Kíni àbọ̀ ìpàdé àwọn olórí ilẹ̀ Africa lórí ààbò dá lé lórí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn olórí ní ilẹ̀ Africa ti fi ohun ṣọkàn lórí àti wá ojútùú sọ̀rọ̀ ìgbéṣùmọ̀mí àti ìkọlù àwọn alákatakítí ẹ̀sìn tó ń wáyé ní ẹkùn Iwọ̀ oòrùn Africa.
Wọ́n ni ẹkùn náà ti di oríkò ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí tí àwọn kò sì ní gbà kí ìkọlù bẹ́ẹ̀ máa tẹ̀síwájú.
Èyí ló jẹ́ ìfẹnùkòníbi àbọ̀ ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀ èdè Africa lórí ètò ààbò tó wáyé ní Accra, olú ìlú orílẹ̀ èdè Ghana.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí orílẹ̀ èdè náà ṣe sọ, ẹkùn Iwọ̀ oòrùn Africa ń kojú ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí mẹ́jọ lójúmọ́, tó sì jẹ́ pé, ó kéré tán, ẹ̀mí èèyàn mẹ́rìnlélógójì ló ń bá àwọn ìkọlù náà lọ.
Wọ́n ní ìdájí àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn èèyàn tó ń bá ìkọlù ìgbéṣùmọ̀mí lọ ń wáyé láti Africa gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta lẹ́yìn ìpàdé náà ṣe sọ.
Ààrẹ Ghana, John Mahama ló ṣáájú ìpàdé náà pẹ̀lú àwọn aṣojú láti orílẹ̀ èdè Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Mali, Mauritania, Nàìjíríà, Senegal àti Togo.
Àwọn olórí orílẹ̀ èdè náà gbàgbọ́ pé àwọn orílẹ̀ èdè lẹ́kùn Iwọ̀ oòrùn Africa ni wọ́n ní ìsopọ̀ mọ́ra wọn nípa ilẹ̀, okoòwò àti ojú ọjọ́, tó sì jẹ́ pé ó yára kí ìpèníjà ètò ààbò ní orílẹ̀ èdè kan tètè ran òmíràn.
Kí ni wọ́n fẹnukò láti ṣe?
Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwọn olórí orílẹ̀ èdè náà jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfarajìn wọn láti ri dájú pé ìbáṣepọ̀ tó lòòrìn wà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n súnmọ́ ara wọn lójúnà àti jọ kojú ìpèníjà ààbò àti ìṣèjọba tó bá jọ ń kojú wọn.
Wọ́n ni àwọn yóò máa fi ìròyìn tó ara awọn létí lójùnà àti ri i pé àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí kò rí ààyè jòkòó ní agbègbè ẹnikẹ́ni.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn yóò máa ṣe ìpàdé lóòrè kóòrè láti ṣe àgbéyẹ̀wò bí ètò ààbò ṣe ń lọ sí ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan àti láti lè mú àyípadà bá bí wọ́n ṣe ń ṣèdájọ́ àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ fún ìwà ìgbéṣùmọ̀mí lẹ́nubodè kọ̀ọ̀kan.
Lórí dídá ààbò bo ẹnubodè, wọn fẹnukò láti gbógunti àwọn agbéṣùmọ̀mí nípasẹ̀ ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀ èdè lójúnà àti mú àdínkù bá báwọn agbèṣùmọ̀mí ṣe ń wọ orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn.
Wọ́n pinnu láti ṣe àgbékalẹ̀ ìwé ìfẹnukò lórí ìbáṣepọ̀ àti ààbò èyí tí wọ́n máa ṣe láàárín oṣù mẹ́ta, tí yóò sì parí láàárín oṣù mẹ́fà.
Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ààbò, àwọn olórí orílẹ̀ èdè náà ṣèlérí láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ pọ̀, ètò ìlera, iṣẹ́ àti ètò ẹ̀kọ́.
Wọ́n fi kun pé àyípadà ojú ọjọ́ náà ń ní ipa tó lóòrìn tó ń kó ní ìgbé ayé àwọn èèyàn, wọ́n ní àwọn yóò máa fi sí gbogbo ètò tí wọ́n bá ti ń gbèrò láti àsìkò náà lọ.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n ní àwọn yóò máa ṣe ìpàdé ní ọdún méjì méjì láti mọ bí wọ́n ṣe ń ṣàmúṣẹ àwọn ohun tí wọ́n fẹnukò lé lórí sí.



























