Báwo ló ṣe yẹ láti fún ẹni tí ejò bá sán ní aporó ejò 'antivenom'?

Àwòrán ejò tó ká, tó yọ orí sókè

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Láti ìgbà tí ikú ọ̀dọ́bìnrin Ifunanya Nwangene ti gbòde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kejì ni onírúurú awuyewuye ti ń wáyé lórí ọ̀nà tí arábìnrin náà gbà kú.

Ohun tí ẹ̀gbọ́n Ifunanya kọ sójú òpó Facebook rẹ̀ ni pé níṣe ni àwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ sí ní fa omi sára rẹ̀ nígbà tí ó sọ fún wọn pé ejò bu òun jẹ pé wọn kò fun ní aporó tó ń pa oró ejò.

Àmọ́ ilé ìwòsàn Federal Medical Centre, Jabi, ìlú Abuja nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi léde tẹmpẹlẹmọ pé àwọn fún ọmọbìnrin náà ní aporó ejò.

Èyí sì bẹ̀rẹ̀ sí ni fa oríṣiríṣi àríwísí nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bèèrè pé ṣé omi ló yẹ kí wọ́n fún-un ni tàbí kí wọ́n gun ní abẹ́rẹ́.

Ọ̀nà wo ni wọ́n ń gbà fún èèyàn ní aporó ejò tí wọ́n ń pè ní "antivenom"?

Aporó ejò "antivenom" jẹ́ aporó ejò tí wọ́n máa ń fún èèyàn ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí ejò bá bu èèyàn jẹ láti fi pa oró ejò náà.

Ìwádìí ní lílo àwọn antivenom yìí ní ọ̀nà tó dára jùlọ láti pa oró ejò tí ejò bá sán èèyàn bí ó till jẹ́ pé ó ní àwọn àléébù tirẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn, ọ̀pọ̀ àwọn tí ejò bá sán ni wọn kìí dédé fún ní abẹ́rẹ́ aporó lára bíkòṣe fífi abẹ́rẹ́ náà sínú omi èyí tí wọ́n máa gbà láti iṣan.

Inú iṣan ni wọ́n máa ń gbà láti fi fún ẹni tí ejò bá sán ní aporó.

Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n máa fi aporó náà sínú omi, tí wọ́n sì máa fún ẹni nípasẹ̀ lílo iṣan, tí ẹni náà yóò sì gba omi náà fún bíi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí wákàtí kan.

Ẹni náà yóò ti kọ́kọ́ máa gba omi lọ, tí àwọn dókítà yóò sì máa fi abẹ́rẹ́ náà sínú omi náà díẹ̀díẹ̀ títí tó fi máa iye tó yẹ láti gbà.

Vial ẹ́jọ sí mẹ́wàá ni wọ́n fi kọ́kọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀, tí ẹni tí ejò bá sán sì lè gbà tó ogójì vials bí ejò náà bá ṣe lóró sí.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ara wọn máa ń kọ́kọ́ gbòdì sí aporó yìí tí wọ́n bá ti ń gbà á kó tó di pé ara wọn tó máa balẹ̀ tó bá yá.

Ìwádìí ní ìdá ogójì nínú àwọn tí wọ́n fún ní aporó ejò ni ara ní wọ́n ṣe bí ẹni tí gìrì gbé níbẹ̀rẹ̀ kí ara wọn tó padà balẹ̀.

Wo nǹkan tí o lè sáré ṣe tí ejò bá bu èèyàn jẹ

Ejo to gun la ẹnu bi ẹni pe o fẹ gbe nnkan mi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọrọ iku ọdọbinrin Ifunanya Nwangene ti a gbọ wi pe o dagbere faye lẹyin ti ejo bu u jẹ niluu Abuja si n mi ori ayelujara titi.

Nwangene ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to tun jẹ akọrin ni iroyin sọ pe o ku lẹyin ti ile iwosan meji ti wọn gbe e lọ niluu Abuja ko ni abẹrẹ to maa n pa oro ejo.

Ọpọ ọmọ Naijiria papaa julọ lori ayelujara lo ti n fi aidunnu wọn han lori iroyin to sọ pe awọn ile iwosan ti wọn gbe Ifunaya lọ ko ni oogun to n poro ejo.

Bo tilẹ jẹ wi pe ile iwosan ijọba apapọ FMC, Jabi niluu Abuja to jẹ ọkan ninu awọn ile iwosan naa ti ṣalaye wi pe irọ to jinna si oootọ ni pe awọn o ni oogun to n poro ejo, ọpọ eeyan lo si n kọminu pe eto ilera ti ko mọyan lori lo fa iku ọdọbinrin naa.

Idi niyii ti BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ nnkan ti o le sare ṣe ti ejo ba bu eeyan jẹ.

Ohun to yẹ koo ṣe bi ejo ba ṣan eeyan

- Gbe eeyan ti ejo ṣan naa kuro nibi ti ejo ti san an tabi ki o le ejo naa kuro to ba ṣi yọju.

- Yọ ohun kohun to ba le ṣe ipalara kuro ni oju ibi ti ejo ti bu eeyan naa jẹ - nkan bii oruka tabi ẹgba ọwọ tori o le da wahala mii silẹ bi oju sisan yẹn ba wu.

- Jẹ ki ẹni naa fi ara balẹ tori kii ṣe ọpọlọpọ gbogbo ejo sisan naa ni yoo fa iku ẹni naa loju ẹsẹ.

- Ma jẹ ki ẹni naa gbera rara, iwọ ni koo gbe ẹni naa lọ si ile iwosan ni kia kia.

- Tẹ oju egbo ti ejo san naa pẹlu agbara

- Ma ṣe lo oogun ibilẹ rara.

- Ẹni naa le lo oogun oyinbo Paracetemol lati din ara riro ku tori bi ejo ba san ni jẹ, o maa n dun eeyan gidi gan.

- Yi oju ẹni naa si ẹgbẹ kan tori ti o ba fẹ bi eebi.

- Rii daju pe o n wo ẹni ti ejo bu jẹ naa ki o si ri pe ẹni naa ṣi n mi