Ilé ẹjọ̀ wọ́gilé ìpàdé àpérò PDP tó wáyé ní Ibadan, fọwọ́ sí igun Wike, Ó ní igun Makinde kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Kabiru Turaki SAN/X
Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Ibadan ti wọgile ipade apero ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to waye niluu Ibadan.
Ipade apero naa lo waye ni ọjọ Kẹdogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025.
Ileẹjọ tun fofin de iṣejọba Tanimu Turaki ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si ni ki wọn ye pe ara wọn ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni ile ẹjọ tun fidi rẹ mulẹ pe awọn alaṣẹ ti ofin da mọ ni igun Mohammed Abdulrahman ati Sẹnẹtọ Samuel Anyanwu, titi ipade apero mii yoo fi waye.
Ọdun 2025 ni gbẹ oṣelu PDP dibo yan Kabiru Tanimu Turaki (SAN) lati ipinlẹ Kebbi gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ tuntun nibi ipade apero ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan ipinlẹ Oyo
Turaki to jẹ agbẹjọro agba bori pẹlu ibo 1,516, nigba ti alatako rẹ, Lado Danmarke, lati ipinlẹ Katsina ri ibo 275.
Ibi ipade apero naa ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fọwọ osi juwe ile fun Minisita fun olu ilu Abuja ati Gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Nyesome Wike; Gomina nigba kan nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ati alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Samuel Anyanwu.
Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun fọwọ osi juwe, oludamọran fun ẹgbẹ naa, Kamaldeen Adeyemi Ajibade, SAN; Senator Mao Ohuabunwa; George Turner ati Hon Umar Bature.
Igbakeji alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Oloye Olabode George, lo pe fun yiyọ Wike ati awọn yooku kuro ninu ẹgbẹ naa, to si kede pe igbesẹ naa da lori bi wọn ṣe n gbimọ pọ lati ba ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ.














