Coronavirus treatments: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá pàṣẹ pé kò gbọdọ̀ sí ìdádúró fún àwọn tí iṣẹ́ wọn ṣe kókó lásíkò ìséde

Oríṣun àwòrán, UNITED STATES AFRICA COMMAND
Ẹgbẹ awọn dokita onimọ iṣegun oyinbo ni Naijiria ti fagile iyanṣẹlodi ti wọn bẹrẹ, nitori bi awọn ọlọpaa ṣe fiyajẹ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kan lasiko isede coronavirus.
Lara oun ti awọn dokita naa tọka si nipe ileeṣẹ ọlọpaa n da awọn ọmọ ẹgbẹ wọn duro, eyi ti ko yọ awọn ọkọ to n gbe alaisan silẹ.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita, wọn ni ki awọn dokita o pada si ẹnu'ṣẹ wọn laago mẹfa irọlẹ oni.
Iyanṣẹlodi naa ko pe wakati mejila ti wọn fi kede pe awọn ti fagile.
Ọjọru ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi naa, ti wọn si s pe yoo wa titi di igba ti ijọba yoo fopin si ifiyajẹni ti awọn ọlọpaa n ṣe si awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lasiko ofin Konile-o-gbele.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ ọhun fi sita ni wọn ti fikun pe awọn ọlọpaa tilẹ n ti wọn mọle ni aini idi.
Ṣugbọn ṣa, Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Muhammed Adamu paapa ti fi aṣẹ tuntun sita nipa ofin konile o-gbele kaakiri orilẹede Naijiria.
- Ìtàn ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko
- Ẹ wo bí ìpínlẹ̀ Eko, Ondo àti Oyo yóò ṣe dá ilé ìjọ̀sìn padà
- Ọlọ́pàá ṣ'orò alẹ́ ẹrẹbẹ̀ fáwọn akọ̀ròyìn, dókítà
- Ìjẹkújẹ àwọn adarí ìjọba ló sọ mí di alárìnkiri nílẹ̀ òkèèrè-Oluwo
- Coronavirus ti di ara wa, kò le è kúrò mọ láéláé - WHO
- Coronavirus cases in Africa- Atọ́nà bí nkàn ṣe ń lọ ní Afirika
- Ènìyàn 226 ló ní àrùn Coronavirus ní Ọjọ Ìṣẹ́gun
- Inú jìn! Akitiyan ọmọ'ṣẹ́ mi tó wà lára àwọn tó jí ìbejì mi gbé kò kéré nígbà tí á n wá wọn- Akeugbagold

Ọlọ́pàá ṣ'orò alẹ́ ẹrẹbẹ̀ fáwọn akọ̀ròyìn, dókítà
Ko din ni aadọta awọn dokita , oniroyin atawọn oṣiṣẹ ẹka to ṣe koko miran lasiko ajakalẹ arun coronavirus yii ni awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti fi panpaẹ ofin mu bayii lọjọ Iṣẹgun ni ibamu pẹlu aṣẹ kan ti ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria pa.
Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ni aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ konile o gbele eleyii to de igbokegbodo ọkọ laarin agogo mẹjọ alẹ si agogo mẹfa owurọ gẹgẹ bi ara ọna lati dena itankalẹ ajakalẹ orun COVID-19.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọṣa aarẹ ko ṣai ṣe gafara fun awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn jẹ koṣemaani lasiko naa bii awọn oṣiṣẹ eto ilera, akọroyin ati bẹẹbẹl lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ni ọjọ Iṣẹgun ni ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ṣe ipade ori ayelujara pẹlu awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa lorilẹ€de Naijiria nibi to ti paṣẹ fun wọn lati tubọ rii pe aṣẹ konile o gbele naa fẹsẹmulẹ sii ti wọn si ni o paṣẹ pe ki wọn maa fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni ti irinkerindo rẹ ba ti kọja agogo mẹjọ alẹ.
Lagbegbe Alausa ni ilu Eko, gbogbo awọn dokita ati akọroyin to n bọ lati ibi iṣẹ ni awsn ọlọpaa ko da satimọle ti wọn si gbẹsẹle ọkọ wọn.
Iroyin taa gbọ ni pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ti aarẹ gbe kalẹ lori kikoju arun coronavirus, PTF lo wa kan si ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ki o to paṣẹ ki wọn tu wọn silẹ lẹyin ti wọn ti lo bii wakati meji lagọ ọlọpaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Lagos state lockdown relaxation: Ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ni ìlànà tuntun fún Covid-19 yóò fi ṣiṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/Twitter
Ijọba ipinlẹ Eko ti n gbeero lati fi opin si isede coronavirus patapata, ṣugbọn diẹdiẹ ni yoo bẹrẹ.
Gomina Babajide Sanwo-Olu lo kede awọn ilana tuntun yii, pẹlu boṣe jẹ pe ipinlẹ Eko ni aarun coronavirus pọ si julọ ni Naijiria.
Ọsẹ keji ti ijọba dẹ isede lo n pari lọ bayii, ṣugbọn gomina sọ pe ọsẹ mẹfa ni yoo gba.

