Kí ni orísun fífà orí ọmọ tuntun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Abdullahi Bello Diginza
- Role, BBC News, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ẹya Yoruba ati awọn ẹya mii ni Naijiria n fa ori fun ọmọ tuntun, akọ tabi abo, nibi ọjọ diẹ ti wọn ba bi wọn saye, gẹgẹ bii aṣa ṣe gbe kalẹ fun wọn.
Ṣugbọn ni awọn ẹya mii, idakeji lo ba de, wọn maa n fi i silẹ fun ọpọ ọdun fun obinrin, ti ọkunrin si maa n ge ti wọn lẹyin ọdun tabi oṣu diẹ.
Ọpọ awuyewuye lo ti jẹyọ lori eyi boya o dara fun ọmọ ikoko tabi ko dara.
Ẹṣin, aṣa ati ogun wa lara ohun to n fa ariyanjiyan lori boya ki wọn ge irun ọmọ ikoko tabi ki wọn fi silẹ.
Sugbọn e wo ni awọn onimọ ni o dara ju?
Ibeere yii ni a fẹ pese idahun si bayii.
Igba wo lo yẹ ki ọmọ ikoko ge irun akọkọ?
Sheikh Halliru Maraya, onimọ nipa ẹṣin Islam ati ọmọ igbimọ Alalaji nipinlẹ Kaduna, ni iṣe yii jẹ ohun to wa lati inu ẹsin Islam.
"Sunnah ojisẹ Allah, Anabi Muhammad (Ki ikẹ ati ọla maa ba a ) to wa ninu Hadith ti Samra ibn Jundub – eyi ti Ibn Dawud, Ibn Majah and Tirmidhi ṣe akọsilẹ rẹ - ṣalaye pe ojisẹ Allah ni: Ti ẹ ba bi ọmọ tuntun, to ba di ọjọ keje, ẹ gẹ irun rẹ.
"Fun idi, ẹyi ni orisun gige irun ọmọde ninu ẹṣin Islam." Onimọ naa lo ṣalaye bẹẹ.
Ṣugbọn ninu aṣa, o nira pupọ lati tọka si orisun gige irun tabi igba akọkọ ti wọn bẹrẹ si maa ge irun ọmọ ikoko, gẹgẹ bii awọn onimọ ṣe ṣalaye.
Ọjọgbọn Aliyu Muhammad Dan Bunza, onimọ nipa aṣa ati olukọ ni Fasiti Usmanu Danfodio University, Sokoto, ni ko si akọsilẹ ọjọ tabi asiko ti iran Hausa bẹrẹ si maa ge irun ọmọ tuntun.
"O nira pupọ lati mọ eyi nitori gbogbo iran eeyan dudu lo maa n ge irun ọmọ wọn."
Bakan naa Ọjọgbọn Maryam Mansur Yola, onimọ nipa iran Hausa ati olukọ ni Bayero University, Kano, ni igbagbọ wa pe irun gige fun ọmọde bẹrẹ lati aye atijọ ṣugbọn ko si akọsilẹ ọjọ tabi asiko ti eyi waye.
"Koda, ṣaaju ka too gba ẹṣin Islam, nigba ti awọn Hausa n bọ atẹgun," o salaye.
Ọjọgbọn Bunza ni idi ti awọn ko le fi ṣawari igba akọkọ ti iran Hausa bẹrẹ si ni ge irun fun ọmọ ikoko ni pe ko si akọsilẹ lasiko naa.
Ọjọgbọn Maryam Mansur Yola nidi ti iran Hausa fi maa n ge irun ọmọ ni lati da aabo bo wọn lọwọ aisan ojọ.
"A maa n ge irun ọmọde fun aabo lori aisan to le maa se awọn ọmọde yii, bii ori fifọ ati bẹẹ bẹẹ lọ."
Ọjọgbọn Bunza fikun eyi pe iran Hausa gbagbọ pe irun ti ọmọ ba gbe waye le ko aisan ran ọmọ naa.
Igba wo lo yẹ ki wọn ge irun ọmọ tuntun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sheikh Halliru Maraya ni ofin Islam ni Ojisẹ Allah ni wọn gbọdọ ge irun ọmọ tuntun laarin ọjọ meje.
Bakan naa ninu aṣa ile Hausa, wọn maa n ge irun ọmọde ni ọjọ keje ti wọn ba bi si aaye , Ọjọgbọn Bunza ṣalaye.
"O yẹ ki a maa ge irun ọmọde ni ọjọ ti wọn ba bi i, ṣugbọn nitori idi kan ko le ṣee ṣe, wọn yoo wa fi silẹ fun ọjọ meje.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Anfaani wo lo wa ninu gige irun ọmọ ikoko
Dokita Lawal Musa Tahir, onimọ nipa ọmọde ni ile iwosan kan niluu Abuja, ṣalaye pe ko si ẹri kankan pe gige irun ọmọde le da aabo bo ọmọ.
"Ẹwẹ, awọn kan gbagbọ pe ti ẹ ba ge irun ọmọ, awọn irun to maa jade maa rẹwa ju ti tẹlẹ lọ, awọn kan tun ni ọmọ naa yoo ni anfaani si atẹgun, ṣugbọn iwadii kankan ko fidi eyi mulẹ rara," Bẹẹ ni Dokita Lawal ṣalaye.
Ni ti Ọjọgbọ Bunza, o ni gige irun ọmọ maa n pese aabo fun ọmọ lọwọ otutu.
Dokita Lawal Musa Tahir tẹsiwaju pe ti wọn ba maa ge irun ọmọde, wọn gbọdọ ṣe e pẹlu irinsẹ to mọ tonitoni lati ma le ṣe akoba fun ọmọ naa.
"To ba ṣee ṣe, ẹ ri i daju pe ẹ lo irinsẹ to mọ tonitoni lati fi ge irun ọmọ naa lati ma le tun ṣe akoba nla fun ọmọ naa."
Dokita Tahir lo ṣalaye bẹẹ.



























