogbo mọto to jọ ti awọn ajinigbe naa ni, to si n ṣe eto lori redio, bẹẹ lo n bẹbẹ lori Facebook pe ki wọn tu awọn ọmọ naa silẹ."
Akeugbagold fikun pe afurasi naa n fo fayọ lasiko ti wọn tu awọn ọmọ naa silẹ ni, ti ko si si ẹni to fura si pe ejo rẹ lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Akeugbagold ni oun ti darijin awọn afurasi ajọmọgbe naa, ti oun si setan lati ran lọwọ to ba jade ni ahamọ, oun si n gbadura fun pe ko yi iwa rẹ pada, ko le di aafa nla.
Lórí ọ̀rọ̀ àwọn ìbejì mí tí wọ́n jí gbé, ṣe ni mo finúwénú tí wọ́n fún mi ní iwọ jẹ-Akeugbagold
Yoruba bọ, wọn ni bi iku ile ko ba pa ni, tode ko le pa ni nitori eyinkule ni ọta wa, inu ile lawọn aṣeni n gbe.
Owe yii lo wa si ọkan onimọ nipa ẹṣin Islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold ti wọn ji ibeji rẹ gbe lọ laipẹ yii, to ṣe n fi ika hanu loju opo Facebook rẹ lọsan ọjọ Aje.
Akeugbagold naa, ti awọn ọlọpaa ṣe afihan awọn afurasi agbebọn to gbe awọn ibeji rẹ gba owo, lo bọ soju opo Facebook rẹ, to si n gbarata pe, ọkan lara awọn afurasi ti ọlọpaa fi oju wọn han naa, lo jẹ Judasi to da oun.
Koda onimọ nipa ẹṣin Islam naa sisọ loju rẹ pe, afurasi ọhun lo sun mọ oun bii iṣan ọrun, to si n ṣe akoso awọn oju opo ayelujara ti oun ti maa n ṣe waasi aawẹ Ramadan.
O fikun pe afurasi ọhun, to pe orukọ rẹ ni Opeyemi Ibraheem Agbenuso Odo, ni awọn dijọ jẹun ninu awo kan ṣoṣo lasiko isinu ni ọjọ mẹta sẹyin, to si jẹ ẹni bii ọkan oun.
"A ṣe oun lo ṣe kokari bi wọn ṣe ji awọn ibeji mi gbe, ọdalẹ ni. Mo ro pe ọlọgbọn eeyan ni, ti mo si ti fi orukọ rẹ silẹ mọ ara awọn eeyan ti yoo lọ si Mecca lọdun yii, bẹẹ ni mo tun seleri lati gbe gbogbo bukata ayẹyẹ inawo igbeyawo rẹ ni oṣu Kejila ọdun yii."
Akeugbagold wa n beere pe "Ṣe ẹṣẹ ni ki eeyan maa huwa rere si ọdọ to ni ọpọlọ lori amọ ti ko niṣẹ lọwọ bi? Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira lo fẹ gba lori ṣiṣe akoso awọn oju opo itakun agbaye ti mo ti n ṣe waasi, yatọ si owo kaadi deta to n lo, to si ti gba ida mẹẹdọgbọn ninu owo naa."

Akeugbagold ni bi asiri awọn afurasi ajọmọgbe naa ṣe tu, lo fihan pe Ọlọrun jẹri oun pe oun nikan soso ni oun n sin.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọjọ Aje ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ṣe afihan awọn afunrasi ti ọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa mu fun jiji ọmọ Akeugbagold gbe ti wọn si gba miliọnu mẹrin naira ki wọn to fi awọn ibeji naa silẹ.
Gẹgẹ bi ọrọ ti ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Kọmiṣọna Olukolu sọ, ko si ẹni to roo kan arakunrin naa.
"Nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ti awọn ọlọpaa si bẹrẹ iwadii lai mọ pe awọn mejeeji naa wa lara awọn to ṣe ọṣẹ naa."