Awọn ilana isede tuntun fun ipinlẹ Eko niyii
1. Register-to-Open - Eyi tumọ si pe ijọba yoo kọkọ ṣe ayẹwo ile ijọsin, ileeṣẹ, tabi ile itaja to ba fẹ ẹ bẹrẹ iṣẹ pada.
2. Lẹyin ayẹwo naa, ileeṣẹ, ile ijọsin, tabi ile itaja bẹ ẹ yoo gba iwe ẹri pe o pa ilana ati ofin ti ijọba gbe kalẹ lati fi opin si Covid-19.
3. Ijọba ko ti i sọ ọjọ ti awọn eeyan wọn yii yoo pada bẹrẹ iṣẹ wọn, lẹyin ayẹwo naa, ṣugbọn o sọ pe ki awọn to ni ileeṣẹ naa mura silẹ lati tẹle ilana tuntun naa, nitori pe coronavirus ti mu ayipada ba ayika wa.
4. Awọn ti ilana tuntun naa kan ni ṣọọṣi, mọṣalaaṣi, gbọngan ayẹyẹ, ile itaja igbalode nla, gbọngan sinima, ati awọn ibi igbafẹ.
5. Awọn nkan ti ijọba yoo yẹwo kii wọn o to o fun wọn ni iwe ẹri ni, ilana ijina sira ẹni ti wọn ti gbe kalẹ, ati fun imọtoto. Awọn nkan wọnyii ni yoo si sọ boya awọn ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi naa yoo ṣi pada.
6. Ijọba yoo paṣẹ fun awọn banki, ati ọja lati maa da awọn onibara to jẹ agbalagba lohun laarin aago mẹsan aarọ si mẹwa aabọ, ki wọn o to da awọn ọdọ lohun.
7. Dandan ni wiwọ ibomu-bo ẹnu nipinlẹ naa. Awọn ọlọkọ eero si gbọdọ tẹle ilana ijina sira ẹni.
Ṣugbọn ṣa, Gomina Sanwo-Olu sọ pe o ṣeeṣe ki isede miran tun waye, ti awọn araalu ko ba tẹle awọn ilana naa.

