Ṣé lóòótọ́ ni pé fífẹ́ ju ìyàwó kan lọ máa ń mú ẹ̀mí ọkùnrin gùn si?
Bi awón ọkunrin ṣe n sọ pe ọkan ṣoṣo pere lobinrin dun mọ lọwọ ọkọ naa ni isẹ iwadii tuntun lati fasiti Sheffield ni United Kingdom ti gbe abọ iwadii kan sita.
Wọn rii pe awọn ọkunrin tó le lẹni ọgọta ọdun ti wọn lo fun iwadii naa lati orilẹde ogoje lagbaye ti wọn si fẹ ju iyawo kan lọ ni ẹmi gigun ida mejila sii ju awọn ọkunrin olobinrin kan soṣo lọ ninu iwadii naa.
Won gbe abọ yii sita nibi ipade International Society for Behavioural Ecology to waye ni New york.
Won ṣawari pe ẹmi awọn obinrin maa n gun sii lataari ayọ ti titọju awọn ọmọọmọ maa n fun wọn yatọ si idunnu lori ọmọ wọn ni eyi ti ko ri bẹẹ fun awọn ọkunrin.
Bẹẹ, ayọ ọkunrin ati ẹmi gigun a maa wa nigba mii nipa nini ibalopọ to ṣi le dọmọ nigba ti ọkunrin ba wa lẹni ọgọta, aadọrin ati ọgọrin laye.
Awọn oluwadii naa sọ pe eyi tumọ si pe ọkunrin to ba ni ju obinrin kan lọ yoo bimọ sii, yoo si ṣi maa gbadun ibalopọ pẹlu awọn iyawo rẹ ti ọjọ ori wọn yoo yatọ sira wọn ni eyi ti ọkunrin olobinrin kan kii jẹ igbadun rẹ.
Awọn agba sọ pe to ba ti kọ iwaju si ẹ ko o ta, to ba kọ ẹyin si ẹ ko o ta a ṣugbon to ba ti ku iwọ nikan ko o tun ero ara rẹ pa.
Iwọ lo mọ boya igbeaye ati ọrọ rẹ faaye gba nini iyawo to pọ.
A ko ni ṣi iyawo fẹ laṣẹ Edumare




























