Rògbòdìyàn ṣúyọ níbi ètò ìdìbò wọ́ọ̀dù ẹgbẹ́ òṣèlú APC l'Ondo, Èèyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn

Alaga APC ti wọn lu niluu bara

Oríṣun àwòrán, Ade Adetimhin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Rogbodiyan to bẹ silẹ niluu Odode-Idanre, nipinlẹ Ondo ti gbẹmi eniyan meji ti awọn marun-un mii si farapa.

Rogbodiyan yii bẹ silẹ lasiko eto idibo lati yan awọn adari wọọdu kankan lẹgbẹ Oṣelu APC nipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin akọlu to sẹlẹ ni ọọfisi ẹgbẹ oṣelu naa ṣaaju lọjọ Isẹgun ọsẹ yii nibi ti awọn janduku ti ya bo gbagede naa ti wọn si lu awọn adari ẹgbẹ ọhun ni alubami.

Ọkan lara awọn to farapa naa ni aburo alaga ẹgbẹ Oṣelu APC nipinlẹ Ondo, Ade Adetimehin.

Bakan naa ni a gbọ pe wọn jo ọkọ ayọkẹlẹ aburo alaga naa ti awọn eniyan si gbe lọ ile iwosan fun itọju lẹyin ti wọn da ajọ iya fun.

Lasiko to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alaga ẹgbẹ Oṣelu APC nipinlẹ Ondo, Ade Adetimehin sọ pe awọn to ṣe akọlu naa ro pe oun lo wa ninu ọkọ naa nitori oun ati aburo oun jọ ara wọn gidi.

O ṣalaye pe wọn yin ibọn si aburo oun naa, ti wọn si fi ada ṣa a yanayana.

Adetimehin sọ pe aburo oun naa wa nile iwosan bayi nibi ti to ti n gba itọju.

Kí ní ọlọ́pàá sọ lórí ìkọlù ìlú Idanre?

Ọlọpaa ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, Ondo State Police Command

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atejade latọwọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Jimoh Abayomi, o salaye pe alaafia ti jọba niluu Idanre.

Abayomi sọ pe DPO agọ ọlọpaa ilu naa pe ipe pajawiri si olu ileeṣẹ wọn niluu Akure, ti kọmisọna ọlọpaa si ji giri si ipe naa, to si ṣe abẹwo si ilu naa.

O ṣalaye pe kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal ati ojugba rẹ, ọga agba ajọ NSCDC, Oluyemi Ibiloye ko awọn ikọ wọn sọdi lati ri daju pe alaafia jọba niluu naa.

Alukoro naa sọ di mimọ pe awọn marun un lo farapa ninu iṣẹlẹ naa, ti kọmisọna ọlọpaa si se abẹwo si wọn lati mọ ipo ti wọn wa.

Abayomi sọ pe wọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ti wọn yoo si ri daju pe wọn fi panpẹ ọba mu awọn to sọsẹ ọhun.

Lasiko iwadii BBC Yoruba lori idi gan-an ti wọn ko fi tii mu ẹnikẹni lori iṣẹlẹ yii, esọ alaabo kan ti ko fẹ ki orukọ rẹ di mimọ ṣalaye pe ejo lọwọ ninu.

O ni awọn to ṣagbateru awọn to sọsẹ naa jẹ alagbara ninu ilu, idi ree to fi soro lati fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni lori iṣẹlẹ naa titi di asiko yii.

Ẹṣọ alaabo naa sọ pe idi niyi to fi soro fun awọn Ọlọpaa lati fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni titi di asiko yii.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni iroyin akọlu si olu ọọfisi APC nipinlẹ Ondo kun ori ẹrọ ayelujara.

Awọn janduku ya bo ọọfisi APC naa lasiko ti awọn adari ẹgbẹ ati awọn alẹnulọrọ kan n se ipade lori eto idibo lati yan awọn adari ẹgbẹ naa ni wọọdu kọọkan.

Awọn oṣojumikoro sọ pe awọn janduku naa to ọgọrun un.

Gomina Ayedatiwa lo ṣagbatẹru ikọlu na - Alaga APC l'Ondo

Ade Adetimehin ẹni to sọrọ lẹyin akọlu naa ṣalaye pe wọn gba ẹti ohun ti wọn si na ohun gidigidi.

O fẹsun kan gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Orimisan Aiyedatiwa pe oun lo ṣagbatẹru akọlu naa.

O ṣalaye pe alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Ondo lo ko awọn janduku naa sọdi ti wọn si wọn si din dundu iya fun gbogbo awọn ti wọn wa ninu ipade naa.

Alaga naa sọ pe iyalẹnu ni akọlu naa jẹ nitori Gomina Aiyedatiwa mọ nipa ipade ọhun.

Mi o mọ nnkankan nipa rẹ - Gomina fesi

Ninu atẹjade latọwọ agbẹnusọ gomina, Ebenezer Adeniyan, o ṣalaye pe irọ to jina si ootọ ni pe gomina Aiyedatiwa lo ṣagbatẹru akọlu naa.

O ṣalaye pe gomina Aiyedatiwa ni ibaṣepo to dan mọran pẹlu awọn alaṣẹ ẹgbẹ APC, nitori naa ko si idi kankan ti Gomina yoo fi ṣe akọlu naa.

Ṣugbọn o koro oju si akọlu naa, o si kilọ fún gbogbo awọn oludije lati kilọ fún awọn alatilẹyin wọn ki wọn ma ṣe fa wahala lasiko eto idibo naa.