Kí ni èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí owó táwọn abániwálé máa ń fi kún owó ilé?

Àkọlé fídíò, Owó àwọn abániwálé
Kí ni èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí owó táwọn abániwálé máa ń fi kún owó ilé?

Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń mú ìgbé ayé rọrùn fún ẹ̀dá ni ibùgbé lẹ́yìn oúnjẹ.

Àmọ́ káàkiri Nàìjíríà lásìkò yìí, ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń kọ àwọn èèyàn lóminú ni bí owó ilé ṣe ń gbẹ́nu sókè ní gbogbo ìgbà.

Bí owó ilé ṣe ń gbẹ́nu sókè ni owó tí àwọn abániwálé máa ń gbé lé owó ilé náà tún gọbọi.

Èyí ló mú BBC News Yorùbá bí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti sọ àríwisi wọn lórí èyí.