Nítorí tíátà làwọn òbí mi fi fàáké kọ́rí pé àwọn kò ní rán mi lọ sílé ẹ̀kọ́ – Ajanbadan

Àkọlé fídíò, Nítorí tíátà làwọn òbí mi fi fàáké kọ́rí pé àwọn kò ní rán mi lọ sílé ẹ̀kọ́ – Ajanbadan
Nítorí tíátà làwọn òbí mi fi fàáké kọ́rí pé àwọn kò ní rán mi lọ sílé ẹ̀kọ́ – Ajanbadan

Eekan oṣere tiata ni Ọgbẹni ti awọn eeyan mọ si Ajanbadan. Ninu ifọrọwerọ rẹ kan pẹlu BBC News Yoruba.

Gbajumọ oṣere naa to ni ọmọ ilu Ọyọ, ṣalaye pe ere sinima kan ti oun ṣe to gbajugbaja lawọn eeyan tẹ mọ lara gẹgẹbi inagijẹ.

O ni ere ori itage loun fi kọ iṣẹ tiata, ati wi pe ipinnu oun lati tẹle ilana ere tiata lati ṣe e gẹgẹbi iṣẹ lo mu ki awọn obi oun jawọ ninu riran oun lọ si ileẹkọ.