"Awakọ̀ tó gbé afurasí alárùn Covid-19 ní Kwara kò sí ní ibùdó ìyaraẹni sọ́tọ̀"
Yàtọ̀ si aríwo tó ń tàn ká pé gómínà ìpínlẹ̀ Kwara tí paṣẹ pé ki wọ́n fún awakọ̀ tó wà nínú fọ́rán kan to fójú hàn lórí ayélujára níbi ti wọ́n ti n gbé ènìyàn kan sí inú ọkọ pàjáwìrì aláàrùn Covid-19 níwèé ìdádúro,
Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kwara Raji Razaq ni ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Raji Razaq ní wọ́n kan yọ awakọ̀ náà kúrò lára àwọn to n mójútó àwọn alárùn coronavirus ni, nítorí pé ó kùna láti pa àwọn ilànà tóyẹ ki o tẹ̀lé mọ́.
Ó ní ọkùnrin ti wọ́n lọ gbé òun pẹ̀lú kìí ṣe àláàrùn Coronavirus, ó sì ti wà ní àkàtà ìjọba fún ìtọ́jú báyìí.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Kọmísọ́nà ní gbogbo àwọn ọgálọ́gàá ilé iṣẹ́ náà to fi mọ akọwé agba ilé iṣẹ́ iléra to pàṣẹ fun awakọ̀ náà láti lọ gbé ẹni náà ni wọ́n ti gba iwé ìbáwí.
Alhaji Razaq ni ìpàpara ni awakọ̀ náà fi bá iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ó yẹ kí ó dúró de àwọn ti yoo gbé aṣọ ìdáàbò tó yẹ kí o wọ̀ wá, súgbọ́n ko fi àrà balẹ̀
Kíni ìlànà tó tọ́ láti gbé aláàrùn Covid-19 nílé wọn
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Kọmísọnà ní tí wọ́n ba ti pé ilé iṣẹ́ ètò ilera bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ ọ̀gá àgbà ni ìpè náà yóò dé sí ti yóò si pàsẹ fún àwọn to wà ni ìdí, ètò pàjáwìrì láti lọ́ṣe iṣẹ́ wọn.
Lórí ìtàkùn ayélujára àjọ to n gbógunti ààrùn Coronavirus ni Naijira NCDC náà, wọ́n sàlàyé àwọn ìlànà ti àwọn elétò ààbò àti ará ilú gbọdọ̀ mọ̀ ti wọ́n bá ri ẹni tó ni ààrùn Coronavirus.
* O ṣe pàtàkì láti mọ àwọn ibi ìtọjú to wà ni àyíka ní ìpińlẹ̀ tàbí ni agbègbè wọ́n
* Àwọn elétò ìlera ti gbọdọ̀ kọ́kọ́ lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bi a ṣe n tọ́jú àjàkálẹ̀ ààrùn ti wọ́n pè ni (Infection, Prevention, And Control IPC).
* Gbogbo òṣìṣẹ́ tí yóò ba kójú àláàrùn Covid-19 gbọdọ̀ wọ aṣọ ìdáàbò (PPE), ìbòmú, ìbọ̀wọ́, awòojú àti fìlà
* Ní kété ti òṣìṣẹ́ ìlera bá ti gbé aláàrùn coronavirus tan, o ṣe pàtàkì láti fi àwọn kẹmika apakòkòrò tọ́jú gbogbo ǹkan ti ẹni náà wọ̀ kí o to kúrò ní ilé ìwòsàn.
Sáájú ní àkọ̀wé gómìnà Kwara Rafiu Ajakaye ti fi àtẹjáde kan síta pé gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara Abdulrazaq Abdulraman ti pàṣẹ pé kí wọ́n fún àwakọ̀ náà ni iwé ìdádúró.
Sùgbọ́n nígbà ti BBC padà pèé ló ní, wọ́n kan yọọ́ kúrò ni ẹ̀ka Covid -19 ní kìíṣe pé wọ́n yọọ́ lẹ́nu iṣẹ́
Atẹ́gùn òjò rán ọ̀pọ̀ lóko àdánù nílùú Ìbàdàn, aráàlú gbarata
Ibadan rainstorm: Awọn olugbe ilu Ibadan gbarata lori awọn ile ti atẹgun ojo ṣidanu

Awọn olugbe agbegbe Joyce B ni ilu Ibadan ti bẹrẹ sini ke irora lẹyin ti ojo to fi iṣeju marundinlaadọta rọ lopin ọṣẹ ṣe akoba fun awọn ile kan.
Ninu itakurọsọ pẹlu ikọ BBC Yoruba, ọkan lara awọn ti o fi ara gba iṣẹlẹ naa, arakunrin Kayọde Popoọla ṣe alaya wi pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹlẹ ri lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin ti oun ati ayarẹ ti ya ile ti wọn fi da ile ẹkọ silẹ fun awọn akẹkọ to n bẹ ni agbegbe naa.
O ni oun n wẹ lọwọ ni nigba ti ipe pajawiri kan wọle wi pe atẹgun ojo ti ṣi paanu ile lọ ti o si rọ lu ile alaja kan to n bẹ ni iwaju ibi ti wọn fi n ṣe ile ẹkọ.