Owó tó kàn mí nínú N4 mílíọ̀nù ìbejì Akeugbagold tí a jí gbé, bàtà ni mo fi rà-Afunrasí
Kele ofin ti mu awon ọdaran to ji awọn ibeji Alhaji Taofẹẹq Akewugba Gold gbe.
Meje ni awon ọdaran naa, ọkunrin mẹfa ati obinrin kan ti wọn gba lati tọju awọn ibeji ni gbogbo ọjọ mẹjọ ti wọn lo lakata awọn ajinigbe.
Ohun iyalẹnu ni wi pe meji ninu awọn ọdaran naa lo sun mọ Baba ibeji pẹkipẹki gẹgẹ bi oṣiṣẹ, milliọnu mẹrin naira sini wọn gba ki wọn to jọwọ awọn ọmọ naa.
Kọmisana ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Ṣina Olukolu lo ṣe afihan awọn ọdaran naa lọjọ Aje ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan.

Yatọ si pe ọwọ tẹ wọn, miliọnu mẹta din ẹgbẹrun lọna igba Naira (2.8m), ni awọn afurasi naa sọ pe awọn naa owo ti wọn gba fun itusilẹ awọn ọmọ naa ku.
Miliọnu mẹẹrin Naira ni wọn gba.

Ẹ bá mi dúpẹ́ lọ́wọ́ Sunday Igboho, Ajimobi, Seyi Makinde àti àwọn ọlọ́pàá fún iranwọ wọn láti rí ìbejì gbà padà
Ilumọọka onímọ̀ nípa ẹṣin Islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold tí kesi àwọn olórí wá ní Naijiria lati mojuto ìpèsè ètò ààbò tó péye.
Akeugbagold gbe ìmọ̀ràn náà kalẹ lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ni àárọ̀ ọjọ́ Aiku, ní kété tí ó rí àwọn ìbejì rẹ, tí wọ́n jí gbé padà.
O ni ìṣẹ̀lẹ̀ bí wọn ṣe jí àwọn ìbejì òun gbé tí jẹ kò yẹ òun gbé a ti ní ìṣòro pupọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ju bí a ṣe ríi lọ, paapa nípa eto aabo."Mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan ti ń kó ronú si, mo mọ ọ̀pọ̀ nkan ti mi ò mọ, mo sì bá ara mi ni aaye ti ń kó lérò pé mo lè bá ara mi, mo sì ń rọ àwọn olórí wa lati yí ìwà padà"
- Wo àwọn òfin tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé jáde fún àwọn tó n padà sẹ́nú iṣẹ́ lẹ́yìn k'ónílé o gbélé
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa òfin NCDC tó ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀
- Àjọ tó n mójútó ìpèsè òògùn ní America ti fọ́wọ́ sí lílo òògùn Ebola fí tọ̀jú Coronavirus
- Àwọn ọlọ́pàá wú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Uniport mẹ́ta tí àwọn ajínigbé sin
- Ká má ri! Buhari tún ti yan òkú sípò alàyè
Bákan náà ni Akeugbagold ni "irú nkan kò ṣẹlẹ̀ sí èmi yìí, kò sì ẹni tí kò leè ṣẹlẹ̀ sì. Àwọn ọlọ́pàá wá, wọn fẹ isẹ ṣe, ọ̀pọ̀ wọn sì ni kò ní irinsẹ láti fi ṣíṣẹ."
Onímọ̀ nípa ẹṣin Islam náà tún rawọ ẹbẹ ṣi ìjọba pé kò pèsè gbogbo nkan ti àwọn ọlọ́pàá bá nílò, to si tún rọ gbogbo abiyamọ láti máa gbe ọmọ wọn pamọ fún ààbò tó péye."
