Ilé ìwòsàn l'Abuja yarí pé àwọn fún Ifunanya lábẹ́rẹ́ tó ń poró ejò, àwọn ọ̀rẹ́ olóògbé fèsì

Ifunanya Nwangene rẹrin in muṣẹ, o si lo ẹgba-ọrun

Oríṣun àwòrán, Ifunanya Nwangene/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ile iwosan ijọba apapọ FMC to wa lagbegbe Jabi niluu Abuja ti ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ nigba ti wọn gbe ọdọbunrin Ifunanya Nwangene, gbajugbaja akọrin to doloogbe lẹyin ti ejo bu u jẹ nile rẹ wa sile iwosan naa.

Adari ile iwosan ọhun, Dokita Bioku Muftau, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe irọ nla to jinna soootọ niroyin ti ọpọ n gbe kiri lori ayelujara wi pe ile iwosan naa ko ni abẹrẹ to maa n pa oro ejo lati fun Ifunanya nigba ti wọn gbe e wa.

Dokita Muftau ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera nile iwosan naa fun ọdọbinrin to doloogbe ọhun ni itọju to peye nigba ti wọn gbe e de.

''Awọn oṣiṣẹ wa gbiyanju lori Ifunanya, wọn sapa wọn lati ri pe o ji pada, wọn lo ẹrọ lati fun ni afẹfẹ to le fi mi, bakan naa ni wọn tun fun un ni abẹrẹ to maa n pa oro ejo.

Lẹyin ọpọlọpọ igbiyanju ni wọn ri pe oro ejo naa ti wọn Ifunanya lara gidi gan an.

Bo tilẹ jẹ pe wọn gbiyanju lati gbe e lọ si wọọdu ti wọn maa n ti ṣetọju awọn ti ailera wọn ba le gan an, ṣadeede ni gbogbo ẹ kan yi biri.

Awọn oṣiṣẹ ile iwosan FMC Jabi tun gbiyanju oriṣiiriṣii ọna lati doola ẹmi Ifunanya, ṣugbọn pabo lo jasi.

Tori naa irọ nla ni ọrọ tawọn kan n gbe kiri wi pe ile iwosan FMC Jabi ko ni abẹrẹ to n pa oro ejo,'' Dokita Muftau lo sọ bẹẹ.

Bi adari ile iwosan naa ṣe n kẹdun pẹlu ẹbi Ifunanya, ni o tun fi dawọn eeyan loju pe awọn oṣiṣẹ eleto ilera nile iwosan FMC Jabi kii fi iṣẹ ṣere rara.

O wa rọ awọn eeyan lati maa ṣe iwadii iroyin ti wọn ba fẹ gbe sita daadaa, ki wọn to maa gbe sori ayelujara.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Awọn ọre Ifunanya sọ nnkan ti wọn mọ nipa iku akọrin naa

Sam Ezugwu to jẹ ọkan lara awọn ọrẹ korikosun Ifunanya sọ fun BBC wi pe irawọ ọsan to ja lulẹ ni ọdọbinrin naa to doloogbe.

O ni ọdun yii ni Ifunanya n gbero lati gbe orin rẹ jade fun igba akọkọ.

Hillary Obinna toun naa jẹ ọrẹ oloogbe ni oun gbọ pe Ifunanya n sun lọwọ ni nigba ti ejo bu u jẹ.

O ni lẹyin igba naa ni wọn ri ejo meji ninu ile rẹ.

Obinna ṣalaye pe ile iwosan ti ko jinna sile rẹ ni wọn kọkọ gbe Ifunanya lọ, amọ, wọn ni awọn o ni abẹrẹ to n pa oro ejo nibẹ.

Lẹyin naa lo sọ pe wọn gbe e lọ sile iwosan FMC Jabi.

Obinna fikun ọrọ rẹ pe abẹrẹ to n pa oro ejo kan ni wọn fun Ifunanya dipo meji ni ile iwosan FMC Jabi.

Amọ, awọn adari ile iwosan naa ni irọ ni tori awọn fun ọdọbinrin naa ni itọju to yẹ to fi mọ abẹrẹ ti n pa oro ejo.

Awọn adari ile iwosan naa sọ pe awọn oṣiṣẹ awọn gbiyanju lati doola ẹmi Ifunanya, amọ, oro ejo naa ti wọ ọ lara gan an.