O ni, "Inu ile mi ti mo n gbe ni mo wa, mo n wẹ lọwọ ni gbogbo inu ile bẹrẹ sini mi gbugbugbu. Bi mo ṣe jade nile iwẹ mo rii pe yara mi ti n jo.
Yara mi o jo ri, yara awọn ọmọ mi naa bakan naa.
Iyẹn ni a n mojuto lọwọ mo n pe Ọlọrun pe aanu, aanu o.

Lojiji ni ẹrọ ibanisọrọ mi dun, ọkan ni ninu awọn olukọ wa lo pe mo ba gbe ipe rẹ.
Jọkẹ ki lo ṣe ẹ? Daddy atẹgun ti gbe gbogbo paanu o..."
Popoọla ni iye owo ti yoo ṣe atunṣe ile ẹkọ naa ko di ni milliọnu meji naira, bẹẹ sini awọn to ya ile igbe lo jẹ gbese nitori baba to ni ile ti darugbo.

O ra ọwọ ẹbẹ si ijọba ati awọn ẹlẹyin ju aanu lati ṣe iranlọwọ fun wọn lasiko yii.
Gbogbo paanu ti atẹgun ojo ṣi danu ni awọn to n gbe awọn ile naa ti n gbiyanju lati kojọpọ si ẹgbẹ kan lasiko ti ikọ iroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe kan.Lọkọọkan-ejeeji sini wọn duro gẹgẹ bi wọn ṣe n wo awọn ile naa pẹlu iyalẹnu.

Oyo state: Ẹ̀mí mẹ́rin bọ́ sọnù, ọ̀pọ̀ èèyàn fara pa nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ogbomoṣọ

Eeyan ẹrin ọtọọtọ lo padanu ẹmi wọn ti ọgọrọ awọn eeyan mii si fi ara pa ninu ijamba ọkọ to waye nilu Ogbomoṣọ lọsan ọjọ ẹti.Ni agbegbe Apake lopopona marosẹ Ogbomọṣọ si Ilọrin atijọ ni ọkọ akẹru kan ti sa wọ ibi ti awọn ero ọkọ ati ọlọkada korajọpọ si.

O ṣoju mi koro ṣe alaye fun awọn oniroyin pe eeyan mẹrin lo ku loju ẹsẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ko awọn ti o fi ara pa lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Oyinbo, LAUTECHTH to n bẹ niluu Ogbomọṣọ.Iroyin sọ wi pe ẹkun ariwa ni ọkọ naa n ri irinajo lọ ki o to di wi pe o padanu ijanu ọkọ lasiko to n sa fun awọn ẹṣọ aabo oju popo niluu Ogbọmọṣọ, ṣugbọn adari ẹṣọ aabo oju popo to n bẹ ni agbegbe naa, Bọlade Olugbẹsan sọ wi pe irọ to jina si ọọtọ ni ẹsun naa.
O ni ko si oṣiṣẹ ẹṣọ aabo pupo ni ibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ.O ṣoju mi koro mii ti o ba awọn oniroyin sọrọ ṣe alaye wi pe ọlọkada ni awọn eeyan mẹrẹẹrin to padanu ẹmi wọn sinu ijamba naa.Lasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii, awọn osiṣẹ aabo duro wamuwamu si ofisi ẹṣọ aabo oju to n bẹ ni agbegbe 'High School' niluu Ogbomọṣọ lati dena akolu awọn ara ilu to n fapajanu nitori ijamba naa.

Coronavirus: Mẹ́rin nínú àwọn mọ́kànlá láti Sokoto tí wón mú l'Oyo ló ní àrùn Covid-19

Mẹrin ninu awọn eeyan mọkanla to n ti ipinlẹ Sokoto bọ ṣugbọn ti awọn agbofinro mu lẹnu ibode ipinlẹ Oyo si Osun lo ni arun Coronavirus.
Ẹni to n risi iṣẹlẹ naa, Taiwo Ladipo lo fi ọrọ ọhun lede fun awọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun.
O ni awọn mẹrin naa ti wa ni ile iwosan ti wọn ya sọtọ fun awọn to ni arun Covid-19, eyi to wa ni Olodo.