Agba Alfa náà, tó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó jí ọmọ rẹ gbe nítorí wọn fi tí ọmọlúwàbí kun, tún ṣàlàyé pé àwọn èèyàn náà bá òun sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ nípa ipò tí Naijiria wá àti nípa ti ara òun gan-an.
Akeugbagold wa sísọ lójú rẹ pé, inú igbó kan ládùúgbò Mufu Lanihun lójú ọna marosẹ Ibadan sì Eko ni òun ti rí àwọn ìbejì náà nibiti àwọn ajinigbe dá wọn padà sí, tó sì ni òun kò leè sọ iye owó idande tí òun san fún wọn fún aráyé.

Oríṣun àwòrán, Akewugbagola
O wa dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn èèyàn ti wọn dúró tíì lásìkò ìṣòro náà, àti àwọn tó ṣe iranlọwọ láti tètè rí àwọn ọmọ naa gba padà, tó fi mọ gbogbo àwùjọ agbaye.
"Mo dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run, àwọn ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àwọn akin èèyàn ti wọn dúró ti mi bíi oloye Sunday Igboho, Alhaji Mutiu Onimaalu àti àwọn èèyàn tó fi owó rán mi lọ́wọ́ láti san fún àwọn ajomogbe naa"
"Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gomina Oyo tẹ́lẹ̀, Abiola Ajimobi, gomina Seyi Makinde àti gbogbo àwùjọ àgbáyé fún atilẹyin wọn.
Wọ́n ti rí ìbejì Taofeeq Akeugbagold tí wọ́n jígbé nílùú Ibadan

Oríṣun àwòrán, Facebook
Iroyin to n tẹwa lọwọ ni pe wọn ti ri awọn ibeji olori ẹsin Isalm, Taofeeq Akeugbagold ti wọn jigbe nilu Ibadan.
Akeugbagold fi ikede naa sita lori ayelujara Facebook rẹ lowurọ oni pe ẹgbẹ igbo nla kan ni wọn ti ri awọn ọmọ naa lẹyin ọjọ kẹjọ ti wọn ti ji wọn gbe nile rẹ to wa ni adugbo Ọjọ nilu Ibadan.
O ṣalaye pe ni nkan bi agogo maarun abọ idaji ọjọ isinmi ni wn yọnda awọn ọmọ naa fun oun lẹgbẹ igbo kan ni agbegbeti oun ko mọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O ni "mo dupẹ lọwọ gbogbo yin fun adura ati atilẹyin yin. Abẹẹrẹ mi bọ sinu okun, Ọlọhuun yọ ọ pada fun mi."
Sheikh Taofeeq Akeugbagold tí wọn jì ìbejì rẹ lọ lọ́jọ́ Satide to kọjá, tí kọ́kọ́ kéde pé, Gẹ̀ẹ́sì tó yọ lẹ́nu bíi ti oyinbo ni àwọn ajọmọgbe tó bá òun sọ̀rọ̀ ń sọ lẹ́nu
Akeugbagold ni èyí fihan pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde Fáṣítì làwọn ajomogbe ọhun, to sì ń ké sí ìjọba láti tètè pèsè isẹ fáwọn ọdọ tí kò nise lọwọ.
Onímọ̀ nípa ẹṣin Islam náà, lásìkò tí ń sọ̀rọ̀ lórí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà dé dúró, tún sísọ lójú rẹ pé, àwọn ajinigbe ọhún tún ti ya fọto àwọn ìbejì náà ranse si òun, tí àwọn ọmọ náà sì ń wo pẹ̀lú ibanuje.
"Kódà ọkàn nínú wọn ń sọkún ni nígbà tí ojú èkejì tí wú fún omijé. Ń kó sì gbàdúrà irú iriri báyìí fún ọ̀tá mi rárá, ọkàn àwọn ọmọ mi ń fà mí."
Akeugbagold ni nìbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò òun pẹ̀lú àwọn ajinigbe, ṣe ni àwọn ajomogbe náà ń kanra jagbe mọ òun, àmọ́ ní báyìí wọn tí ń nawọ ìfẹ́ lórí fóònù si òun.