Akọrin, Ifunanya Nwangene jáde láyé lẹ́yìn tí ejò ṣan ní Abuja

Ifunanya Nwangene

Oríṣun àwòrán, Ifunanya Nwangene/Kingsley Nwangene/Facebook

Òkú arábìnrin, Ifunanya Nwangene, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, tí wọ́n ní ejò san ti balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Enugu.

Olórí ẹgbẹ́ àwọn akọrin ní ìlú Abuja, Sam Ezugwu ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún BBC.

Ó ní bàbá Ifunanya ló ní kí wọ́n gbé òkú arábìnrin náà wá sí ìlú Enugu lẹ́yìn tó jáde láyé ní ìlú Abuja.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ní ìròyìn ikú Ifananya bẹ̀rẹ̀ sí kàn lórí ayélujára látàrá ìròyìn pé ejò ló san ọmọbìnrin náà tó fi jáde láyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Àwòrán Ifunanya àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Kingsley

Oríṣun àwòrán, Ifunanya Nwangene/Kingsley Nwangene/Facebook

Ẹbí olóògbé náà, Kingsley Nwangene lójú òpó Facebook rẹ̀ kọ pé ejò ló san ẹ̀gbọ́n òun lásìkò tó sùn sínú ilé rẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ó ní Ifunanya fúnra rẹ̀ ló pe òun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta láti ṣàlàyé fún òun pé ejó sán òun tí òun sì ti ń lọ sílé ìwòsàn kan.

Ó ṣàlàyé pé bí ó ṣe ń lọ sílé ìwòsàn làwọn ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù ṣùgbọ́n nígbà tó dé ilé ìwòsàn tó kọ́kọ́ lọ àwọn, ilé ìwosàn náà ní àwọn kò ní abẹ́rẹ́ tí wọ́n fi ń pa oró ejò.

"Mò ń ba sọ̀rọ̀ bó ṣe ń lọ sílé ìwòsàn. Ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ ltó kọ́kọ́ lọ ní agbègbè Lugbe sọ pé àwọn kò ní abẹ́rẹ́ láti pa oró ejò.

"Ilé ìwòsàn kejì tó lọ jẹ́ ti ìjọba tó sì débẹ̀ ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá òwúrọ̀.

"Ó sọ fún mi pé àwọn dókítà bèèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ òun tí wọ́n sì ní àwọn máa fún-un ní àwọn abẹ́rẹ́ kan."

Ifunanya Nwangene wọ aṣọ dúdú, àwòrán ọwọ́ rẹ̀ tí wọ́n fi abẹ́rẹ́ sí

Oríṣun àwòrán, Kingsley Nwangene/Facebook

Kingsley fi kún àlàyé rẹ̀ pé àwọn dókítà ló yọ aṣọ tí Ifunanaya fi so ibi tí ejò ti ṣan tí ọkàn sì ti ń balẹ̀ pé yóò rí ìtọ́jú tó péye nílé ìwòsàn náà.

Ó sọ pé lẹ́yìn tí wọ́n fún Ifunanya ní omi nílé ìwòsàn náà ni kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́, tí òun sì pa fóònù láti fún-un láàyè látu gba ìtọ́jú bó ṣe yẹ.

Ó ní lẹ́yìn náà ni òun pé ẹbí àwọn kan tó wà ní ìlú Abuja láti lọ yọjú síi nílé ìwòsàn.

Kingsley ní ìròyìn tí ilé ìwòsàn náà fi síta pé Ifunanaya kò tète dé ilé ìwòsàn ló ṣokùnfà ikú rẹ̀ kìí ṣe òótọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Sam Ezugwu sọ fún BBC pé nígbà tí òun dé Federal Medical Centre, Abuja tí Ifunanya lọ, òun bat í àwọn dókítà ń tọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́.

Ezugwu ní àwọn dókítà sọ fún òun pé abẹ́rẹ́ tó máa ń pa oró èjò méjì ló yẹ kí Ifunanya gbà ṣùgbọ́n ẹyọ̀kan ni àwọn ní.

Ó sọ pé òun wá abẹ́rẹ́ kejì lọ ṣùgbọ́n òkú Ifunanya ni òun bá nígbà tí òun fi máa ra abẹ́rẹ́ náà dé.