Lẹyin itakurọsọ pẹlu awọn arinrin ajo naa, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde sọ pe oun ko ni yọnda wọn fun ijọba ipinlẹ Sokoto, ayafi ti wọn ba kọkọ ṣayẹwo arun Coronavirus fun wọn.
Iye awọn to ti lugbadi arun naa nipinlẹ Oyo lọwọ yii jẹ mọkandinlogoji, ti mejidinlọgbọn ninu wọn si n gba itọju lọwọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹsan an ti ri iwosan, awọn kan ti jẹ Ọlọrun nipe nipe nitori arun naa.
Kò tíì sí àrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Oyo - Ijọba Oyo

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe ko si ẹni kankan to tii ni arun Coronavirus nipinlẹ naa, ati pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari awọn eeyan to ṣalabapade ẹni ti wọn fura si pe o ṣeṣe ko ti ko arun naa wọ ipinlẹ ọhun.
Kọmiṣọna eto ilera, Bashir Bello ni ijọbaa ti ṣayẹwo ẹni kan to ṣẹṣẹ de lati ilẹ Gẹẹsi, ti wọn si ti fi ayẹwo naa ranṣẹ si yara ayẹwọ to wa ni fasiti ẹkọṣẹ iṣegun to wa ni ilu Eko, LUTH.
O ni lọwọ yii, oun ko tii le fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni ti lugbadi arun naa nipinlẹ Oyo titi di igba ti esi ayẹwo naa yoo jade.
Bello sọ pe ijọba ipinlẹ naa mọ pe ẹni to ko arun Coronavirus wọ ipinlẹ Ekiti lo akoko diẹ nilu Ibadan.
O ni ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Oyo ti n gbaradi lati koju arun ọhun lati igba to ti ṣẹyọ lorilẹ-ede Naijiria.
Bello tẹsiwaju pe "Bo tilẹ jẹ pe arun yii ti n peleke si ni Naijiria, ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ wa n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe arun naa ko si ni ipinlẹ Oyo."
Bello wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ma foya nitori arun naa, ṣugbọn ki wọn ma ṣe awọn ohun to le mu arun jina si ayika wọn, bii wiwa ni nkan bii iwọn ẹsẹ bata mẹfa si awọn elomiran ati ṣisṣọra fun ibi ti ọpọ eeyan ba korajọpọ si.
Coronavirus: Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kán Seyi Makinde níkòó fún ìgbàlejò ìpàdé ìtagbangba PDP níbàdàn lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus

