Speed Limit: Ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta àti #3000 ni ìtanràn fun awakọ̀ to bá jẹ̀bi

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ to n risi ọrọ oju popo lorilẹ-ede Naijiria, FRSC ti ni ẹgbẹrun mẹta Naira ni awakọ yoo maa san ni gbogbo igba ti awọn ba ti mu wọn fun ijanu ọkọ (Speed Limiter) lójú pópó.
Adari Ikọ Ajọ Irinna popo ni ipinlẹ Eko, Hyginius Omejie to ba BBC Yoruba sọrọ lasiko to n fesi si igbesẹ wọn lati rii wi pe awọn awakọ lo ẹrọ ti yoo fopin si ere asapajude loju popo lasiko ọdun yii.
Omegie ni ẹrọ ‘speed limiter’ naa ko ni jẹ ki awọn awakọ wa ọkọ loju popo ju kilomita aadọrun un ni wakati kan (90/km per hour) ti wọn ba n wa ọko lo loju popo.
Pataki 'Speed Limiter' ninu ọkọ rẹ:
O fikun un wi pe ti ọkọ ba ni ẹrọ yii ninu ọkọ, igbakiigba ti wọn ba ti kọja ila ni ọkọ naa yoo kọ lati sisẹ afi ti wọn ba da ọkọ naa pada si iye to yẹ ki wọn ma a rin loju popo.
Adari ikọ ajọ irinna popo ni ipinlẹ Eko fikun ọrọ rẹ pe ‘ẹrọ speed limit’ yii n sisẹ pelu ẹrọ to n gbe epo bẹntirolu lọ si inu ọkọ ni.
Amọ nigbakugba ti wọn ba ti lu ofin speed limit yii, epo ko ni lọ si ibi to yẹ ko lọ ninu ọkọ, ohun ni yoo mu ki ọkọ naa pana.
Ajọ to n risi ọrọ oju popo lorilẹ-ede Naijiria, FRSC ni awọn awakọ igboro ni awọn kọkọ bẹrẹ si ni kan an ni dandan fun.
Nitori pe o di dandan lati ni ẹrọ yii sinu ọkọ wọn nitori awọn ni wọn saaba maa n sagbakọ ijamba ọkọ loju popo.
Ijiya fun ẹni ti ko ba ni 'Speed Limiter' ninu ọkọ rẹ:
Hyginius Omejie ni owo itanran to jẹ faini ẹgbẹrun mẹta naira ni awọn ti ko ba ni yoo ma a san,
Koda, wọn yoo tun fi ẹwọn osu mẹta jura gẹgẹ bii ijiya fun awọn arufin yii.













