Ese Oruru: Arákùnrin tó jí Ese Oruru gbé gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n

Oríṣun àwòrán, @HRFKingFGA
Ile ẹjọ giga kan nilu Yenagoa tii ṣe olu ilu ipinlẹ Bayelsa ti dajọ ẹwọn ọdun mẹrindinlọgbọn farakunrin Yunusa Dahiru to ji ọmọbinrin Ese Oruru gbe ti o si tun fipa fẹ sile.
Lọjọbọ ni idajọ t'awọn eeyan ti n reti yi waye niwaju ile ẹjọ ti adajọ Jane Inyang dari rẹ.
Adajọ tu Yunusa silẹ lori ẹsun kini ti wọn fi kan ṣugbọn o gba idajọ ẹwọn ọdun marun un lori ẹsun keji, meje lori ẹlẹẹkẹta, ẹlẹẹkẹrin ati ẹlẹẹkarun-un.
Gẹgẹ bí adajọ ti se sọ, ni ṣiṣẹ n tẹle ni idajọ naa yóò tẹle ara wọn.
Bi a ko ba gbagbe, ọjọ kejila oṣu kẹjọ, ọdun 2015 ni wọn ji Eseoghene Rita Oruru gbe ni Bayelsa lọ si Kano.
Níbẹ ni Yunusa ti ki mọlẹ to si fun ni oyun, to sọ di iyawo rẹ lalai gba iyọnda awọn obi rẹ.
Ọrọ yi mu iriwisi wa ti ọpọ ọmọ Naijiria si bẹnu àtẹ lu iwa to wu yi.
Koda o mu ki ijọba apapọ pàṣẹ ki ọga agba ọlọpaa nigba naa, Solomon Arase da Eseoghene pada si ipinlẹ Bayelsa lọdọ awọn obi rẹ.
Bẹẹ ni ijọba pàṣẹ ki wọn ṣẹjọ Yunusa ni ibamu pẹlu ofin niwaju ile ẹjọ to kaju osunwọn.












