Ṣé lóòótọ́ ni ẹran ajá ni jíjẹ le pa oró májèlé?
Jijẹ ẹran aja ni awọn apa ibi kan lorilẹede Naijiria jẹ nnkan ti ọpọ awọn eeyan ni agbegba naa nifẹ si pupọ.
Bẹẹ si ni, awọn ẹya mii lorilẹede Naijiria korira jijẹ ẹran aja, paapa awọn musulumi.
Orilẹede Naijria jẹ ọkan lara orilẹede ti wọn ti n jẹ aja ni ile Afrika, koda n jẹ mọ pe ọkan lara ọja aja to tobi ju, wa lorilẹede Naijiria?
Ọja yii wa nipinlẹ Plateau lorilẹede Naijiria, ti ọpọ awọn eeyan kaakiri orilẹede Naijiria si ma n peju si ọja naa lati ra aja tabi ta aja.

Ikọ BBC News gbera lọ si ọja lati ba awọn araalu sọrọ lori ohun ti wọn ri, ti wọn si fi nifẹ aja jijẹ.
Ọkan lara awọn eeyan to ba wa sọrọ ṣalaye pe, ti oun ba jẹ ẹran aja bayii, egun ara oun yoo le koko, ti ko si ni rẹ oun rara.
Ẹlomiiran ṣalaye pe ẹran aja yii ko wọn rara, pẹlu igba naira, oun yoo ra ẹran aja to kun ẹnu.
Ọkunrin mii to ba wa sọrọ ni, "ti o ba n jẹ ẹran aja, ti eeyan ba fun ẹ ni majele, ko le mu ẹ rara.
"Ko da to ba fẹ fi ogun mu obinrin, o le lo ọkan aja tabi ẹẹdọ aja mọ awọn nnkan mi lati ti fi mu obinrin naa."
Ọkunrin miiran sọ fun wa pe oun ko ri nnkan buburu ninu jijẹ aja.
Fun Olusegun Pabilanu, oyinbo alawọ funfun, to n gbe lorilẹede Naijiria, o ni ohun akọkọ to ya oun lẹnu nigba ti oun wa si orilẹede Naijiria nibi awọn eeyan ṣe n jẹ aja, ti wọn ko si fi bo rara.
"Nnkan to ya mi lẹnu ni ẹra aja, awọn eeyan yii ko ti ẹ gbiyanju ati fi pamọ, pe ki n ṣe ẹran aja o, ẹran igbẹ ni.
"O ni igba kan, aja lati orilẹede mii ni aja yii, ẹya aja naa jẹ Rottweiler, eyi to ti dagba ni a n wo nibẹ, ti ọkunrin kan si dana si labẹ lati jo irun lẹnu eti aja naa."
Pabilau ni oun ni lati bi ọkunrin naa pe ṣe o ji aja naa nitori o jẹ ohun iyalẹnu pupọ.