Oríṣun àwòrán, Facebook/PDP
Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kán Seyi Makinde níkòó fún ìgbàlejò ìpàdé ìtagbangba PDP níbàdàn lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus
Ọpọ lo ti n bu ẹnu atẹ lu bi Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti ṣe ipade itagbangbe oṣelu ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ibadan l'Ọjọru, bo tilẹ jẹ wi pe ibẹrubojo awọn arun coronavirus wa nita.
Nigba to n sọrọ nibi ipade ọhun to waye ni gbọngan Mapo, Makinde ni apẹrẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ si ni gbori soke ni bi Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Olagunsoye Oyinlola ati awọn alatilẹyin rẹ ṣe pada sinu ẹgbẹ naa.
Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Taofeek Arapaja, sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun ariwa Oyo tẹlẹ, Dokita Gbenga Babalola atawọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu ADC to fi mọ oludije fun ipo gomina nipinlẹ Osun, Alhaji Fatai Akinbade lo darapọ mọ PDP nibi ipade ọhun.
- Ìjọ kò ní tilẹ̀kùn ilé ìjọsìn nítorí àrùn Coronavirus - Ondo PFN
- Èyí ni ipa tí àdínkù owó epo bẹtiró yóò mú bá ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà
- Ẹyin ilé ìjọsìn, ẹ tilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí yín láti dènà àrùn Coronavirus - ìjọba Eko
- Ẹ wo ohun tí baba Adeboye sọ lórí ọ̀rọ̀ Coronavirus
- Kí ni ìtumọ̀ Pelúpelú, ìlànà àkàsọ̀ ọba tó fa wàhálà l'ọ́balọ́ba l'Ekiti
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
Bakan naa lawọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu ADP ati ZLP darapọ mọ PDP nibi ipadae itagbangba naa ti wọn pe ni ipade iṣọkan ni Ibadan.
''Ipade yii jẹ ibẹrẹ iṣọkan apa iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, ti a ba si ti wa ni iṣọkan lapa iwọ oorun gusu, Naijiria naa ti wa ni iṣọkan niyẹn,'' Gomina Makinde lo sọ bẹẹ.
Makinde ni ''awọn eeyan kan ni ko yẹ ki PDP ṣe iru ipade itagbangba bayii lasiko ti coronavirus n tankalẹ yii, ṣugbọn ọkan lara awọn olori wọn lo sọ pe arun coronavirus ti wọ inu ẹgbẹ wọn, amọ awa mọ pe ko si ninu ẹgbẹ ti wa.''
Ninu ọrọ tiẹ nibi ipade naa, Oyinlola sọ pe asiko ti to lati ṣe atunto orilẹede Naijiria, o ni itanjẹ ẹgbẹ APC ti to gẹẹ.
O rọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lati fi ọgbọn yanju ọrọ to ba wa laarin wọn ki iṣokan le wa ninu ẹgbẹ.
''Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ lọ sí ibi ìpàdé PDP ní Ibadan, ẹ lọ yara yín sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò coronavirus''
Ọgọrọ eeyan lo dẹnu bo Gomina Seyi Makinde lori ayelujara lẹyin to ṣagbatẹru ipade itagbangba ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ibadan l'Ọjọru.
Ohun ti ọpọ n sọ nipe kii ṣe akoko yii ti ibẹru-bojo ajankalẹ arun coronavirus wa nita lo yẹ ki Makinde ṣe iru ipade bẹẹ.
Ibrahim Lawal Esq ṣapejuwe ipade itagbangba PDP bi igbesẹ omugọ ti ko mu ọgbọn wa rara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ibeere ni @AbdulMahmud01 n beere ni tirẹ, o ni ''kinni o n ṣe wa gan an? O sọ pe o ṣeni laanu pe ko si ẹnikan to ronu pe iru ipade itagbangba yii le ṣakoba fun eto ilera araalu pẹlu bi arun covid-19 sẹ wa nita bayii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5

End of X post, 6
@Lucasscot_101 ṣalaye ni tiẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu APC lo kọkọ bẹrẹ iwa aṣiwere tawọn eeyan si ro pe ko si were to le ju iyẹn lọ.
Amọ o ni o ṣeni laanu pe iwa aṣiwere ti ẹgbẹ oṣelu PDP gan wa ju ti APC lọ. O pari rẹ bayii pe ko si ẹni ti ori rẹ pe ninu awọn ẹgbẹ mejeeji.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
Adeola @Harrdehy fi igbe bọnu ni tiẹ, o ni ẹnikẹni to ba kopa ninu ipade itagangba ẹgbẹ osẹlu PDP gbọdọ ya ara rẹ sọtọ fun ayẹwo arun coronavirus.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 8

End of X post, 9
Ọgọrọ eeyan lo fẹnu ko pe igbesẹ ẹgbẹ osẹlu PDP lati ṣe ipade naa kudiẹ kaato.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 10

End of X post, 11

End of X post, 12
Amọ ninu gbogbo eyi, ero Olamide Abimbola yatọ ni tiẹ. O ni aṣiwere ni gbogbo awọn to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC ti wọn n sọ oko ọrọ si PDP nitori ipade itagbangba ti wọn ṣe ni Ibadan.
Abimbola ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe iru ipade itagbangba ti ko waye ri ninu iwe itan. O rọ awọn to n bu ẹgbẹ naa loju opo Twitter pe ki wọn ronu si ọrọ naa daadaa ki wọn to maa sọrọ loju opo Twitter.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 13