Bákan náà lo sísọ lójú rẹ pé ara, ara ìyá ìbejì kò dá rárá, ṣe ló ń dákú lọpọlọpọ ìgbà, tí òun sì ń gbe láti ilé ìwòsàn kan si òmíràn, tí ẹ̀jẹ̀ ruru òun sì ń ga sì lojoojumo.
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?
Àwọn tó jí ìbejì mi gbé ti pè mí ṣùgbọ́n N50 mílíọ̀nù tí wọ́n ń béèrè pọ̀ ju agbára mi lọ-Akeugbagold
Akeugbagold, bàbá ìbejì tí wọ́n jí gbé n'Íbàdàn ní òun ti ń tà dúkìá òun láti rówó àmọ́ ohun táwọn ajọmọgbe ń bèèrè kọjá agbára

Oríṣun àwòrán, Akeugbagold
Sheik Taofeeq Akeugbagold, tí àwọn gende agbebọn jí ìbejì rẹ gbé lọ, tí fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn tó gbé ìbejì òun ti kan sì òun.
Lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lọjọru, Akeugbagold kọ láti sọ iye owó tí àwọn ajọmọgbe náà ń béèrè fún aráyé, ó ní wón ti dunkooko mọ òun láti má ṣe tú àṣírí náà síta.
- Orúkọ Abiku ni Okunnu tí mo ń jẹ nínú eré, inú orin Barrister ni mo sì ti ri - Wale Akorede
- Wo àwọn èèkàn ìlú Kano tó kú láàrín ọjọ́ mẹ́rin sí ara wọn
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó jogún eré ṣíṣe lọ́dọ̀ òbí wọn
- O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ
O ni "gbogbo ohun tí wọn ń béèrè, tí mo bá tá nkan ti mo ní, ko kà, mo sì ń bẹ wọn lọwọ ni, wọn si ti ní ń kó gbọ́dọ̀ kéde síta."
"N kò mọ bí mo ṣe fẹ́ rí àwọn nkan ti wọn n bèèrè yìí, tí ń kó bá sọ síta. Kò sí bí mo ṣe leè rí, kódà, kí wọn dín mi nínú rẹ, mo sì nílò iranlọwọ, torí kii se nkan kékeré ni wọn béèrè".
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ipò tí ìyà ìbejì wá, Akeugbagold ni ṣe ni ìyàwó òun kan ń dákú ni gbogbo igba ni, kódà, ó ni wọn tun ṣẹ̀ṣẹ̀ fi silẹ nile ìwòsàn ni, eyiun bí kò bá tún dákú kí ilẹ tó sú.
Akeugbagold fikùn pé, òun ti ko awon nkan ti oun leè tá jáde, pé kí wọn lu wọn ní gbanjo, láti tètè rí owó gba.
Akeugbagold ni òun sì ń bẹ àwọn ajomogbe yìí, kí wọ́n dakun, ṣàánú òun, kí àwọn èèyàn sì bá òun bẹ wọn láti gba owó tó mọ niwọnba lọ́wọ́ òun, òun kò sì fẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá dá sí ọ̀rọ̀ náà.
" Àárín èmi àti àwọn tó jí ọmọ gbé nìkan ni mo fẹ́ kí idunadura náà wá, mo sì ní ẹtọ láti lo ọna ti mo ba mọ pe o dara, láti dáàbò bo ohun tí Ọlọ́run fún mi."
