Akọrin Fuji, Shanko Rasheed pàdánù àkọ́bí ọmọ rẹ̀, Jamal

Jamaldeen Emrys Atanda wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó ń wo ọ̀ọ́kán lápá ọ̀tún, Shanko Rasheed wọ aṣọ aláwọ̀ èsúrú lápá òsì, ó mú gbohùngbohùn dání

Oríṣun àwòrán, Iam_shankorasheed/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajúmọ̀ olórin Fuji, Atanda Adekunle Rasheed tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Shanko Rasheed ti pàdánù àkọ́bí ọmọ rẹ̀, Jamaldeen Emrys Atanda.

Ní ìdájí kùtùkùtù ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejì, ọdún 2026 ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáyé.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Shanko Rasheed kọ sójú òpó Instagram rẹ̀, ó ní "kò sí òbí tó gbàdúrà láti fojú sunkún ọmọ láyé ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run."

Ṣáájú ikú ọmọ náà ni Shank ti ń kọ onírúurú àtẹ̀jáde lójú òpó WhatsApp rẹ̀ pé kí wọ́n má gba àwọn ọmọ òun lọ́wọ́ òun.

Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kejìlá ọdún 2025 ni Shank Rasheed ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún méjìlá fún ọmọ náà.