Nigerian Traffic Laws: Ohùn tó yẹ ní mímọ nípa òfin ojú pópó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lilọ bibọ loju popo jẹ ohun ti a ko le sa fun gẹgẹ bi ọmọ eniyan.
Ati ẹni to n fẹsẹ rin atawọn to n gun ọkọ, awọn ofin wa to de bi eeyan ti ṣe maa n lọ loju ọna.
Bayi ti ọdun lọ si opin ti awọn eeyan si n palẹmọ lati ririn ajo ọdun Keresimesi, o tọ ki a la ara wa lọyẹ nipa awọn ofin to yẹ ni mimọ loju popo.
Awọn ofin wọn yi ṣebi ni pọ diẹ ṣugbọn nitori asiko diẹ ninu wọn la fẹ gbe yẹ wo lonii.
Ẹ wa nkan fidi le ki ẹ fidi le nkan ma bawa fi ọkan ba awọn ofin wọn yi lọ ni ṣiṣẹntẹle.
Bẹliti ọkọ di dandan lati wọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn to ṣe ọkọ fi aaye kalẹ fun wa lati lo bẹliti yi ni kete ti a ba ti ko si inu ọkọ.
Anfaani bẹliti yi pọ ti a si ma dena fifi ori gba ti ijamba ọkọ ba ṣẹlẹ.
O di dandan fun nikẹni to ba wa ninu ọkọ lati wọ bẹliti yi,o wa fun awakọ ati gbogbo ero to ba gbe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ ma ṣe fẹrupọkọ yin
Ọkọ kọọkan lo ni iye eeyan to le gbe ati iye ẹru ti o yẹ ki o di.
Bi ẹ ba n wa ọkọ ti ẹru tabi ero pọju deede ohun to yẹ, ẹ ti tasẹ agẹrẹ sofin ni yẹn.
Aburu ka ma di ẹru pupọ ni pe e o ni ri ilẹkun ọkọ pade daada ati pe ọkọ naa ko ni gbera bo ti ṣe yẹ
O gbọdo niiwe aṣẹ awakọ:
Bi eeyan ba fẹ wa ọkọ, o di dandan ko jẹ awakọ to dantọ.

Oríṣun àwòrán, FRSC/Facebook
Ohun taa si fi jẹri si ni pe yoo ti gba iwe aṣẹ awakọ lọdọ awọn alaṣẹ.
Eleyi ni yoo jẹ eri pe o yẹ ni ẹni to le gbe eeyan si inu ọkọ. Aini iwe yi jẹ ọna kan gboogi tawọn eeyan fi n tako ofin irina.
Yara lọ ṣeto tirẹ ki o to bọ sọna fun irinajo.
Ina ọkọ rẹ gbọdọ mọlẹ kedere
Yoruba a ma ni oju ni baba ara.Fẹnikẹni to ba n wakọ, ina ọkọ rẹ ṣe pataki.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ si pe wọn yoo jẹ ki wiwakọ lalẹ ninu okunkun rọrun, awọn ina ara ọkọ tun jẹ atọna fawọn awakọ mii lati mọ ti eeyan ba n duro tabi to ba fẹ gbera.
Ẹni ti ina ọkọ rẹ ko ba ṣiṣẹ bo ti ṣe yẹ ti tasẹ agẹrẹ sofin irinna.
Yagọ fun oti mimu lasiko to ba n wakọ
Njẹ iwọ fẹran ọti mimu?

Oríṣun àwòrán, Sean Gallup
Bi o ba n wakọ, ma ṣe mu ọti, ti o ba n mu ọti, ma ṣe wakọ.
Ẹni tawọn agbofinro ba ri pe o mu ọti lasiko tabi ṣaaju ki o to wa ọkọ yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Idi ti wọn fi ni ka ma muti lasiko ta ba n wakọ ni pe o le ṣe okunfa ijamba ọkọ ti ẹmi si le ba lọ.
Awọn ofin miran:
- Ma ṣe sare asapajude loju popo
- Ri i wi pe gbogbo awọn taya ọkọ rẹ jẹ eyi to dara to ṣi n ba oju titi ṣọrẹ lalaafia
- Ni ohun eelo taa fi n pa ina ninu ọkọ rẹ (fire extinguisher)
Mọ wi pe ijọba ko gbe awọn ofin wọnyi kalẹ lati fi iya jẹ eeyan bi kii ṣe lati daabo bo ẹmi
Ri wi pe o tẹle awọn ofin yi ki o ma ba ri ibinu awọn ajọ ẹsọ aabo oju popo iyẹn 'Federal Road Safety Commission (FRSC)'