Akeugbagold wá dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo aráàlú fún àdúrà àti aduroti wọn láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé, tó sì tún ń rọ wọn láti túbọ̀ máa bá òun bẹ àwọn ajọmọgbe ná

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀
- Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

Ìyá ìbejì tí di jánna-janna, ẹyin tẹ jí ìbejì mi gbé, mo bẹ yín, ẹ kàn sí mi ká sọ̀rọ̀ - Akeugbagold

Oríṣun àwòrán, Akewugbagold
"Lóòótọ́ ni mo dù ipò òṣèlú mú rí, mo sì ti kúrò nibẹ láti May 2019, bóyá wọn wa ro pe owo oselu si ku nílé ni, kò ye mi, mo roo, roo, n kò rí ro, èmi kò ṣe ibajẹ si ọdọ ẹnikẹ́ni, n kò sì ba ti ẹnikẹ́ni jẹ́, ṣùgbọ́n mo mọ pe, ibi tí ọ̀rọ̀ aje Naijiria de dúró rèé. "Onímọ̀ nípa ẹṣin Islam náà wá tún woye pe, bóyá àwọn agbebọn ọ̀hún kàn ń wá ohun tí wọ́n yóò jẹ, ní wọn ṣe wá gbé ìbejì òun, ó ní, ibi tí eto ààbò orílẹ̀ èdè yìí dé dúró nìyẹn.Akeugbagold wá ń béèrè pé kí ló dé tí àwọn ọlọ́pàá kò fi dá àwọn agbebọn náà dúró lójú ọ̀nà tí wọn di lásìkò isede Coronavirus, tí àwọn agbebọn ọ̀hún jí ọmọ òun gbé.
- Ọwọ́ àwọn alásẹ ọgbà ẹ̀wọn ní ọ̀daràn to ni Corornavirus wà báyìí-Kọmísọ́nà ìlera Ondo
- 'Ó ṣeéṣe kí Ààrẹ Buhari pàṣẹ ìgbélé jákèjádò Nàìjíríà lónìí'
- Dibu Ojerinde, akọ̀wé JAMB tẹ́lẹ̀ pàdánù ọ̀pọ̀ dúkìá sọwọ àjọ ICPC"Bí àwọn agbebọn náà ṣe múra kò jọ tí ọmọlúwàbí, kí ló dé tí wọn kò kan 'Road Block' kankan lójú ọna, mo wá ń rọ gomina Makinde láti mojuto eto ààbò."Akeugbagold tún gbarata pé, ibanujẹ ni kí òbí má rí ọmọ rẹ, ibanujẹ tó ga ní, tí òun si ń rántí bí àwọn ọmọ náà ṣe máa ń dá oúnjẹ òun ru lásìkò isinu.O wa gbé oríyín fún àwọn ọlọ́pàá lórí isẹ takuntakun tí wọn ṣe láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé, ṣùgbọ́n ó ni ọrọ òun àti ti àwọn tó gbé ọmọ òun yàtọ̀ sí ti àwọn ọlọ́pàá, yóò sì dára kí àwọn èèyàn náà kan sì oun.Akeugbagold tún wà bẹbẹ, ó ní "mo bẹbẹ lọwọ gbogbo àwọn èèyàn ti mo ba ṣẹ tàbí àwọn tí wọn ró pé mo ṣẹ àwọn, àbí àwọn tí ìyà àwọn ọmọ náà bá ṣẹ, kí wọn dakun, jọwọ forí jin mi, mo bẹbẹ ni".
Sunday Igboho dá sí ọ̀rọ̀ ìbejì Akeugbagold tí wọ́n jí gbé
Ibadan Kidnap: Sunday Igboho ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọlọ́pàá láti wá ìbejì Akeugbagold síta

Oríṣun àwòrán, others
Èèkàn àwùjọ kan, Oloye Sunday Adeyemo, tí gbogbo èèyàn mọ si Sunday Igboho, ti sọ̀rọ̀ lórí ìbejì onímọ̀ kan nípa ẹṣin islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold, tí àwọn gende agbebọn gbé lọ lọ́jọ́ Satide. Igboho, lásìkò to ń takurọsọ pẹ̀lú àwọn akoroyin kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn agbofinro nipinlẹ Oyo, láti ṣíṣẹ kára, fi doola ẹ̀mí àwọn ọmọdé méjèèjì náà lọ́wọ́ ewu.
