Ẹ fi Osugbo kún ìgbìmọ̀ afọbajẹ tí yóò yan Awujale tuntun- Ẹgbẹ́ Òsùgbó rọ Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Gov. Dapo Abiodun/ Facebook/Others
Latari ati jẹ ọkan lara awọn igbimọ afọbajẹ to n ri si iyansipo Awujalẹ tuntun niluu Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun, awọn ẹgbẹ Osugbo ti rọ Gomina Dapo Abiodun lati jẹ ki awọn naa wa ninu igbimọ afọbajẹ.
Oluwo Osugbo niluu Ijebu-Ode, Omobolanle Bakare, fi aidunnu rẹ han si bi Osugbo ko ṣe si ninu igbimọ afọbajẹ ti yoo yan Awujalẹ.
Oluwo Osugbo sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun ana, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026, nibi ipade ẹgbẹ naa ti wọn ṣe niluu Ijebu-Ode.
O ni ko yẹ ko jẹ awọn eeyan kọọkan ti ko si ayẹwo kikun nipa wọn ni yoo maa ri si iyansipo Awujalẹ tuntun.
Bakan naa lo ni ofin ọdun 1957 nipa yiyan eeyan sipo abalaye lo gbe Osugbo si ipo kẹta, ko si yipada.
"O daa bi ijọba ṣe dawọ eto iyansipo Awujale duro na"
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Oluwo Osugbo ṣalaye pe o daa bi ijọba Dapo Abiodun ṣe paṣẹ pe ki wọn dawọ igbesẹ iyansipo Awujalẹ duro na.
Bakare sọ pe pẹlu bi awọn kan ṣe dide si ọrọ naa nigba to n lọ lọwọ, o ṣee ṣe ko di ariwo bijọba ko ba tete da a duro bẹẹ.
O fi kun un pe kijọba tun ṣewadii iru awọn eeyan ti yoo di igbimọ afọbajẹ naa mu, nitori ọrọ pe wọn n fi owo tan awọn afọbajẹ kan jẹ ko ba ma ṣẹlẹ to ba ṣe pe awọn ti eeyan le fi ọwọ sọya nipa wọn lo wa ni igbimọ naa.
"Mo fẹ kijọba ṣewadii iru awọn eeyan ti yoo wa nigbimọ afọbajẹ. Wọn ko gbọdọ yan ẹnikẹni lasan, awọn eeyan to jẹ ọmọluabi ni ki wọn yan."
Nigba to n tẹsiwjau lori ki wọn yan Osugbo kun igbimọ afọbajẹ, o rọ ijọba Ogun lati ranti pe ofin oye jijẹ ọdun 1957 fi han pe lara igbimọ afọbajẹ ni Oluwo Osugbo Ijebu-Ode.
"Ni 1957, ipo kẹta ni wọn fi Osugbo si. A ti kọwe sijọba lati ri i pe awa naa wa lara awọn afọbajẹ.
"Ofin ti da Oluwo Ijebu-Ode mọ bii ara igbimọ naa, ṣugbọn ko dun mọ awọn kan, tori ẹ la ṣe ta ko o."
Bẹẹ ni Oluwo Osugbo Ijebu-Ode, Omobolanle Bakare, ṣalaye.