- Ohun tí a mọ̀ nípa ikú ọ̀wọọ̀wọ́ ní Kano nìyí
- Aláàfin pín oúnjẹ́ fárá Ọ̀yọ́
- Èèyàn 91 míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Nàíjírìa
- Dibu Ojerinde, akọ̀wé JAMB tẹ́lẹ̀ pàdánù ọ̀pọ̀ dúkìá sọwọ àjọ ICPC
- Ìlànà IVF là fi bí ìbejì tẹ gbé lẹ́yìn idaduro ọdún méjìlá, ẹ jọ̀ọ́, ẹ tú wọn ṣílẹ̀ - Akeugbagold, aya rẹ bẹ̀b
Bákan náà lo tún rọ gbogbo àwọn agbofinro yíká orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, láti pawọpọ ṣe àwárí ìbejì ọhun, kí wọ́n si tún rí dájú pé àwọn olubi ẹ̀dá to ṣiṣẹ láabi náà, fi imú kò ata òfin.Igboho ni ara Abiamọ tá òun nígbà tí òun gbọ nípa iṣẹlẹ náà, tó sì tún bá òun lójijì, pẹlu àfikún pé, ìwà ajọmọgbe náà kò bójú mu rárá.O wa ń para poro pé irú àwọn ìwà ọ̀daràn báyìí kò yẹ kó máa wáyé làwọn Ìpínlẹ̀ àti orílẹ̀ èdè tí ìjọba ti ń ná owó gọbọi lórí ìpèsè eto ààbò àti mímú adinku bá àwọn ìwà ọ̀daràn loniran ń rán.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- A fẹ́ lo ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tó ye àrùn Coronavirus láti fi ṣe ìwòsàn fún àwọn tó wà lórí àárẹ- UK
- Coronavirus: Kíni àwọn àmì tuntun tó n fihàn?
- Ọjoọ́ mélòó ni Coronavirus ń lò lára kí ènìyàn tó gba ìwòsàn?

Bẹẹ ba gbàgbé, a ti mú ìròyìn wá fún yín ṣáájú nípa bí àwọn agbebọn kan ṣe ya wọ ilé Sheikh Taofeeq Akeugbagold ni alẹ ọjọ́ Satide, tí wọn si gbe ìbejì rẹ, takọtabo lọ
Ibadan Kidnap: Ọdún méjìlá ni mo fi ní ìdádúró ki nto fi IVF bi àwọn ìbejì yìí - ìyàwó Akeugbagold ẹ̀bẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Akewugbagola
Gbajugbaja onímọ̀ kan nípa ẹṣin islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold àti aya rẹ, tí ń fi tomije Tomije rawọ ẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn agbebọn tó jí ibeji àwọn gbé, tu àwọn ọmọ náà silẹ.Akeugbagold, nínú fídíò kan tó gbé soju òpó Facebook rẹ ni irọlẹ ọjọ́ Aiku, ní òun àti ìyá ìbejì tí wọn jì gbé lọ, tí ń rọ àwọn ajọmọgbe ọhun pé, kí wọn tú àwọn ìbejì àwọn silẹ.Bẹẹ bá gbàgbé, a ti mú ìròyìn wá fún yín ṣáájú lọ́jọ́ Aiku, nípa bí àwọn gende agbebọn tí yà wọ ilé Akeugbagold lalẹ ọjọ́ Satide, tí wọn sì gbé àwọn ìbejì rẹ kékeré lọ.
Nínú fídíò náà, ní ìyá àwọn ìbejì ọhun tí ń kígbe pé, káwọn ajọmọgbe náà ro tí ìrora tí òun là kọjá, lẹ́yìn idaduro ọdún méjìlá, kí òun tó ri àwọn ọmọ ọhun bí."Ẹ dakun, tẹkun tẹkun ni mo fi ń bẹ yín pé kẹ bá mi tú àwọn ọmọ mi silẹ, ẹ wo ìrora tí mo jẹ fún ọdún méjìlá tí mo ti ń wá ọmọ, kí n tó rí àwọn ọmọ náà bi. Gbogbo ohun tẹ bá fẹ́ kí n ṣe, ní máa ṣe."

Oríṣun àwòrán, Akewugbagold
Bákan náà, Akeugbagold, lásìkò to ń báwọn akọroyin sọ̀rọ̀ ni, lati igba ti iṣẹlẹ náà tí wáyé, òun kò tíì fi ojú kan oòrùn, tí òun sì ń retí kí àwọn ajọmọgbe náà pé òun lórí ẹ̀rọ ibaraenisoro." Ọdun méjìlá ni ìyàwó mi fi wá ọmọ. Àwọn ọmọ yìí nìkan sì la bí ní ìlànà ọmọ bibi tí ìgbàlódé IVF, ohun tí mo ń bẹbẹ fún ní ààbò àwọn ọmọ mi, mo sì ń gbàdúrà pé kí wọn pé mi lórí foonu"Wàyí o, òṣìṣẹ́ alarena fún ileesẹ ọlọ́pàá nipinlẹ Ọ̀yọ́, Olugbenga Fadeyi tí ṣàlàyé pé, ọwọ àwọn tí bá èèyàn mẹrin lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.O wa fi ọwọ ìdánilójú sọya pé, aáyán tí ń lọ láti ṣe àwárí àwọn ìbejì náà, tó sì ń rọ àwọn èèyàn tọrọ náà kan láti fi ọwọ sowọpọ pẹ̀lú ileesẹ ọlọ́pàá.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Iroyin to ń tẹ wá lọ́wọ́ ni yajo yajo tí kéde pé, àwọn gende agbebọn tí jí ìbejì gbajugbaja onímọ̀ kan nípa ẹṣin islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold gbe lọ.
Déédéé aago mẹ́jọ alẹ ọjọ́ Satide, ni àwọn agbebọn náà jí àwọn ìbejì ọhun, tí wọn jẹ takọtabo, gbé lọ nínú ilé Akeugbagold tó wà ládùúgbò Ọjọọ n'ilu Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Nígbà tó ń fi idi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC Yoruba, àbúrò Akeugbagold to bá wà sọ̀rọ̀ ni, lóòótọ́ ni wọn jì àwọn ọmọ náà lọ àmọ́ Sheikh kò tíì leè sọ̀rọ̀ lórí iṣẹlẹ náà báyìí
Àmọ́ ìkéde kan tí Akeugbagold fi soju òpó Facebook rẹ ṣàlàyé pé, kò ju ìṣẹ́jú mẹwa lọ tí òun kúrò nínú ilé, láti lọ ṣe igbohunsilẹ waasi aawẹ, tí àwọn agbebọn fi wọlé, kò òun ni ọmọ méjì lọ.
Akeugbagold, ẹni tó ṣàlàyé pé ọdún méjìlá ni ìyá àwọn ọmọ náà fi ń woju Ọlọ́run, kò tó rí àwọn ìbejì náà bí, tún rawọ ẹ̀bẹ̀ sì àwọn gende agbebọn náà láti tètè dá àwọn ọmọ òun padà fún òun torí Ọlọ́run.
Bákan náà lo tún rọ àwọn aráàlú pé kí wọn máa gbàdúrà fún àwọn ọmọ náà, kí Ọlọ́run leè ṣe wọ́n ní rírí kíákíá.
Akeugbagold tún kesi àwọn agbofinro láti tètè bá òun ṣe ìwádìí nípa ibi tí àwọn ọmọ náà wá, kí wọn sì bá òun kò wọn wálé.



















